You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
MMM: EFCC ìpínlẹ̀ Enugu fi ìkìlọ síta lórí ètò sogúndogójì
Laipẹ yii ni awọn alaṣẹ MMM kéde lójú òpó ayélujára pé ètò nàá ti gbe aṣọ ìlànà tuntun wọ̀.
Nigba ti BBC kan si banki Naijiria, CBN, wọn ni gbogbo igba lawọn maa n kilọ fawọn ọmọ Naijiria lori owo sogundogoji.
CBN ni ẹnikẹni to ba fi owo rẹ pamọ si ibikibi ti CBN ko lọwọ si wa ninu ewu jibiti.
Chidi Okoroafor to jẹ agbẹnusọ fun CBN ṣalaye kikun fun BBC pé ajọ NDIC lo maa n ṣeto adojutofo fawọn ibi ifowopamọ si gbogbo ti CBN fọwọ si ni eyi ti MMM ko si nibẹ.
Ọpolopo ikilọ ni o ti jade fawọn ọmọ Naijiria ti wọn ro pe ti awọn ba tun MMM ṣe, boya awọn a ri owo wọn tẹlẹ to ti rì sinu ẹ gba pada.
Iwadii BBC fihan pe ilana tuntun wọn yii ko sọrọ lori owo to ti wọnu MMM tẹlẹ ati ọna ti eeyan le fi rii gba pada.
Kini ero EFCC lori MMM ni Naijiria?
Ajọ to n koju iwa jẹgudujẹra lorile-ede Naijiria ti figbe bọ ẹnu fawọn eeyan Naijiria lati yago fun eto sogundogoji MMM to wọlu pada.
Agbẹnusọ ajọ naa ni ipinlẹ Enugu, Chris Oluka lo fi ikilọ yi sita.
EFCC: Ẹ yàgò fún MMM, àwa ké fún un yín tó o!
Ninu ifọrọwanilẹnuwo lori ẹrọ alagbeka pẹlu BBC, Oluka sọ pe ko si anfaani kankan ti yoo tẹyin didarapọmọ eto naa bi kii ṣe pipadanu owo.
O salaye pe o ṣoro lati gba awọn to wa nidi eto yi mu nitori pe oju opo ayelujara ni wọn ti n ṣe eto naa.
Amọ ṣa, o rọ ẹnikẹni to ba ni iroyin nipa awọn sogundogoji yi lati fi ṣọwọ si ajọ naa.
Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yi ni MMM, ti apeja rẹ n jẹ Mavrodi Mundial Moneybox tun wọlu pada ni Naijiria.
Eto yii jẹ oni sogundogoji ti ọpọ eniyan jakejado agbaye, ti ko yọ awọn ọmọ Naijiria silẹ kopa ninu rẹ ti wọn si jẹ owo ti awọn mii padanu obitibi owo si MMM ti kógbá wọlé.
Eto naa ti ileeṣẹ to n mojuto o sọ pe awọn gbe kalẹ lati ''máa pese iranlọwọ'' Àwọn olùdókòwò MMM ń fi apá jánú fun awọn eniyan.
Wọn kede lọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa ọdun loju opo ayelujara wọn pe ilana tuntun ti awọn n ṣiṣẹ le lori lati igba ti ti tẹlẹ dẹnu kọlẹ, ti pari fun lilo.
Ninu oṣu kẹrin, ọdun 2018, ni awọn oludari eto sogundogoji ọhun kede pe awọn n kogba wọle nigba ti baba'salẹ wọn to bẹrẹ rẹ, Sergie Mavrodi kuÀìsan ọkàn pa olùdásílẹ̀ sogúndogójì MMM.
Ọpọ eniyan kaakiri agbaye, to fi mọ orilẹ-ede Ghana, Kenya, ati Naijiria, to kopa ninu eto naa lo padanu ọpọlọpọ miliọnu, nigba ti nkan bẹrẹ si ni daru fun eto naa l'ọdun 2016.
Iwadii ti BBC ṣe lori ilana tuntun yii fihan pe - bii ti tẹlẹ, awọn eniyan yoo forukọ silẹ loju opo ayelujara wọn, wọn si tun ti da ẹlẹgbẹjẹgbẹ silẹ lori ayelujara Whatsapp fun awọn ọmọ Naijiria lati maa lo.
Nigba ti yoo si fi di owurọ ọjọ kẹtalelogun, eniyan bi ọrinlerugba din mẹfa lo ti darapọ mọ ẹgbẹ naa lori Whatsapp.
MMM sọ pe awọn ti pa ilana da ninu eto tuntun yii, ati wi pe dipo eniyan, rọbọọti ni yoo ma ṣakoso bi nkan ṣe n lọ.
Igba akọkọ kọ niyi ti iru eto yii ṣeleri èrè kiakia fun awọn oludokowo, ti ọpọ eniyan si n ṣe e bo tilẹ jẹ wi pe awọn alaṣẹ n kilọ fun wọn. Amọ ṣa, ikilọ naa kìí wọ wọn leti.