Nigeria Army: àṣírí àwọn ajínigbé kò bò mọ́ ni Ondo àti Ekiti

Kete ti ijọba apapọ ti paṣẹ pe ki awọn ọmọ ogun lo mojuto ọrọ awọn ajinigbe ni iṣẹ ti bẹrẹ.

Ọpọlọpọ iṣẹlẹ ijinigbe lo ṣẹlẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria lasiko yii ni eyi to n kọ ọpọ olori lominu.

Koda laipẹ yii ni wọn ṣi ji ọmọ minista eto ilera, Ojogbon Adewole gbe ki awọn agbofinro to rii padaỌmọ isaac Adewọle gba ìdáǹdè lọ́wọ́ ajínigbé.

Ileeṣẹ ologun ṣalaye pe awọn ẹrọ ayaworan to n fo lofurufu yii ni awọn yoo lo lati ṣawari ibúba awọn ajinigbe lawọn ipinlẹ yii.

Lọjọ Eti ni wọn ṣe ifilọlẹ awọn ẹrọ yii ni Osi ni Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo.

Ogagun agba Zakari Abubakar to jẹ adari ikọ ọmọ ogun ni ẹkun yii ṣalaye pe awọn ẹrọ yii a maa ṣiṣẹ laarin ipinlẹ mejeeji tọrọ kan ni

Ogagun Zakari ni Ogagaun agba Tukur Buratai ti paṣẹ lati Abuja pe ijinigbe gbọdọ dopin ni ẹkun yi lẹyẹ-o-soka.

Ọgagun Buratai to n dari gbogbo ọmọ ogun Naijiria ni lilo awọn irinṣe igbalode bi eyi yoo tete jẹ ki iṣẹ naa rọrun lati ṣe.

Ogagun Abubakar ni ikọ omo ogun oriṣi meji ti wọn kọkọ gbe kalẹ lati gbogun ti ijinigbe ni yoo jọ lo ẹro yii lati mu ayipada de ba eto aabo awọn eniyan ipinlẹ Ondo ati Ekiti

Ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ ni aja iwoyi lo mọ ehoro iwoyii lé ni awọn fi ọrọ yii ṣe.

O ni igbo kijikiji to wa ni agbegbe yii ni awọn kan ti sọ di ibuba wọn fun iṣẹ ibi.

Ogagun Azinta to jẹ olori ikọ ọmọ ogun ni ẹkun yii ni wọn ti paṣẹ fun pe ko rii pe gbogbo ọmọ ogun sá ipa wọn fun alaafia awọn eniyan Ekiti ati Ondo ti wọn n gbe ninu ipaya bayii.

Awọn ọmọ ogun wa fi da gbogbo awọn arinrinajo loju pe ko nii sewu mọ lopopona lati isinyii lọ.

Wọn ni awọn ikọ tijọba ṣagbekalẹ lati gbogun ti awọn ajinigbe ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu ni agbegbe yii.

Igbagbọ awọn eniyan ipinlẹ Ondo ati Ekiti ni pe laipẹ ni wọn yoo le tun maa fẹdọ sori oronro sun bii ti tẹlẹ pẹlu igbesẹ tuntun ti awọn ọmọ ogun gbe yii.