You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọogun mu darandaran fulani mẹfa, wọn pa mẹwa ni Adamawa
Ọwọ awọn ọmọogun ti tẹ awọn kọlọransi darandaran mẹfa kan ti wọn kọlu ileto Gwanbar ni ipinlẹ Adamawa.
Awọn darandaran fulani naa ni wọn ba dukia jẹ ti wọn si tun ti ina ile ni ileto naa ki ọwọ awọn ologun to tẹ wọn.
Awọn ologun mu awọn mẹfa ọhun lẹyin ti wọn ti pa mẹwa ninu wọn to gbiyanju ati ba awọn ọmọogun fibọn pẹẹta.
Awọn eeyan ileto naa lo ke gbajare sita sawọn ọmọogun ọwọ kọkanlelọgọrun ileesẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ti wọn n seto abo Ayem Akpatuma ti ijọba apapọ sẹsẹ ko lọ si agbegbe naa lati kapa gulegule ikọlu awọn darandaran fulani lagbegbe naa.
Amọṣa awọn amokunsika ẹda naa ti sa kuro ni ileto naa ki awọn ologun to de siblẹ.
Ọwọ tẹ mẹfa ninu awọn darandaran fulani naa nigba ti awọn ọmọogun naa tọpinpin wọn de ileto miran ti orukọ rẹ n jẹ Garigiji nibi ti wọn ti n gbimọran ati salọ mọ awọn ologun naa lọwọ.
Lara awọn ohun ija oloro ti wọn ka mọ awọn darandaran naa lọwọ ni ibọn atamatase AK47 kan, ọta ibọn mọkanlelogoji, ibsn atọwọda kan pẹlu ọta rẹ marundinlọgbọn tofimọ ada kan.