Làásìgbò ọ̀tun bẹ́ sílẹ̀ ní Ifon àti Ilobu, Gómìnà Adeleke kéde òfin kónílé ó gbélé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Sẹ́nétọ̀ Adeleke ti kéde òfin kónílé ó gbélé láàárín aago mẹ́fà ìrọ́lẹ́ sí aago mẹ́fà ìdájí ní ìlú Ilobu àti Ifon ní ìpínlẹ̀ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí Kọmíṣánnà fétò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun, Kolapo Alimi fi léde lọ́jọ́ Ẹtì ní Gómìnà Adeleke gbé ìgbésẹ̀ náà látàrí ìjà ọ̀tun tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín ìlú Ilobu àti Ifon.

Ẹ ó rántí pé Gómìnà Adeleke ti kọ́kọ́ kéde òfin kónílé ó gbélé láàárín aago mẹ́wàá alẹ́ sí aago mẹ́rin ìdájí ní nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn nítorí ìjà tó ń wáyé láàárín ìlú méjéèjì.

Àtẹ̀jáde náà ní Gómìnà Adeleke kọminú lórí àkọ̀tun ìkọlù tó ń wáyé ní ìlú Ifon àti Ilobu.

"Èyí ló mú kí gómìnà kéde òfin kónílé ó gbélé láàárín aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ sí aago mẹ́fà ìdájí bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹta, ọdún 2025."

Gómìnà Adeleke tún darí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ àwọn ológun, àwọn ọlọ́pàá, àwọn ẹ̀ṣọ́ ara ẹni lààbò ìlú NSCDC láti máa ṣàmójútó ètò ààbò ní àwọn ìlú méjéèjì ní gbogbo àsìkò lójúnà àti dènà títẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.

Bákan náà ni gómìnà tún pè fún ìpàdé àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ní ìlú méjéèjì tó fi mọ́ Olufon ti Ilu Ifon, Ọba Peter Oluwole Akinyooye àti Olobu ti ìlú Ilobu, Ọba Ashiru Olatoye Olaniyan.

Gómìnà Adeleke ní káwọn alẹ́nulọ́rọ̀ náà wá bí wọ́n ṣe máa paná aáwọ̀ tó ń wáyé láàárín àwọn èèyàn wọn.

Ó wá rọ àwọn èèyàn ìlú náà láti gba àláfíà láàyè, kí wọ́n sì gba ara wọn mọ́ra láti máa gbé nínú ìfẹ́, kí wọ́n sì dẹ́kun fífa làásìgbò ní gbogbo ìgbà.

Ó ní ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ pé ó lọ́wọ́ nínú ìwà jàgídíjàgan yóò fojú winá òfin.