You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ajínigbé palẹ̀mọ́ àwọn èrò ọkọ̀ GIG & ABC tó ń gba Kogi lọ Abuja
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kogi ti fidi iroyin n ja kiri lori ayelujara pe awọn ajinigbe kọlu ọkọ ero meji nipinlẹ Kogi, ti wọn ji awọn ero to wa ninu ọkọ naa gbe mulẹ.
Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ ni pe awọn ọkọ ero naa lo gbera lati ilu Umuahia nipinlẹ Abia, ti wọn si n morile lọ ilu Abuja sugbọn awọn ajinigbe da wọn lọna ni agbegbe Lokoja nipinlẹ Kogi, ti wọn si ko awọn ero wọle sinu igbo.
Awọn ọkọ ero naa lo jẹ ti ileeṣẹ God is good ati ABC.
Saaju ni ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Chude Nnamdi, ti kọkọ pariwo sita lori ayelujara pe ọkunrin kan sọ fun oun pe Iyawo rẹ wa lara awọn ero ti awọn ajinigbe naa ko lọ sinu igbo, to si sọ fun pe awọn ajinigbe naa fi foonu iyawo rẹ pe lowurọ oni.
Agbẹnusọ fun Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, William Ovye Aya sọ fun BBC pe otitọ ni pe isẹlẹ naa waye sugbọn awọn ko ti le sọ iye eeyan to wa lọwọ awọn ajinigbe naa.
“A ti gba iroyin nipa isẹlẹ ijinigbe naa, sugbọn a ko le sọ iye eeyan to wa ninu ọkọ naa.
“Nigba ti a gba iroyin, Ọga ọlọpaa to wa ni agbegbe naa pẹlu awọn fijilante ati ọdẹ ti gbera lati lọ sinu igbo lati le se akitiyan lati dola awọn eeyan lọwọ awọn ajinigbe.”
Bakan naa, Ileeṣẹ BBC kan si ileeṣẹ God is Good Motors, ti ọkan lara awọn osisẹ eọn ti ko fẹ ka darukọ oun fidi isẹlẹ naa mulẹ fun wa.
“A n gbiyanju lati tun iwadi, ohun ti a ba ba bo , a o jẹ ki ẹ mọ,” O salaye.
Ẹni to ba wa sọrọ lati Ileeṣẹ ABC ni oun ko ti le fi di isẹlẹ naa mulẹ, to oun ko si le sọ boya otitọ ni tabi irọ.
Opopona Ajaokuta, Okene ati Lokoja ni agbegbe ipinlẹ Kogi ni ọpọ isẹlẹ ijinigbe ti waye ni ọpọ igba.
Ninu oṣu kejila ọdun 2023 ni Ileeṣẹ Ọlọpaa kede pe awọn dola ẹmi awọn eeyan mọkanlelogun ti awọn ajinigbe ji gbe ni agbegbe Ajaokuta.