Gbajúgbajà àgbà akọni òǹpìtàn, Jimi Solanke jáde láyé

Gbajugbaja akọtan ohun asọtan, olorin ibilẹ, akọ ewi to tun jẹ agba oṣere, Alagba Jimi Solanke ti jade laye

Ọdun 1942 ni wọn bi oloogbe naa saye.

Owurọ kutu Ọjọ Aje, Ọjọ Karun un, oṣu keji ọdun 2024 ni Solanke dagbere faaye ni ile iwosan ẹkọ iṣegun, Olabisi Onabanji to wa ni Sagamu nipinlẹ Ogun.

Ẹni ọdun mejileelogorin ni agba akọtan naa.

Akọroyin BBC news Yoruba ti ba ọkan lara awọn enìyan oloogba naa sọrọ lorí aago, ìyẹn Omoba Biola Ogundeko, to si fi iroyin ikú Baba Jimi Solanke naa mulẹe.

Ta ni Jimi Solanke?

Fun ọpọlọpọ to wo awọn ere ori itage bii Kurunmi ati Ovonramwen Nogbaisi ti Ola Rotimi kọ, Death and the King's Horseman ti Wole Soyinka kọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, wọn mọ pe gbagada ni oju Jimi solanke wa ninu awọn ere naa tori oun ni o ko ipa to tobi julọ ninu wọn.

O ti le ni aadọta ọdun to ti lo ninu iṣẹ tiata nipa gbigbe aṣa ibilẹ Yoruba ati agbegbe rẹ ga.

Ilu Eko ni wọn bi Solanke si ni ọdun 1942.

Ni ẹka ti orin, ọpọlọpọ orin ati orin itan ni Baba Solanke ti kọ ati eyi ti ko tilẹ tii gbe jade rara rara.

Awọn orin ọmọde naa ko gbẹyin nibẹ gẹgẹ bi ohun baba Solanke ṣi ṣe n dan ninu orin yi