Ta ni àwọn èèyàn tí Tinubu yàn sí ìgbìmọ̀ àlááfíà láti fòpin sí ìpànìyàn ní Benue àti iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti wá ojútùú sí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Benue.

Ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàlá mọ́ òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kẹfà ni ìkọlù tuntun míì wáyé ní ìlú Yelwata, ìjọba ìbílẹ̀ Guma ní ìpínlẹ̀ Benue níbi tí àwọn aláṣẹ ti sọ pé èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló pàdánù ẹ̀mí wọn.

Lara awọn eeyan to wa ninu igbimọ alaafia naa ni awọn gomina tẹlẹ, agba oselu, ọba alaye atawọn agba lẹnu isẹ ọba.

Awọn gomina to wa ninu igbimọ alaafia naa:

Àwọn èèyàn tí ààrẹ yàn sí ìgbìmọ̀ náà mẹrin ninu wọn jẹ gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Benue.

O si daju pe awọn eeyan yii mọ tifun tẹdọ ohun to n se okunfa isẹlẹ ipaniyan lemọ-lemọ ni ipinlẹ naa.

Awọn gomina mẹrẹẹrin naa ni iwọnyi:

  • Gómìnà ológun tẹ́lẹ̀ rí ní ipinlẹ Benue, Ọ̀gágun Atom Kpera
  • Sẹ́nétọ̀ George Akume ti oun naa ti jẹ gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Benue ni ọdun 1999
  • Sẹ́nétọ̀ Gabriel Suswam ti oun naa ti jẹ gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Benue ni ọdun 2014
  • Góminà Samuel Ortom tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbésẹ̀ kuro nipo gomina ní ìpínlẹ̀ náà.

Awọn ọmọ igbimọ yoku ree:

Awọn ọmọ igbimọ alaafia ti ààrẹ Tinubu tún yan ree:

Alága àwọn lọ́balọ́ba fún ìpínlẹ̀ Benue, Ọ̀jọ̀gbọ́n James Ayatse

Ọba alayé fún ilẹ̀ Idoma, Dókítà John Elaigwu.

Bẹ́ẹ̀ náà láwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀, tó fi mọ́ àwọn tí kìí ṣe ọmọ ìpínlẹ̀ Benue náà wà lára ìgbìmọ̀ tí ààrẹ yàn.

Mọ̀ díẹ̀ nípa àkọsílẹ̀ díẹ̀ lára àwọn èèyàn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà

  • John Atom Kpera

Ọ̀kan lára àwọn tí ààrẹ yan sí ìgbìmọ̀ láti wá àláfíà sí ìpínlẹ̀ Benue ni John Atom Kpera.

Òun ni gómìnà ológun àkọ́kọ́ fún ìpínlẹ̀ Anambra láàárín ọdún 1976 sí 1978 lábẹ́ àkóso ìjọba ológun Olusegun Obasanjo.

Lẹ́yìn náà ló tún ṣe gómìna ológun fún ìpínlẹ̀ Benue láàárín ọdún 1984 sí 1985 lábẹ́ àkóso ìjọba ológun Muhammadu Buhari.

Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kìíní, ọdún 1941 ni wọ́n bí John Atom Kpera ní Mbatierev, ìjọba ìbílẹ̀ Gboko.

Lẹ́yìn tó darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ ológun ni ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ológun Haile Selasie Military Academy ní Ethiopia lọ́dún 1962.

Ó ko ipa tó lòòrìn lórí ètò ìdìtẹ̀gbàjọba tí wọ́n gbèrò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Kẹẹ̀dógún, ọdún 1966, tó sì ṣàtìlẹyìn fún ọ̀gágun Chukwuma Kaduna Nzeogwu ṣùgbọ́n tí ìdìtẹ̀gbàjọba náà kò bọ́ si.

Lásìkò ìṣèjọba gẹ́gẹ́ bí gómìnà ológun, ó gbé ètò kalẹ̀ láti mu ní dandan fáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà láti máa tọ́jú àyíká wọn.

  • Sẹ́nétọ̀ George Akume

Sẹ́nétọ̀ George Akume ni akọ̀wé ìjọba Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí.

Òun ni Mínísítà fún àwọn àkànṣe iṣẹ́ àti ètò ìjọba síra láàárín ọdún 2019 sí 2023 lábẹ àkóso ààrẹ Muhammadu Buhari.

Ó ṣojú ẹkùn Benue North-West ní ilé aṣòfin àgbà láàárín ọdún 2007 sí 2019.

George Akume ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Benue láàárín ọdún 1999 sí 2007.

Ní ọdún 2018 ni Akume di ẹ̀bi ìkọlù tó ń wáyé láàárín àwọn darandaran àtàwọn àgbẹ̀ ru ìjọba ìgbà náà.

Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdún 1953 ni wọ́n bí Akume tó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ Sociology ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Ibadan.

  • Gabriel Torwua Suswam

Ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 1964 ni wọ́n bí Gabriel Suswam ní ìlú Anyiin, ìjọba ìbílẹ̀ Logo.

Láàárín ọdún 1999 sí 2007 ló ṣojú ẹkùn Katsina-Ala/Ukum/Logo ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Abuja.

Ọdún 2007 ni wọ́n yàn-án sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Benue, tó sì lo sáà méjì lórí ipò náà.

Ọdún 2009 ló sọ pé ó yẹ kí wọ́n máa yan àwọn olóṣèlú tó bá ṣe dada sípò fún sáà míì láì ṣe ìpolongo ìbò kankan.

  • Samuel Ortom

Samuel Ortom ni gómìnà ìpínlẹ̀ Benue tó wà lórí ipò gba àkóso lọ́wọ́ rẹ̀ lọ́dún 2023.

Ó ti fìbà kan rí jẹ́ mínísítà kejì lórí ètò ìdókoòwò àti ọrọ̀ ajé lábẹ́ àkóso ìṣèjọba ààrẹ Goodluck Jonathan.

Ọjọ́ Kẹtàlélọgún, oṣù Kẹrin, ọdún 1961 ni wọ́n bí Ortom ní ìjọba ìbílẹ̀ Guma ní ìpínlẹ̀ Benue.

Ní ọdún 2017, lẹ́yìn ọdún méjì tó gba àkóso Benue, ni buwọ́lu òfin pé àwọn darandaran k]o gbọdọ̀ da ẹran jẹko ní gbangba ní ìpínlẹ̀ Benue lẹ́yìn ìkọlù àwọn darandaran ṣokùnfà ikú ọ̀pọ̀ èèyàn.

Ó ní òun gbàgbọ́ pé òfin náà máa mú òpin bá ìkọlù lemọ́lemọ́ náà ṣùgbọ́n síbẹ̀, níṣe ni ìkọlù láàárín àwọn darandaran àti àgbẹ̀ ń le si ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Kí ni iṣẹ́ tí ìgbìmọ̀ náà yóò ṣe?

Ààrẹ Tinubu nígbà tó ń gbé ìgbìmọ̀ náà kalẹ̀ níbi ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tó wáyé ní ìpín lẹ̀ nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí wọn lórí ìkọlù náà sọ pé ìgbìmọ̀ náà ní iṣẹ́ láti wá ọ̀nà bí àlááfíà ṣe máa jọba ní ìpínlẹ̀ Benue.

Tinubu ní òun ti ṣetán láti dókoòwò lórí bí àlááfíà ṣe máa jọba àti pé àwọn gbọdọ̀ wá ọ̀nà láti sọ wàhálà tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Benue di ohun tó máa mú ìlọsíwájú bá ìpínlẹ̀ náà.

Ó fi kun pé ìlàkàkà ìgbìmọ̀ náà láti jẹ́ kí àlááfíà jọba yóò so èso rere nígbà tí gbogbo èèyàn bá sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ papọ̀, tó sì pè fún àtìlẹyìn àwọn ìpínlẹ̀ tó súnmọ́ Benue bíi Nasarawa.

Ó ní pé káwọn èèyàn ìgbìmọ̀ náà jẹ́ kí àwọn pàdé ní Abuja láti mọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbé bí wọ́n ṣe wá ojútùú sí ètò ààbò náà gbà.

Kí lo ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ni Benue ti ipinlẹ naa fi nilo igbimọ apẹtusawọ?

Ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàlá mọ́ òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kẹfà ni ìkọlù tuntun míì wáyé ní ìlú Yelwata, ìjọba ìbílẹ̀ Guma ní ìpínlẹ̀ Benue níbi tí àwọn aláṣẹ ti sọ pé èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló pàdánù ẹ̀mí wọn.

Óṣojúmikòró kan ní àwọn darandaran tó gbé ìbọn dání ló kọlu agbègbè náà, tí wọ́n sì tún kojú àwọn ọlọ́pàá.

Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ni àwọn tó ṣèkọlù sí ìlú náà tún dáná sun.

Èyí mú kí àwọn ọ̀dọ́ ìlú náà tú síta lọ́jọ́ Àìkú láti fi ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí ìṣekúpani tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní agbègbè náà.

Ọ̀pọ̀àwọn èèyàn tó fi mọ́ àwọn lọ́ọ́kọ lóòkì ní Nàìjíríà tó fi mọ́ Atiku Abubakar ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà.

Èyí ló mú ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu, lẹ́yìn tó fi àtẹ̀jáde léde láti bá àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Benue kẹ́dùn, ṣàbẹ̀wò síbẹ̀ lọ́jọ́rú.

Tinubu ní òpin gbọdọ̀ dé bá ìkọlù tó ń wáyé ní Benue ní gbogbo ìgbà náà.