Kókó ọ̀rọ̀ tí ààrẹ Bola Tinubu sọ lásìkò tó ṣàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Benue

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ Bola Tinubu ti kede awọn erongba rẹ lati wa ojutu si iṣoro ija awọn agbẹ ati darandaran to n waye lemolemo nipinlẹ Benue.

Aarẹ sọ eyi lasiko abẹwo to ṣe si ipinlẹ naa lati ṣe abẹwo si awọn eeyan to farapa lasiko ikọlu awọn agbebọn to waye ni ilu Yelwata.

Tinubu kede idasilẹ igbimọ awọn olori ti yoo wa bi alaafia yoo ṣe jọba lẹyin ọpọ ọdun ti ija yii ti n waye.

O ni igbimọ yii ni yoo aṣoju ati awọn ladelade bi Tor Tiv V, Och'Idoma, ati awọn olori ilu mii nipinlẹ naa, ti wọn yoo si pade niluu Abuja fun ipade lati wa ojutu si iṣoro naa.

Bẹẹ ba gbagbe, ikọlu awọn agbebọn yii ṣekupa eeyan to le ni aadọta ni iye ti ọpọ si farapa yanayana.

"Mo fẹ ki a da igbimọ olori silẹ bayii, ki a wa pade niluu Abuja lati wa ọna abayọ fun alaafia lati jọba. Mo ṣetan lati lọwọ ninu alaafia yii.

"Mo fẹ ki awọn olori ilu bii Tor Tiv ati Ochidoma wa ninu igbimọ alaafia yii. Mo mọ pe bayii o tis u yin lati ma gbọ ohun ṣugbọn mo n fun yin idaniloju pe a ma wa ọna abayọ, a o sọ ibanujẹ di ilọsiwaju."

Mo n reti iroyin pe ẹ ti mu awọn ọdaran yii - Tinubu

Aarẹ Tinubu tun tẹnu mọ idi pataki to fi ṣe koko fun awọn ọmọ Naijiria lati fọwọ sowọpọ dipo ki wọn ba ara wọn ja.

Bakan naa ni aarẹ tun gba awọn olori Ologun ati Ọga fun ileeṣẹ ọlọpaa, Kayode Egbedokun ni iyanju lati ṣawari awọn eeyan to lọwọ ninu ikọlu naa.

"Ọlọpaa, mo lero pe awọn ọmọ Ologun yii wa ni itọsi lati tẹti silẹ fun iroyin yẹ. Baw oni wọn ṣe ti mu eeyan kankan bayii? Mo reti pe ma ti gbọ pe ẹ ti mu awọn ọdaran yii.

"Christopher, o ti ṣe ọpọ. Mo gbọ ọrọ rẹ, o ni jẹ ko rẹ lati wa ninu igbo. Oloyede ati ọga ologun Air Marshal, a dupẹ lọwọ yin ṣugbọn a ni tẹ eti wa silẹ, ka ṣawari awọn ọdaran yii.

A bẹ aráàlú láti tú jáde, tó sí ẹ̀gbẹ́ òpópónà láti ṣàyẹ́sí Ààrẹ Tinubu tó wá ṣe àbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí wa - Ìjọba Benue

Ijọba ipinlẹ Benue ti ke si awọn eeyan ipinlẹ naa lati ṣayẹsi Aarẹ Bola Tinubu lasiko abẹwo rẹ sipinlẹ naa lonii Ọjọru.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu lẹta kan ti ijọba ipinlẹ ọhun fi ṣọwọ si awọn aṣaaju kan atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ipinlẹ ọhun.

Ṣaaju ni Tinubu ti kọkọ sọ pe oun yoo wọgile irinajo to yẹ ki oun ṣe si ipinlẹ Kaduna, ti oun yoo si lọ si Benue lati lọ ba awọn eeyan ipinlẹ naa kẹdun lẹyin ikọlu to waye nibẹ lọsẹto kọja.

Eyii ko ṣẹyin bi awọn afurasi darandaran ṣe kọlu abule kan nibẹ ti wọn si gbẹmi eeyan to le ni ọgọrun un.

Ki lo wa ninu lẹta ti ijọba kọ?

Gẹgẹ bii ohun to wa ninu lẹta ti Francis U Ngutswen, to jẹ oluranwọ agba fun ijọba lori akanṣe iṣe kọ, gbogbo awọn eeyan gbọdọ tu jade lati wa pade Aarẹ, ki wọn si yẹ si lati papakọ ofurufu.

O ni ki awọn eeyan to ara wọn lọwọwọ bii ọmọ ile ẹkọ soju ọna papakọ ofurufu ipinlẹ naa titi de oju ọna olobiripo Wurukum titi de ile ijọba to wa niluu Makurdi nibi ti Aarẹ yoo ti ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọrọ.

O fi kun pe iye eeyan ti wọn yoo gba wọle yoo da lori iye eeyan to ba yọju ati awọn aṣọ ti wọn ba wọ.

Lẹyin naa lo ni ki awọn eeyan ọhun kan si ọofisi oun fun ẹkunrẹrẹ nipa bi eto naa yoo ṣe lọ.

Ko si ohun to n jẹ ija laarin awọn agbẹ atawọn darandaran ni Benue, awọn ẹranko lo fẹ wa gba oko – Ileeṣẹ ọmọ ogun

Olori ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, ọgagun Christopher Musa, ti sọ pe ko si ohun to n jẹ ija laarin awọn agbẹ atawọn darandaran ni Naijiria, ati pe awọn to n da ẹranko n lọ da fa wahala ninu oko oloko.

Nigba to n ba awọn obinrin sọrọ ni Benue, o mẹnuba ohun mẹta pataki to n fa iṣẹkupani lemọlemọ nipinlẹ naa atawọn agbegbe mii ni Naijiria.

O ṣalaye pe ijọba gbọdọ wa ojutu si ọrọ awọn to n ko ẹran lati ilu kan lọ si omiran ko to pẹ ju.

Musa tun mẹnuba ọrọ ilẹ to n da ija silẹ laarin awọn oniluu atawọn alejo.

Ọga ileeṣẹ ọmọ ogun naa sọ pe niwọn igba ti awọn darandaran ko ba ko ẹran jẹ oko kaakiri mọ, pupọ ninu awọn iṣọro ati laasigbo yii ni yoo di ohun igbagbe.

O ni "Iṣoro meji tabi mẹta lo n fa wahala yii, akọkọ ni ọrọ ilẹ laarin awọn ọmọ oniluu atawọn alejo.

"Ekeji ni bi wọn ṣe n ko ẹran jẹ oko kaakiri. Mo ti sọ fun awọn eeyan pe ti wọn ba n so nipa ija laarin agbẹ atawọn darandaran… amọ ti oko ba wa ni tirẹ ti ẹranko wa sibẹ, kii ṣe ija laarin eeyan meji, o n tumọ si pe ẹnikan lo lọ sori ilẹ ẹlomii.

"A ni lati wa ojutu si ọrọ yii, ti ẹranko ko barin kaakiri mọ, ko ni si wahala yii."