Ààrẹ Israel ní òun ń gbèrò láti gbẹ̀mí aṣaajú ilẹ̀ Iran, bí àdó ikú tó jábọ́ sórí iléeṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Iran, ṣe gbẹ̀mí òṣìṣẹ́ méjì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ni iroyin sọ pe o ti fontẹ lu igbesẹ orilẹede Israel lati gbẹmi asaaju ilẹ Iran, Ayatollah Ali Khamenei.

Amọ lasiko to n ba ileesẹ iroyin ABC sọrọ ni wakati diẹ sẹyin, Olootu ijọba ilẹ Israel, Benjamin Netanyahu daba pe oun n gba lero lati gbe igbesẹ naa.

O ni "gbigba ẹmi Khamenei yoo mu opin de ba aawọ to n waye naa, ti yoo si dena ki ogun ado oloro lilo bẹrẹ.

Ki wa ni yoo sẹlẹ si Khamenei, tii se asaaju to tii pẹ julọ nipo, ẹni to maa n tẹnumọ lọpọ?

Ado iku Israel bọ sori ileesẹ agbohunsafẹfẹ Iran, eeyan meji ku

Awọn ileesẹ iroyin ni orilẹede Iran ti kede pe ọpọ ado oloro lo n bu, ti wọn si n tiraka lati daabo bo oju ofurufu lọwọ ina nilu nidaji oni.

Ni ooru mọjumọ aarọ yii, orilẹede Iran ju awọn isọri ọpọ ado oloro lati gbẹsan ikọlu ti ilẹ Israel n se, eyi to n pe akiyesi pe ikọlu n waye lawọn apa aarin gbungbun ati ariwa ilẹ Israel.

Bi o tilẹ jẹ pe ikọlu naa ko lagbara to awọn eyi to waye ni alẹ ọjọ melo kan, sibẹ, iroyin ni wọn ko ni ipa kankan tabi se ijamba fun ẹnikẹni.

Nigba to n ba ileesẹ tẹlifasan ilẹ Iran to wa nilu London sọrọ, Olootu ijọba ilẹ Israel, Benjamin Netanyahu salaye pe orilẹede oun ti ba ọpọ ado oloro ilẹ Iran jẹ, amọ ikọ ọmọ ogun rẹ si nilo akoko diẹ si.

Wayi o, eeyan meji lo ti ku nigba ti ado oloro Israel kọlu ileesẹ agbohunsafẹfẹ to jẹ tilẹ Iran.

Gẹgẹ bi iwe iroyin ilẹ Iran, IRNA t iwi, Olootu iroyin ati osisẹ miran ni ileesẹ agbohunsafẹfẹ Islamic Republic of Iran Broadcasting (IRIB) lo jade laye nigba ti ado oloro ti Israel ju jabọ sori olu ileesẹ naa lọjọ Aje.

Awọn fidio to jade sori ayelujara lasiko ti wọn gbe iroyin sori afẹfẹ safihan ariwo ibugbamu nla, ti ina inu ibudo igberoyin jade si ku, bi awọn ogiri se wo lulẹ ni ibudo iroyin naa.

Amọ lẹyin wakati diẹ ti ikọlu naa waye, ileesẹ agbohunsafẹfẹ IRIB bẹrẹ isẹ pada.

'"Trump ge irinajo rẹ sibi ipade G7 kuru, o pada sile tori ikọlu to n waye ni agbegbe Middle East"

Tun wẹ, ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan lo ti n sa kuro nilu Tehran bayii, ti lilọ bibọ ọkọ si mu akọlu-kọgba lọwọ bo se n waye lẹnu ọjọ melo kan ti wahala naa bẹrẹ.

Idile kan wa to kuro nilu Tehran, to si yẹ ko lo wakati mẹta de ibi ti wọn n lọ amọ wakati mẹrinla ni wọn papa lo tori aklu-kọgba ọkọ ati ero.

"Gbogbo oju popo lo ti di, koda, ko mu ọgbọn dani lati lọ ha sinu akọlu-kọgba ọkọ naa lasiko yii"

Bi ẹ ko ba gbagbe, olootu ijọba ilẹ Israel, Benjamin Netanyahu lo kede lana pe kawọn olugbe ilu Tehran fi ilu naa silẹ, ti aarẹ ilẹ Amẹrika naa si kin lẹyin pe ki gbogbo eeyan kuro ni olu ilu ilẹ Iran mọjumọ oni.

Nibayi, aarẹ Donald Trump ti ge irinajo rẹ sibi ipade G7 to n waye nilẹ Canada kuru.

Ninu ikede to gbe soju opo ayelujara X rẹ, akọwe iroyin fun aarẹ Amẹrika, Karoline Leavitt salaye pe aarẹ pada sile nitori "ikọlu to n waye ni agbegbe Middle East".

Israel ní káwọn aráàlú kúrò ní Tehran, pé àwọn ti gba àkóso gbogbo ojú òfurufú

Iléeṣẹ́ ológun Israel, IDF ti sọ fáwọn èèyàn ní Tehran, olí ìlú Iran láti kúrò ní agbègbè náà kíákíá.

IDF sọ pé àwọn máa ṣèkọlù sáwọn iléeṣẹ́ ìpèsè ohun ìjà olóró láwọn agbègbè kan ní Tehran.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun Israel, Avichay Adraee nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí ìkànnì X rẹ̀ ṣàgbéjáde àwọn àwòrán àwọn máàpù ibi táwọn èèyàn ti gbọdọ̀ kúrò.

Ó ṣèkìlọ̀ pé káwọn èèyàn kúrò ní agbè gbè District 3 máàpù náà nítorí ó léwu fún ẹ̀mí wọn.

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba Iran ti sọ pé sísọ fáwọn èèyàn láti kúrò ní ìlú jẹ́ ọ̀nà táwọn ọ̀tá máa ń lò láti fi gba jagun.

Agbẹnusọ ìjọba Iran, Fatemeh Mohajerani tún sọ pé ojú òpó íńtánẹ́ẹ̀tì kò ti ṣe dáadáa mọ́ láti kojú àwọn ìkọlù orí ayélujára tó ń wáyé ní orílẹ̀ èdè náà.

Ṣáájú ni iléeṣẹ́ ológun Israel ti ṣèkìlọ̀ pé àwọn aráàlú Iran ló máa forí kó ìkọlù tí Iran ṣe sáwọn èèyàn rẹ̀, tí wọ́n sì sọ pé káwọn aráàlú kúrò ní Tehran.

Israel ní gbogbo àwọn agbègbè tó súnmọ́ ibi tí Iran ti ń pèsè nǹkan ìjà ogun ni kí wọ́n kúrò ní ibi tí wọ́n wà.

Gẹ́gẹ́ bí nǹkan táwọn èèyàn ń sọ ní Tehran, níṣe ni gbogbo ojú òpó dí, tí ọ̀pọ̀ kò sì ríbi jáde kúrò nínú ìlú Tehran.

Olùgbé Tehran kan sọ fún BBC pé òun ṣì máa wà ní Tehran nítorí kò sí ibi tí òun ń lọ. ó ní òun kò ní ẹ̀bí àti ọ̀rẹ́ láwọn agbègbè míì.

Àwọn èèyàn ní ìwọ̀ oòrùn Tehran sọ pé níṣe ni àwọn ń gbọ́ tí àdó olóró ń dún lákọlákọ.

Àwòrán àti fídíò tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí èẹfí ṣe ń tu jáde ní ẹ̀gbẹ́ àwọn orí òkè tí Israel ń ju àdó olóró sí.

A ti gba gbogbo àkóso ojú òfurufú Tehran - Israel

Orílẹ̀ èdè Israel ní àwọn ti gba gbogbo àkóso ojú òfurufú Tehran tó jẹ́ olú ìlú Iran. Èyí le jẹ́ òótọ́ pẹ̀lú bí Israel ṣe ń onírúurú ìkọlù sí ìlú náà láti bíi ọjọ́ méjì tí ìkọlù náà ti bẹ̀rẹ̀.

Àwọn ọkọ̀ òfurufú Israel ló ti ń ju àdó olóró sí Iran láti ọ̀nà tí kò jìnà rárá. Èyí túmọ̀ sí pé wọn kò nílò láti lo àwọn àdó olóró tó jìnà láti ṣe ìkọlù.

Àwọn ọkọ̀ òfurufú ìjagun Iran ni wọ́n ti ń gbó lọ, tí Israel sì ti ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìjà òfurufú Iran jẹ́ ṣáájú ìkọlù yìí.

Ní oṣù Kẹwàá ọdún tó kọjá tí Israel ṣe ikọlù sí Iran, àwọn ohun ìjà ogun tó jẹ́ èyí tó lè ju àdó olóró láti ọ̀nà jínjìn ni Israel dojú ogun rẹ̀ kọ, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti bá àwọn ohun ìjà òfurufú Iran jẹ́ nínú ìkọlù tuntun yìí.

Justin Bronk ti iléeṣẹ́ Royal United Services Institute sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Israel ń rí ọwọ́ mú lórí òfurufú Tehran báyìí kò túmọ̀ sí pé Israel lágbára ju Iran lọ.

Àwọn àdó olóró tí yínyìn wọn kò jìnà ṣì jẹ́ ohun ìdúnkokò tí Iran sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn.