You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìkọlù Israel àti Iran: Kí ni àwọn nǹkan tó burú tó le ṣẹlẹ̀?
- Author, James Landale
- Role, Diplomatic correspondent
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ní báyìí àárín Israel àti Iran nìkan ni ìkọlù ṣì ti ń wáyé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé tó fi mọ́ àjọ ìṣọ̀kan ti ń ṣe ìkọlù fún wọn láti dáwọ́ ogun dúró.
Ṣùgbọ́n tí àwọn orílẹ̀ èdè ná[bá kọ́ láti gbọ́ ìkìlọ̀ ńkọ́? Tí ogun náà bá fẹjú si, tó sì kan àwọn orílẹ̀ èdè míì?
Àwọn nǹkan tó burú tó lè ṣẹlẹ̀ nìwọ̀nyí.
Wíwọ́ Amẹ́ríkà sínú ogun náà
Pẹ̀lú bí Amẹ́ríkà ṣe ń jiyàn pé àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù tí Israel ṣe sí Iran ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì, Iran gbàgbọ́ pé Amẹ́ríkà buwọ́lu ìgbésẹ̀ Israel àti pé wọ́n ṣe àtìlẹyìn fún Israel lórí ìkọlù ọ̀hún.
Iran le ṣe ìkọlù sáwọn iléeṣẹ́ tó jẹ́ ti Amẹ́ríkà tó wà lẹ́kùn Middle East bíi iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tó wà ní Iraq, iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tó wà ní Gulf àtàwọn míì. Bákan náà ni ikọ̀ ọmọ ogun Hezbollah àti Hamas - bí wọ́n kò lágbára tó bẹ́ẹ̀ mọ́ – tó wà ní Iraq ṣì dúró digbí.
Amkríkà ti wòye pé irúfẹ́ ìkọlù báyìí le wáyé sáwọn nǹkan ìní rẹ̀, èyí ló ṣe pàṣẹ fáwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó wà ní agbègbè náà láti kúrò. Nínú àtẹ̀jáde ti US fi síta, Amẹ́ríkà ṣèkìlọ̀ fún Iran láti má dojú kọ nǹkan ìní àwọn kankan.
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá ṣekúpa ọmọ Amẹ́ríkà ní Tel Aviv tàbí ibòmíràn?
Ó ṣeéṣe kí ààrẹ Amẹ́ríkà Donald Trump fẹ́ jà padà. Láti ọjọ́ pípẹ́ ni wọ́n ti ń fẹ̀sùn kan olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu pé ó ń fẹ́ kí Amẹ́ríkà ṣe ìrànwọ́ fún òun láti rẹ́yìn Iran.
Àwọn onímọ̀ nípa ogun sọ pé Amẹ́ríkà nìkan ló ní pawọn àdó olóró àtàwọn nǹkan ìjà ogun tó le wọ àwọn ibi tí Iran ń kó nǹkan ìjà ogun sí pàápàá èyí tó wà ní Fordow.
Trump ti ṣèlérí fáwọn èèyàn rẹ̀ pé òun kò ní bẹ̀rẹ̀ ogun kankan tí yóò lọ fún ìgbà pípẹ́ ní ẹkùn Middle East. Àmọ́ àwọn kan tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Republican ni wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fún ìjọba Israel lórí ìkọlù náà pẹ̀lú èrò pé àsìkò tit ó láti mú àyípadà bá ìjọba ní Tehran.
Tí Amẹ́ríkà bá fi lè kópa níbi ogun yìí, yóò mú kí ogun náà gùn bí ó ṣe yẹ lọ pẹ̀lú ipa tó lágbára.
Ó ṣeéṣe káwọn orílẹ̀ èdè Gulf dá sí ogun náà
Tí Iran kò bá ríbi dojú àwọn ọmọ ogun Israel àtàwọn nǹkan ìní Israel bolẹ̀, ó ṣeéṣe kí wọ́n fẹ́ ṣe ìkọlù sáwọn iléeṣẹ́ Israel tò wà láwọn orílẹ̀ èdè Gulf pàápàá àwọn orílẹ̀ èdè tí Iran gbàgbọ́ pé wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fáwọn tó jẹ́ ọ̀tá òhun.
Ọ̀pọ̀ àwọn ohun àmúṣagbára àti ohun amáyédẹr]un ló wà ní ẹkùn náà. Ẹ ó rántí pé wọ́n fẹ̀sùn kan Iran pé ó ṣèkọlù sí ọgbà epo Saudi Arabia lọ́dún 2019 àti UAE lọ́dún 2022.
Láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń gbìyànjú láti parí aáwọ̀ láàárín Iran àtàwọn orílẹ̀ èdè kan lẹ́kùn náà.
Ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀ èdè yìí ni iléeṣẹ́ ológun US ń fi wọ́n ṣe ibùgbé. Bákan náà ni ìgbàgbọ́ wà pé àwọn kan ṣe ìrànwọ́ láti gba Israel sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àdó olóró tí Iran jù si lọ́dún tó kojá.
Tí wọ́n bá ṣe ìkọlù sáwọn orílẹ̀ èdè Gulf, ó máa nílò kí Amẹ́ríkà kó àwọn òfurufú ogun rẹ̀ jáde láti fi dá ààbò bò wọ́n àti tàwọn Israel náà.
Kí Israel má rì í àwọn nǹkan ìjà ogun Iran kọlù sí
Tí ìkọlù Israel kò bá so èso rere ńkọ́? Tó bá jẹ́ pé ààbò wà fáwọn iléeṣẹ́ tí Iran ń kó àwọn ohun ìjà ogun "nuclear weapon" ju bí wọ́n ṣe rò lọ? Tó bá jẹ́ pé wọn kò rí uranium oní kìlógíráàmù irinwo (400kg) – tó ṣe é pèsè àdó olóró mẹ́wàá – bàjẹ́ ńkọ́?
Èròńgbà wà pé bóyá inú ilẹ̀ ni Iran lọ tọ́jú àwọn ohun ìjà náà sí. Israel le ti ṣekúpa àwọn onímọ̀ nípa àwọn ohun ìjà ogun yìí àma kò sí àdó olóró tó le pa àwọn onímọ̀ Iran.
Tó bá jẹ́ pé ìkọlù Israel yìí jẹ́ ìtanijí fún àwọn aláṣẹ Iran pé àwọn nílò láti tètè ṣe àwọn àdó olóró láti dènà irúfẹ́ ìkọlù yìí lọ́jú iwájú?
Tó bá jẹ́ pé àwọn olórí iléeṣẹ́ ológun Iran tó wà níbẹ̀ báyìí ní agídí ju àwọn tó ti jáde láyé lọ?
Èyí le mú kí Israel àti Iran le máa tẹ̀síwájú ìkọlù síra wọn fún ìgbà pípẹ́.
Ipa lórí ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé
Owó epo ti ń gbówó lórí lẹ́nu ìgbà tí ìjà ti bẹ̀rẹ̀.
Tí Iran bá lọ ti Strait of Hormuz, tí wọn kò jẹ́ kí epo kọjá níbẹ̀?
Tó bá jẹ́ pé – ní òdìkejì ilẹ̀ Aran – àwọn Houthis ní Yemen pọnkún akitiyan wọn láti ṣèkọlù sáwọn ọkọ̀ ní odò Red Sea? Àwọn nil ó jẹ́ alátìléyìn Iran báyìí.
Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ni wọ́n ń kojú àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé. Alékún owó epo tún máa mú kí ọ̀wọ́ngógó tún lékún si.
Ẹni tí yóò sì jẹ́ àǹfàní yìí jùlọ ni ààrẹ Putin ti Russia tó máa rí àlékún nínú owó tó ń wọlé fún-un láti fi ra nǹkan ogun lórí ogun tó ń gbé ti Ukraine.
Kí ìṣèjọba Iran jábọ́
Tí Israel bá lọ ṣàṣeyọrí pẹ̀lú èròńgbà rẹ̀ láti dojú ètò ìṣèjọba ìlànà ẹ̀sìn Islam bolẹ̀ ní Iran?
Netanyahu sọ pé èròńgbà àwọn ní Iran ni láti bá àwọn ohun ìjà ogun tí wọ́n ń kó jọ jẹ́. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sọ lẹ́yìn ìkọlù ọjọ́ Ẹtì, ó sọ̀rọ̀ lórí èròńgbà láti mú àyípadà bá ìṣèjọba ní Iran.
Ó sọ pé ìkọlù náà jẹ́ ojúnà lári ri pé àwọn èèyàn Iran rí ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ìjọba tó ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀.
Dídojú ìjọba Iran bolẹ̀ yóò dùn mọ́ àwọn kan nínú ní ẹkùn náà pàápàá àwọn ọmọ Israel àmọ́ ipa wo ló máa fi sílẹ̀? Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló máa ti ìdí rẹ̀ yọ?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa rántí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Iraq àti Libya nígbà tí ìjọba wọn lulẹ̀.
Ọ̀pọ̀ ló ń retí ohn tí ìkọlù máa já sí lọ́jọ́ iwájú.
Báwo ni ìpadàbọ̀ Iran ṣe máa le tó? Ṣé Amẹ́ríkà le dá Israel lẹ́kun?