Bí ìkọlù tó ń wáyé láàárín Israel àti Iran ṣe le nípa lórí owó epo

    • Author, Lucy Hooker
    • Role, Business reporter, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìkọlù tó ń wáyé láàárín Israel àti Iran, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹfà, ti ń fa inú fu àyà fu ní ọjà àgbáyé.

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni owó epo ti gbówó lórí, tó sì ti lékún pẹ̀lú ìdá méje 7% nígbà tó fi máa di ọ̀sán ọjọ́ Ẹtì.

Èyí ti ń mú káwọn èèyàn máa kọminú pé ṣe àwọn kò tún ní kojú àlékún owó lórí àwọn ohun àmúṣagbára, tó le mú àlékún bá owó bẹntiróòlù àti oúnjẹ.

Irúfẹ́ èyí ló wáyé nígbà tí Russia ṣe ìkọlù sí Ukraine ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn èyí tó ní ipa lórí ìgbé ayé àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé.

Báwo ni owó epo ṣe ti lọ sókè sí?

Ìkọlù náà ni ipa lórí ọjà àgbáyé lójú ẹsẹ̀.

Epo rọ̀bì Brent Crude – èyí tí wọ́n ń lò lọ́jà àgbáyé – lọ sókè pẹ̀lú ìdá mẹ́wàá kó tó padà sí $75 fún àgbá kan.

Gbogbo ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ gbòógì bá ń wáyé láwọn ẹkùn tó ṣe kókó ní àgbáyé, níṣe ni owó máa ń lọ sókè tàbí kó rí ìjáwálẹ̀, tó fi mọ́ ọjà àgbáyé.

Èyí ni kò jẹ́ kó ya èèyàn lẹ́nu pé ìkọlù náà ní ipa lórí owó epo kíákíá.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀, owó epo rọ̀bì Brent ṣì wà ní àdínkù pẹ̀lú ìdá mẹ́wàá sí iye tó jẹ́ lọ́dún 2023.

Bákan náà ló ṣì dínkù sí iye tó jẹ́ nígbà tí Russia kọlu Ukraine lọ́dún 2022 nígbà tí owó epo wọ $130 fún àgbá kan.

Ṣé owó bẹntiróòlù àtàwọn míì ti gbówó lórí?

Nígbà tí owó epo rọ̀bì bá lọ sókè lọ́jà àgbáyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí mọ̀ àyàfi tí owó epo bẹntiróòlù bá lé kún.

Àmọ́ tí owó àwọn ohun àmúṣagbára bá ti lé kún ni ọ̀pọ̀ nǹkan náà máa gbówó lórí tó fi mọ́ èrè oko, oúnjẹ [[ati ìpèsè ọjà.

Ní ti oúnjẹ, àlékún owó ohun àmúṣagbára le jẹ́ kí owó oúnjẹ lé kún. Tí owó epo bá ti lọ sókè ni yóò ṣòro láti ṣàmúlò àwọn ẹ̀rọ láti fi pèsè oúnjẹ, gbé oúnjẹ lọ sí ibi tí wọ́n ti máa pèsè wọn àti láti tà wọ́n.

Ṣùgbọ́n èyí le rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí owó epo bá lọ sókè fún ìgbà pípẹ́.

Kódà pẹ̀lú epo bẹntiróòlù àti dísù, àlékún owó epo ní ibi tó le ní ipa mọ.

David Oxley ti Capital Economics sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn yóò rántí bí owó epo àtàwọn nǹkan míì ṣe gbówó lórí nígbà tí ìkọlù Ukraine kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.

Ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fi gáàsì tanná sílé tó sì jẹ́ pé owó gáàsì ló máa ń sọ iye tí owó iná mọ̀nàmọ́ná máa jẹ́ ní UK.

Ó fi kun pé owó gáàsì ti lọ sókè lẹ́yìn ìkọlù náà tó sì jẹ́ pé àwọn èèyàn máa rí ipa rẹ̀ díẹ̀díẹ̀.

Ṣé owó epo tún máa lọ sókè si?

"Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nílẹ̀ yìí jẹ́ èyí tó ṣe kókó tó sì ń koni lóminú," Richard Bronze, ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ Energy Aspects, iléeṣẹ́ tó wà fún ìwádìí sọ fún BBC.

Àmọ́ ó ní kò túmọ̀ sí pé ó le ní ipa bíi ti ìkọlù Russia àti Ukraine tàbí àwọn ìkọlù tó ti wáyé sẹ́yìn lẹ́kùn Middle East.

Ó ṣàlàyé pé ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jùlọ báyìí ni pé báwo ni ìjà tó ń wáyé láàárín Israel àti Iran yìí ṣe máa pẹ́ sí, ṣé orílẹ̀ èdè míì yóò darapọ̀ mọ́ wọn àti pé ṣe Amẹ́ríkà máa dá si láti báwọn parí aáwọ́ náà?

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó dá lórí bí wọ́n bá ṣe ń rí epo gbé gba orí omi Strait of Hormuz, orí omi tí wọ́n ń gbé ìdá márùn-ún epo ọjà àgbáyé gbà.

Bronze sọ pé tí kò bá sí ìdádúró pẹ̀lú gbígbé epo, ó ṣeéṣe kí owó má lé kún si.

Lọ́dún 2022, lẹ́yìn tí Russia ṣe ìkọlù Ukraine, báwọn èèyàn ṣe ń bèèrè fún epo rọ̀bì ló sókè lẹ́yìn tí ọjà àgbáyé ṣí lẹ́yìn Covid.

Ní báyìí tí ọjà àgbáyé ń kojú ìgbà tó le, táwọn olùpèsè epo láti Saudi Arabia sí Brazil sì ní ìkápá láti pèsè epo si, ó le ṣeéṣe láti mú àdínkù bá owó epo.

Kíni èyí túmọ̀ sí fún ọjà àgbáyé?

Bí owó bá ṣe lọ sókè sí pẹ̀lú ipa tó bá ní ni yóò sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lórí ìkọlù Israel àti Iran.

Ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kó jk ìjayà tí kò dára fún ọjà àgbáyé lásìkò tí kò dára gẹ́gẹ́ bí Mohammed El-Erian tó jẹ́ olùmọ̀ràn fún ètò ọrọ̀ ajé Allianz ṣe sọ.

Ó ní gbogbo ojú kó wù kí èèyàn fi wò ó, ó ní ipa tí kò dára.

Capital Economics wòye pé bí owó epo bá padà sí $100 àgbá kan, ó le mú ìdá kan kún ọ̀wọ́ngógó fáwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà.

Ó ní èyí yóò mú ìṣòro bá àwọn ilé ìfowópamọ́ àgbà tí wọ́n ń gbìyànjú láti mú ọ̀wọ́ngógó já walẹ̀.

Fún David Oxley, ìwòye tirẹ̀ yàtọ̀, ó ní ìgbà àkọ́kọ́ tí ìkọlù ń wáyé lẹ́kùn Middle East.

"A ti rí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí tó ń wáyé lọ́pọ̀ ìgbà, ó ṣeéṣe kí nǹkan lọ sókè láàárín ọ̀sẹ̀ kan."