Kí ni ohun àràmàǹdà tí Cristiano Ronaldo tún ṣe tó ń da ojú òpó Youtube àti ayélujára láàmú?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja agbabọọlu ọmọ orileede Portugal nni, Cristiano Ronaldo lo tun ti fi itan tuntun balẹ lagbaye, pẹlu bi ikanni ori YouTube to ṣẹṣẹ ṣi ṣe wọ ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu laarin wakati perete.

Eyii la gbọ pe ko ṣẹlẹri ninu itan lori ayelujara, to si jẹ pe oun ni ẹni akọkọ ti yoo fi itan naa balẹ.

Agbabọọlu ọwọ iwaju ikọ ẹgbẹ agbabọọ Al-Nassr naa lo ṣi ikanni amohunmaworan ori ayelujara ti a mọ si YouTube l’Ọjọru to kọja yii.

Itan tuntun naa lo mu ki awọn alaṣẹ ati alakoso ileeṣẹ YouTube fi ẹbun nla rabandẹ ta Ronaldo ti awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye tun n pe ni CR7 lọrẹ.

Aami ẹyẹ goolu ni wọn fi ranṣẹ si Ronaldo lẹyin bii wakati diẹ ti awọn to n tẹle lori ikanni naa ti pọ kọja sisọ.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti Ronaldo yoo maa fi itan balẹ lori ayelujara, oun ni ẹni kan ṣoṣo to ni ololufẹ to pọ julọ lori ikanni Instagram, pẹlu ololufẹ to le lẹgbẹta (636m) miliọnu.

Yatọ si ileeṣẹ Facebook funra rẹ to ni aadọwaa miliọnu (190m) ololufẹ, ko tii si ẹni to tun tii ni ololufẹ to to Ronaldo lori ikanni Facebook, nibi to ti ni aadọsan miliọnu (170m).

Bakan naa lori ikanni Twitter, Ronaldo ni ẹnikẹta ti awọn eeyan tun n tẹle julọ pẹlu ololufẹ miliọnu mejilelaadọfa (112.6m), lẹyin Elon Musk ati Barack Obama to wa ni ipo kinni ati ipo keji.

Ronaldo, ẹni to n lewaju lori awọn ikanni ayelujara kaakiri lo tun kede sita wi pe oun tun ti fẹẹ darapọ mọ ikanni ayelujara miran, to si ni asiko ọhun ti to.

“Asiko ti mo n duro de tipẹ ti dopin bayii. Ikanni YouTube mi ti de sibi patapata. E tẹle mi nibẹ ki ẹ si darapọ mọ mi ninu irin ajo tuntun yii.”

Loju ẹsẹ ti awọn ololufẹ gbajugbaja agbabọọlu, ẹni ọdun mọkandinlogoji naa to ṣi n ta kebe lori papa ti kede eyi sita, ni wọn ti bẹrẹ sii tẹle e.

Laarin iṣẹju aadọrin, o jẹ iyalẹnu wi pe awọn to n tẹle Ronaldo ti le ni miliọnu kan, to si jẹ pe laarin wakati mẹrinlelogun, awọn ololufẹ rẹ ti le ni mili]onu mẹtadinlogun (17.6m).

Ko tii ṣeni to ni iru akọsilẹ bayii, leyi to fi jẹ pe Ronaldo ni ẹni akọkọ.