You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àkọròyìn mẹ́fà rí ẹ̀wọ̀n he; wo ẹ̀sùn tí aàrẹ fi kàn wọ́n
Akọroyin mẹfa lọ ti wa ni atimọle ni Orilẹ-ede South Sudan latari faran to Ṣafihan ibiti aarẹ South Sudan Salva Kiir ti tọ sara.
Oṣu kejila, ọdun 2022 ni aworan iṣẹlẹ naa lu gba oju opo awọn ẹrọ ayelujara nigbati aarẹ Salva naro lati ko orin orilẹ-ede South Sudan nibi ayẹyẹ ijọba kan.
Awọn oṣiṣẹ ile iṣe ijọba mẹfa ni wọn kò si gbaga awọn ọlọpa,eyiti ajọ to risi aabo fun awọn akọroyin ni south Sudan n pe fun itusilẹ wọn.
Patrick Oyet aarẹ awọn akọroyin ni South Sudan ni awọn akọroyin mẹfa naa ni wọn wa ni atimọle ọlọpa nitori wọn furasi wọn pe awọn lo fi aworan naa síta.
Atimọle yii ko ni yoo jẹ akọkọ nitori gbogbo akọroyin to baa ko iroyin ti ko dun mo aarẹ olori orilẹ-ede South Sudan ni wọn sun atimọle.
Aarẹ Salva kirr ni olori south sudan akọkọ lati gba ti o ti gba ominira.