A kò gbèrò láti wọ́gilé ìbò 2023– Ìjọba Nàìjíríà

A kò gbèrò láti wọ́gilé ìbò 2023– Ìjọba Nàìjíríà

 Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ti fi ọkàn àwọn ọmọ Nàìjíríà balẹ̀ pé wọn yóò dìbò ọdún 2023 lásìkò.

 Mínísítà ètò ìròyìn àti àṣà, Lai Mohammed ló fi ọ̀rọ̀ náà àwọn èèyàn lójú níbi ìjókó kan tó wáyé l'Abuja lórí àṣeyọrí ìjọba Muhammadu Buhari.

 Lai Mohammed sọ̀rọ̀ yìí lórí ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ní òṣìṣẹ́ àjọ elétò ìdìbò (INEC), Abdullahi Zuru, sọ pé ètò ààbò tó mẹ́he lé mú kí ìbò 2023 má wáyé.

Àjọ INEC ti kéde pé ní ọjọ́ kaàrùndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ni wọn yóò dìbò ààrẹ, tí wọn yóò sì dìbò gómìnà ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta

Ó ṣeéṣe kí ètò ìdìbò ọdún yìí má wáyé tàbí kí a sún síwájú -INEC

Alaga ajọ to n risi eto idibo ni Orilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, lọjọ Aje ni o ṣeeṣe ki eto idibo ọdun yii ma waye nitori ikọlu tí àwọn kan n ṣe si ọfiisi wọn ati bi eto aabo orilẹ-ede yii ko ṣe mu yanyan to.

Yakubu, ẹni ti Abdullahi Zuru ṣoju nibi ifọrọwerọ ti ajọ ọhun ṣe lori aabo eto idibo ọdun yii ni Abuja.

O ṣe akiyesi pe eto idibo to n bọ n koju ewu nla ti o si ṣeeṣe ki wọn fagile e ti ipo aabo ni gbogbo orilẹ-ede yii ko ba yipada.

Sibẹ, ọga INEC fi da gbogbo awọn ti ọrọ kan loju pe àwọn ko fi ohunkohun silẹ laiṣe lati rii daju pe aabo wa fun awọn oṣiṣẹ oludibo ati awọn ohun elo fun eto idibo ọdun yii.

O ni ajọ INEC mọ wi pe aabo pipe ṣe pataki fun eto idibo eyi ti o mu isọdọkan ati imugboro ba ijọba tiwantiwa nipasẹ ipese agbegbe ti o le mu ki idibo waye ni alaafia.

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fèsì pada fun alaga ajọ INEC

Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti fesi si ọrọ ti ọga ajọ INEC sọ wi pe eto idibo ọdun yii gbọdọ jẹ itẹwọgba lai si idaduro kankan.

Alukoro ẹgbẹ naa Debo Ologunagba ni tipẹtipẹ ni ẹgbẹ awọn ti n kilọ fun ajọ INEC lati ri wi pe eto ìdìbò ọdun yii lọ ní alaafia.

Debo ran aarẹ Muhammadu Buhari leti ko mu ileri rẹ ṣe lati mu ki aabo to daju wa lasiko idibo.

O ni lati ọdun 2019 si akoko yii o le ni aadọta ikọlu ti o ti waye si awọn ibudo INEC jakejado orilẹ-ede yii, o fẹsun kan ijọba pe wọn faye gba lati ri wi pe eto idibo ọdun yii ko waye nii.