Àwọn olóṣèlú tó ń fipá wá ipò agbára ló ń lùlù ìdàrú lẹ́gbẹ́ Ilana Omo Oodua - Akintoye

Alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ to ja fun ominira ilẹ Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti kigbe sita pe awọn oloṣelu ilẹ Yoruba kan ti fẹ da ẹgbẹ naa ru.

Ninu ọrọ to ba iwe iroyin Nigerian Tribune sọ, Ọjọgbọn Akintoye sọ pe ihuwasi awọn oloṣelu to jẹ ọmọ bibi ilẹ Yoruba, to n du ipo agbara kan tabi omiran bayii fihan pe, ọwọ wọn ko mọ si idarudapọ to n waye ninu ẹgbẹ ajijagbara naa.

O ni awọn oloṣelu naa di oju wọn si ohun to pe ni “ipinnu ijọba Buhari lati gbin irugbin ijẹgaba ẹya Fulani” eyi to ni o n waye lọwọ bayii.

O ni o ṣe ni laanu pe pẹlu gbogbo bi nnkan ṣe n lọ bayii, ohun to jẹ awọn oloṣelu naa, paapaa awọn ti ilẹ Yoruba, logun ni ọrọ idibo .

"Mo ti pada sipo alaga ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua lẹyin ti mo kọwe fipo silẹ"

O ni gbogbo awọn oloṣelu wọnyi ni lati mọ pe bi o ti wu ki wọn sa pamọ to fun ipe ominira ilẹ Yoruba, ohun ti araalu n fẹ ni.

Bo pẹ boya, ifẹ araalu ni yoo si pada ṣẹ.

Bakan naa lo ṣalaye pe oun ti pada si ipo gẹgẹ bi alaga apapọ ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, lẹyin to ti kọkọ kọwe fi ipo naa silẹ loṣu kejila ọdun 2022.

Ọjọgbọn Akintoye ni ipe ti awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati ọlọgbajọgba pe ohun lati pada sibẹ lo mu ki oun yi ọkan pada.

Ipe awọn ẹgbẹjẹgbẹ naa waye lẹyin ti Ọjọgbọn Adeniran ti Akintoye fa aṣẹ ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua le lọwọ, pada kede pe oun naa ti fipo ọhun silẹ lọjọ Satide.

Igbimọ adari ẹgbẹ naa lo wa kede lọjọ Satide pe awọn ko le gba ikọwefiposilẹ awọn mejeeji yii.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó tí gbowó, ló ń da ẹgbẹ́ rú, Akintoye sì ni olórí wa - Ilana Omo Oodua

Bi Ọjọgbọn Banji Akintoye ati Ọjọgbọn Wale Adeniran ti wọn jẹ awọn adari ẹgbẹ ajijagbara Ilana Omo Oodua (IOO), to n ja fun idasilẹ Yoruba Nation ṣe kọwe fipo silẹ ni aipẹ yii, ti n ba ọna miran yọ.

Idi ni pe igbesẹ awọn asaju mejeeji naa ko dun mọ ọpọlọpọ ninu, ti awọn agbagba ẹgbẹ ninu ẹgbẹ naa si ti kede pe awọn ko tẹwọ gba iwe ikọwefiposilẹ ọhun lọwọ,

Awọn agbaagba ẹgbẹ IOO se ikede naa, nigba ti wọn n bawọn akọroyin sọrọ lọjọ Satide ni olu ile ẹgbẹ Akọroyin nipinlẹ Oyo, to wa lagbegbe Iyaganku niluu Ibadan.

Bẹẹ ba gbagbe, Akintoye kọwe fipo silẹ lọsẹ kinni oṣu kejila, ọdun 2022, ti Adeniran si bọ si ipo naa.

"Banji Akintoye si ni olori awa ọmọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, a ko gba ikọwefiposilẹ rẹ"

Sugbọn Adeniran naa tun ti kọwe fipo silẹ ninu ọsẹ kinni oṣu kinni ọdun 2023 eyi to n ya ọpọ araalu atawọn ajijagbara naa lominu.

Agbẹnusọ fawọn agbagba ninu ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Oloye Femi Afolabi to ba awọn akọroyin sọrọ ni, awọn ko figba kankan gba iwe ikọwefiposilẹ lọwọ Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti awọn si n kede pe Akintoye si ni olori awọn.

“Ohun iyalẹnu lo jẹ fun wa nigba ti a gba iwe pe Ọjọgbọn Akintoye kọwe fipo silẹ lọjọ karun un oṣu kejila ọdun 2022.

"Awọn eeyan kan lo sanwo fawọn ọmọ ẹgbẹ kan lati da lasigbo silẹ ninu ẹgbẹ Ilana Omo Oodua"

“A wa n kede bayii pe a wa ko gba iwe naa rara, to si jẹ pe Ọjọgbọn Akintoye si ni olori wa.

“Bakan naa, awọn eeyan kan lo san owo fun awọn kan lati da gbogbo lasigbo naa silẹ ati lati ba orukọ rere ati isẹ takuntakun ti Akintoye ti ṣe jẹ, gbogbo idukoko wọn ni ko ni ẹsẹ nilẹ rara.

“A rọ Ọjọgbọn Akintoye lati maṣe kọbi ara si awọn iroyin ofege.

Gbogbo wa ni a pẹlu rẹ, ti a si dupẹ lọwọ rẹ ati awọn ti a jọ n ṣe isẹ takuntakun papọ fun ilọsiwaju ilẹ Yoruba.

Ṣé lóòtọ́ lọ̀rọ̀ owó ń dá wàhálà sílẹ̀ lẹ́gbẹ́ Ilana Omo Oodua tó ń jà fún òmìnira Yorùbá?

Nnkan ko rọgbọ mọ bayii laarin awọn agbaagba ati aṣiwaju ẹgbẹ Ilana Ọm Oodua to n lewaju fun ijijagbara ominira ilẹ Yoruba lọwọ yii; bakan naa ni omi alaafia ẹgbẹ naa n daru bi a ṣe n sọrọ yii.

Gẹgẹbi awọn iroyin to n jade lati ọdọ awọn eekan ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua lọwọ ṣe n sọ, aarin awọn agbaagba ẹgbẹ naa ko gun bayii nitori awuyewuye ẹsun ṣiṣe owo baṣubaṣu ti wọn n fi kan awọn adari ẹgbẹ naa lẹnu lọwọlọwọ yii.

Alaga apapọ meji kọwe fipo silẹ laarin oṣu mẹfa

Ṣaaju oṣu kejila ọdun 2022, Ọjọgbọn Banji Akintoye ni ọpọ mọ si alaga ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua lati ipilẹ ti ẹgbẹ naa ti bẹrẹ.

Nigba to di oṣu kejila ọdun 2022 ni Igbimọ ẹgbẹ naa tẹwọ gba iwe ikọ̀wefipo silẹ Ọjọgbọn Banji Akintoye kuro ni ipo adari ẹgbẹ ọhun.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ori ọjọ ori ni Ọjọgbọn Akintoye gbe eredi igbesẹ rẹ yii ka, awọn iroyin to n suyọ lati ẹgbẹ naa lẹnu lọwọlọwọ yii n fihan pe o dabi ẹni pe dukuu kan n waye laarin ẹgbẹ naa ni.

Ọjọgbọn Banji Akintoye fa iṣakoso ẹgbẹ naa le igbakeji rẹ Ọjọgbọn Wale Adeniran loṣu kejila ọdun 2022.

Amọṣa, fidio tuntun kan ti ẹgbẹ ilana ọmọ Oodua ṣẹṣẹ fi sita fihan pe Adeniran to jẹ alaga tuntun pẹlu tun ti fi ipo silẹ bayii o.

Gbogbo ẹni to ba fowo ranṣẹ si mi lorukọ Ilana Ọmọ Oodua, ki wọn mu iwe ẹri owo sisan rẹ jade - Ọjọgbọn Wale Adeniran

Ọjọgbọn Wale Adeniran ṣalaye ninu fidio naa pe igbesẹ oun lati yẹba kuro lori ipo naa pe idi ti oun fi gbe igbesẹ naa ko yẹ lẹyin awuyewuye owo ninu ẹgbẹ naa.

Ọjọgbọn Adeniran ni oun n yẹba naa lati fi aye silẹ fun iwadi awọn ẹsun ṣiṣe owo mọkumọku ti wọn n fi kan awọn adari ẹgbẹ naa.

Bakan naa lo tun ke sawọn agbaagba ilẹ Yoruba lati gbe igbimọ kan kalẹ fun iwadi awọn ẹsun yii lẹyẹ o ṣọka lati lee fi oju bi nnkan ṣe ri gan han fun awọn ọmọ Yoruba nile loko.

“Ni wakati yii mo yẹba naa, gẹgẹbi alaga ẹgbẹ ilana Ọmọ Oodua, gẹgẹbi ọmọ ẹgbẹ Ilana ọmọ Ooduwa, ati gẹgẹbi olukopa ninu ijijangbara fun ominira ilẹ Yoruba. Lati lee fi aye silẹ fun iwadi to kuna lori awọn ẹsun wọnyii.”

Ọjọgbọn Adeniran ni ki gbogbo awọn eeyan to ba fi owo ranṣẹ si oun tabi ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua o fi risiiti ẹri sisan owo naa ranṣẹ fun ayẹwo to peye.

Ẹsun ṣiṣe owo baṣubaṣu fẹ tu ẹgbẹ Ilana ọmọ oodua ka

Ọjọgbọn Adeniran fi idi rẹ mulẹ pe ọrọ owo ati ẹsun ikowojẹ lo n fa wahala laarin ẹgbẹ to n ja fun ominira ilẹ Yoruba yii.

Bi o tilẹ jẹ wi pe o ti pẹ diẹ ti awuyewuye ti n ja ranyinranyin kaakiri pe awọn kan laarin ẹgbẹ naa n fi apa janu pẹlu bi awọn adari ṣe n ṣe iṣuna ẹgbẹ ọhun.

Koda eyi ti fa iyapa awọn ẹka ẹgbẹ naa kan nilẹ Okere lawọn asiko kan sẹyin.

“Mo n fi asiko yii ke si ẹnikẹni to ba mọ pe oun fi owo ranṣẹ si mi, yala fun ara mi tabi fun ẹgbẹ Ilana tabi fun ijijangbara fun ominira ilẹ Yoruba yii ko jọwọ ko gbe ẹri iwe owo naa jade. Ki iwe ẹri owo sisan naa o fi han wa, elo ni iye owo ti ẹni naa fi ranṣẹ si mi, ọjọ wo dẹ ni.

Kii ṣe Ọjọgbọn Adeniran nikan lo ti mu ẹnu ba eyi lara awọn adari ẹgbẹ naa. Ọgbẹni Maxwell Adeleẹyẹ to jẹ agbẹnusọ fun ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua tẹlẹ pẹlu sọrọ nipa awuyewuye lori owo laarin ẹgbẹ naa.

Ninu atẹjade ti oun paapaa fi sita lọjọ Abamẹta, ọjọ keje oṣu kini ọdun 2023, Maxwell Adelẹyẹ ṣalaye pe oun ko fẹ ni ohunkohun n ṣe mọ pẹlu ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua labẹ awọn adari to n ṣakoso rẹ lọwọlọwọ bayii.

Maxwell Adelẹyẹ ni ki gbogbo awọn to fi owo ranṣẹ o lọ ree di awọn ti wọn fi owo ranṣẹ si mu ki wọn si yee darukọ oun ninu gbogbo wahala to n ṣuyọ lẹyin owo bẹẹ.

Bakan naa lo tka si Ọjọgbọn Banji Akintoye to jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ pe ko jawọ patapata kuro ninu ọrọ ẹgbẹ naa niwọn igba to ni oun ti kọ iwe fipo silẹ.

“Mo ke si Ọjọgbọn Banji Akintoye lati jawọ patapata kuro ninu ijijangbara fun ominira ilẹ Yoruba ki wọn lee tan ina wadi bi owo ṣe wọle lasiko rẹ gẹgẹ bi adari.”