You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Obasanjo ń jowú àṣeyọrí mí ní, fífì ontẹ lù Obi kó ní ṣiṣẹ́ - Tinubu
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Bola Tinubu ti sọko ọrọ sì aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo fun bi o ṣe fi ontẹ lu Peter Obi ti ẹgbẹ oselu Labour pe ohun lo koju oṣuwọn lati jẹ aarẹ Orilẹede Naijiria.
Tinubu sọ eleyi nigba to kopa níbi ìpolongo ibo to waye ni paapa fasiti Benin nipinlẹ Edo.
Gomina ana nipinlẹ Eko ni Obasanjo n jẹ owu awọn akojọ oun nitori afọju ko le lewaju fun awọn afọju.
O tẹsiwaju pe fífi ontẹ lu Peter Obi ko ni ṣe pẹlu aseyọri oun rara ninu eto ìdibo ọdun yìí.
Tinubu ni oun ranti pe aarẹ Olusegun Obasanjo ṣe fi iya jẹ oun ati ogunlọgọ awọn eeyan ipinlẹ Eko lẹyin to kuna lati gbe owo silẹ fun isejọba.
Tinubu ni iwa jẹgudu jẹra wọpọ ninu isejọba Aarẹ Olusegun Obasanjo ati Igbakeji Aarẹ tẹlẹ Atiku Abubakar.
"Njẹ Baba yẹn le pese adari fun Naijiria? Se ko dabi pe ki eeyan ran eeyan tìẹ nisẹ ole ni?
"Afọju to n lewaju fun awọn afọju. Erongba wọn ko ni sisẹ, wọn yoo jọ lulẹ ni.
"Ti n ba ni kí sọrọ lori Obasanjo ati Obi..... Ẹni tí ko mọ ọna ko le fi ọna ran yan ni ọrọ awọn mejeeji.