You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
A ti parí ìgbésẹ̀ láti gbé gbogbo àwọn ọlọ́pàá àgọ́ Ajah- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti ní gbogbo àwọn ọlọ́pàá tó wà ní àgọ́ ọlọ́pàá Ajah ni àwọn máa gbé kúrò ní àgọ́ náà lọ sí àwọn ibòmíràn.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin ló fi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí Twitter rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé ọjọ́ Kejì, oṣù Kìíní ọdún 2023.
Hundeyin ní kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Eko, Abiodun Alabi ti buwọ́lù ú pé kí gbogbo àwọn ọlọ́pàá tó wà ní àgọ́ ọlọ́pàá náà kó gbogbo ẹrù wọn kúrò níbẹ̀ tí wọn yóò sì fi àwọn mìíràn pààrọ̀ wọn.
Ìgbésẹ̀ yìí kò ṣẹ̀yìn ìpànìyàn tó ń wáyé ní lemọ́lemọ́ látọwọ́ àwọn ọlọ́pàá àgọ́ yìí.
Ní ọjọ́ ọdún kérésìmesì ni ọlọ́pàá tó wà ní àgọ́ Ajah, Drambi Vandi ṣekúpa agbẹjọ́rò kan Bolanle Raheem tó wà nínú oyún lásìkò tí Raheem àti àwọn ẹbí rẹ̀ ń bọ̀ láti ilé oúnjẹ kan.
Ṣaájú ìgbà náà ni ìròyìn gbòde pé ọlọ́pàá kan ní agbègbè ṣekúpa ọkùnrin kan Gafaru Buraimoh nígbà tí àṣìta ìbọn ọlọ́pàá bà á.
Èyí ló mú kí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìfẹ̀hónúhàn pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nílò láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá tó wà ní àgọ́ náà kí wọ́n yé fi ojoojúmọ́ pa àwọn ènìyàn.
Hundeyin wá ní ìgbésẹ̀ tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń gbé lórí àwọn ọlọ́pàá tó wà ní àgọ́ náà máa bẹ̀rẹ̀ ní àìpẹ́.
Bákan náà ló ní DPO àgọ́ ọlọ́pàá Ajah, Adolf Ogwu ti darí rẹ̀ wí pé gbogbo àwọn ilé ìtajà àti àwọn ìpàtẹ tó wà ní iwájú àgọ́ ọlọ́pàá náà ni kí wọ́n wò dànù.