Ọkùnrin tó fa nǹkan abẹ́ rẹ̀ yọ nínú bàálù, tọ̀ sí obìnrin kan lára, wọ gàù

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede India ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ arakunrin ti wọn fi ẹsun kan pe o ṣẹyọ si ori agbalagba ti wọn jọ wa ninu ọkọ baalu Air India ni Osu Kọkanla, ọdun 2022.

Iwe iroyin ilẹ India ni Shankar Mishra to tọ si ori ẹlọmiran, jẹ igbakeji adari ileeṣẹ banki ilẹ Amerika, Well Fargo , ki wọn to yọ ni ipo nitori iṣẹlẹ yii.

Mishra lo tọ si ori agbalagba obinrin ti wọn jọ wa ninu ọkọ baalu to n lọ lati New York si Delhi.

Nitori ọrọ yii, ileeṣẹ ọkọ Baalu Air India ti yọ oṣiṣẹ mẹrin to wa lẹnu iṣẹ lọjọ iṣẹlẹ naa kuro lẹnu iṣẹ.

Bakan naa ni wọn kede pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ọlọpaa fi panpẹ ọba mu Mishra

Saaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe awọn ko mọ ibi ti Mishra salọ lẹyin iṣẹlẹ naa, amọ awọn n ba mọlẹbi rẹ sọrọ.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, Mishra lo pa foonu rẹ lati ibẹrẹ oṣu yii, amọ kaadi igbowo rẹ to lo ni Bangalore, ni ọwọ fi tẹẹ.

Wọn si gbe pada si Delhi lati koju ẹsun ti wọn fi kan pẹlu iwadii lẹkunrẹrẹ.

Bakan naa ni awọn eniyan bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ ọkọ ofurufu Air India, lori ihuwasi rẹ lasiko iṣẹlẹ naa.

Wọn tilẹ ni ileeṣẹ naa ko fi iroyin ọhun sita laarin osu kan, ko to di pe iwe iroyin kan gbe isẹlẹ naa jade.

Ileeṣẹ to n risi eto irina nilẹ India wa ṣe apajuwe iwa aibikita ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa gẹgẹ bi eleyii ti ko bu iyi kun ileeṣẹ ofurufu.

Ki lo ṣẹlẹ ninu ọkọ baalu naa, ti ọkunrin fi tọ si obinrin lara?

Iroyin ni pe Mishra lo ti mu ọti yo, to si yọ nkan ọmọkunrin rẹ jade, to si tọ si ara obinrin agbalagba naa.

Iroyin naa lo tan jade nigba ti ileeṣẹ iroyin ni ilẹ India gbe lẹta aidunnu rẹ, ti obinrin naa kọ si adari ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa sita.

Ninu lẹta naa ni obinrin ọhun ni lẹyin ti arakunrin naa tọ si oun lara tan, ti oun si lọ paarọ aṣọ ninu ile igbọnṣẹ, ni oun tun duro fun ogun iṣeju nitori oun beere pe ki wọn fun oun ni aye miran.

Lẹyin naa ni oṣiṣẹ agba kan wa, to si ni ki oun pada si ori ijoko oun, bi o tilẹ jẹ pe wọn fi aṣọ si ori ijoko naa, amọ n ṣe ni agbegbe naa n run fun itọ.

Wakati meji lẹyin isẹlẹ naa, o ni wọn fun oun ni aaye lati joko sibi ti awọn oṣiṣẹ maa n joko si, ti oun si wa nibẹ fun wakati marun un.

Arabinrin naa salaye pe, nigba ti ọti ka loju ọkunrin naa, o bẹbẹ pẹlu omije loju, pe ki oun mase jẹ ki ọrọ naa jade,

Amọ obinrin naa ni oun ti fi ẹjọ naa lọ agbẹjọro oun, oun ko si fẹ ohunkohun ti yoo mu aifọkanbalẹ ba oun.