You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkùnrin mẹ́fà ri ẹ̀wọ̀n he ní Enugu látàrí fífi ìyà jẹ́ Opó
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kede pe ọwọ ti tẹ èèyàn mẹ́fà tí wọ́n ń kópa nínú ẹ̀sùn ìfìyàjẹni opó kan ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Iyaafin Anthonia Umeabelu Okonkwo to je iya ọlọmo merin ni wọn fiya jẹ ni ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwàá ni agbegbe Agunese Affam-Maku.
Wọn fi ẹsun kan opo kan pe o kọ igbin ninu igbo aiwọ ti wọn sọ pẹ o jẹ eewo.
Awọn ọdọ ìlu naa tun fi agbara mu u rin ni ihoho kaakiri agbegbe Agunese Affam-Maku gẹgẹ bi ijiya.
Iwadii awọn ọlọpaa fihan pe awọn ọkunrin mẹfa tun lu ọkọ obinrin naa ati aburo rẹ, ti wọn si farapa yannayanna nigba ti wọn gbiyanju lati gba obinrin naa lọwọ wọn.
Kini ọlọpaa sọ? Nigba ti Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu ṣe afihan awọn ti ọwọ tẹ, diẹ ninu wọn ni Okoro Stan, ẹni ọdun merindinlogoji; Jonathan Nwangene, ẹni ọdun metalelogoji; Maduabuchi Madueke, ẹni ọdun merinlelogbon. Awọn to ku ni Obioma Nwangene, ẹni ọdun mokandinlogoji; Anikene Samuel ọmọ ọdun mẹrinlelogun ati Chukwuebuka Agu, ẹni ọdun mejilelogbon.
Ndukwe to je alukoro fun Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu ṣalaye pe Komisonna ọlọpaa, Ahmed Ammani, ti paṣẹ fun Ẹka Iwadii Ọdaràn ti Ipinlẹ naa lati ṣe iwadii ni kikun lori iṣẹlẹ naa tiiti ọwọ yoo fi tẹ awọn ti o ni ọwọ ninu iwa ibajẹ naa.