Lóòótọ́ ni ológun gbìyànjú láti gbajọba lọ́wọ́ Tinubu lọ́dún 2025 - Ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba Naijiria ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn ọmọ ogun kan gbiyanju lati fi ipa gbajọba lowọ Aarẹ Bola Tinubu lọdun to kọja.
Ọrọ yii lo jẹyọ lẹyin iwadii abẹnu kan lẹyin kan ti wọn ṣe lẹyin ti wọn fi ṣikun ofin mu ọmọ ogun mẹrindinlogun.
Lẹyin ti ọwọ tẹ awọn ọmọ ogun naa ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2025 lori ẹsun aṣemaṣẹ kan ni iwadii ọhun waye.
Bo tilẹ jẹ pe iroyin gbode pe ologun gbiyanju iditẹgbajọba lasiko naa, ijọba Naijiria ni ko ri bẹẹ amọ o paarọ awọn ọgagun kan.
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ni awọn ti pari iwadii abẹnu wọn bayii., eyii to fi han pe pupọ ninu awọn ti ọwọ tẹ naa lo kopa ninu igbiyanju lati gbajọba mọ Tinubu lọwọ.
Atẹjade kan lati ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria fi lede sọ pe iwadii finifini lawọn ṣe lai yọ nnkankan sẹyin.
Atẹjade naa ni wọn ti fi esi iwadii ọhun ṣọwọ si awọn lọgalọga nileeṣẹ ọmọ ogun, awọn ti ọrọ naa ṣi mọ lori yoo si foju bale ẹjọ to wa fun awọn ologun.
Ileeṣẹ naa ko sọ ni pato iye awọn ti ọrọ iditẹgbajọba naa ṣi mọ lori ninu awọn mẹrindinlogun ti ọwọ tẹ, amọ o ni ko ni si ojuṣaju ninu igbẹjọ wọn.
Oniruru iditẹgbajọba lo ti waye ni Naijiria laarin ọdun 1966 si ọdun 1993.

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu
Bo tilẹ jẹ pe awọn oloṣelu lo n ṣejọba lati ọdun 1999, iditẹgbajọba jẹ ọrọ to lagbara ni Naijiria.
Lẹnu lọlọ yi ni oniruru iroyin n jade nipa iditẹgbajọ awọn ologun ni Naijiria amọ gbogbo igba ni ileeṣẹ ologun maa n sọ pe digbi loun wa lẹyin ijọba Bola Ahmed Tinubu.
Iroyin iditẹgbajọba Naijiria yii lo n waye lẹyin ti ologun bẹrẹ si n gbajọba lawọn orilẹede Afrika kan bii Mali, Burkina Faso, Niger ati Guinea.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn ọdọ kan n sọ lori ayelujara pe awọn n fẹ ki ologun gbajọba ni Naijiria ki nnkan le yipada amọ awọn agbalagba to ti ni iriri n sọ pe iditẹgbajọ kọ ni ọna abayọ si iṣọro Naiijiria.
Wayi o, ileeṣẹ ologun Naijiria ko darukọ awọn ologun mẹrindinlogun ti ọrọ naa kan.













