À ń ṣọ́ àwọn gómìnà ní Naijiria lórí bí wọ́n ṣe ń kó Náírà pamọ́ sí ilé – EFCC

Alaga ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, Abdulrasheed Bawa ti ni iye gomina ti awọn n ṣọ fun ẹsun ajẹbanu ti pọsi.

EFCC ni eyi ko ṣẹyin igbeṣẹ Banki apapọ Niajiria, CBN lati ṣe atunṣe Naira, ti wọn si kesi awọn eniyan lati ko owo to wa ni ọwọ wọn wa ki wọn fi gba owo tuntun ti wọn fẹ ṣe.

Ṣaaju ni ajọ EFCC ti kede pe oju awọn wa lara gomina mẹta ti wọn fi ẹsun kan pe o ko owo si ile, ti wọn ko le ko si banki.

Amọ wọn ko sọ iye gomina ti wọn n sọ lọwọ yii fun awọn owo ti wọn n ko sile.

‘’Gbogbo ẹyin gomina to ko owo pamo lati se idibo, a n wo yin’’

Ninu ọrọ rẹ, adari ajọ EFCC naa ni awọn ko ni sọ iye awọn gomina ti awọn n ṣọ awọn awọn n sọ gbogbo bi o ṣe n lọ ni Naijiria.

‘’Mi o mọ iye wọn tabi boya iha ariwa tabi guusu ni wọn, amọ a n sọ awọn gomina ni Niajiria.’’

Bakan naa lo fikun un pe iwadii awọn fihan pe awọn gomina kan ti ko owo pamọ ti wọn fẹ lo lasiko idibo.

Nitori naa igbesẹ ti CBN gbe ki wọn da owo pada si banki lati gba atunṣe yoo tu aṣiri awọn owo ti wọn lu ni ponpo yii.

Ajọ EFCC yii ni kikọ awọn owo pamọ lo fa ọpọlọpọ iṣoro to ba ọrọ aje to fi mọ iya ati iṣẹ to n ba awọn ọmọ Naijiria finra,

Amọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ naa ni aṣiri wọn ko bo mọ.