Tonto Dikeh fẹ̀sùn kan Baba Mohbad pé Ó ń gba ₦10k sí ₦15k kó tó ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀, Baba Mohbad ní irọ́ ńlá ni

Gbajugbaja oṣere tiata, Tonto Dikeh ti fẹhonu han síta lori ihuwasi Joseph Aloba, ẹni to jẹ Baba gbajugbaja olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba tí ọpọ mọ si Mohbad.

Tonto Dikeh, ninu lẹta kan to kọ si Baba Mohbad, eyi to gbe soju opo ayelujara Instagram rẹ, fẹsun kan pe Baba Mohbad n gba owo lọwọ awọn akọroyin ko to ṣe ifọrọwerọ.

Bakan naa lo fẹsun kan Baba oloogbe pe o n wa gbogbo ọna lati gbesẹ le gbogbo ọrọ ti ọmọ rẹ fi silẹ laye.

"Ohun to ba ni lọkan jẹ ní iwa yìí. Ọmọ rẹ, bawo ni awọn ọrọ aye ṣe bo ife to ni si ọmọ rẹ mọlẹ.

"O ṣeni laanu pe o jade sọrọ síta lẹyin ti iroyin jade pe wọn n da owo fun ọmọ-ọmọ rẹ ni akata iya rẹ to jẹ iyawo Mohbad.

"Ṣugbọn ni bayii, o n gba ẹgbẹrun mẹwaa, mẹdogun lati se ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin."

Tonto Dikeh ni nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa si ẹgbẹrun marundinlogun Naira ni Baba Mohbad n gba lọwọ awọn akọroyin ki o to gba ki wọn ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun un.

Bakan naa lo tun koro oju si bi Baba Mohbad ṣe n tọrọ owo lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun ayẹwo DNA fun ọmọ Mohbad dipo ki o kọju si iyawo ọmọ rẹ lati lọ ṣe ayẹwo naa.

Emi o gba owow lọwọ nikni lori ọrọ Mohbad - Baba Mohbad

Joseph Aloba, Baba Mohbad tí fọhun síta lori ẹsun tí gbajumo oṣere tiata obinrin, Tonto Dikeh fi kan pe o n gbowo lọwọ awọn akọroyin ko to ṣe ifọrọwerọ pẹlu wọn.

Ninu alaye to ṣe pẹlu Ileeṣẹ BBC News Yoruba, o ni ko si ohun to jọ bẹ rara, ti oun ko si ni ọrọ pupọ lati sọ.

"Mi o fẹ sọrọ sita pupọ, awọn akọroyin to n wa sọdọ mi, n ko bere owo lọwọ wọn.

"Ṣe bi ẹyin naa wa si ọdọ mi, ṣe mo bere owo lọwọ yin.

"Pupọ awọn akọroyin yii ni wọn fun mi lowo fun ara wọn nitori wọn ti jere lara pe wọn ba mi ṣe ifọrọwerọ."