Seriki Fulani, èèyàn méjì míì tó jẹ̀bi ẹ̀sùn ìjínígbé gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n gbéré

Ileẹjọ giga kan nipinlẹ Kwara ti dajọ ẹwọn gbere fun Seriki Fulani ipinlẹ Kwara Usman Adamu ati awọn mẹta mii lori ẹsun ijinigbe.

Usman Adamu, ọmọ iya yẹ lọkunrin ati eeyan kan torukọ rẹ n jẹ Gidado Idris ni wọn ran lẹwọn gbere lẹyin ti ẹri fi han pe wọn kopa ninu ijinigbe.

Wọn fẹsun kan awọn mẹtẹtaa naa pe wọn ji arakunrin kan Abubakar Ahmad gbe ti wọn si gba miliọnu kan Naira lowo ẹmi lọwọ rẹ ki wọn to tu silẹlẹyin to lo ogunjọ ni ahamọ wọn.

O sunmọ ọdun kan sẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara mu wọn ti ileẹjọ si ti wa da ẹjọ ẹbi le wọn lori lẹyin atotonu awọn agbẹjọro.

Ninu idajọ rẹ to gbe kalẹ lỌjọbọ, adajọ Adajọ Adenike Akinpelu sọ pe awọn mẹtẹẹtaa yi jẹwọ ẹṣẹ wọn.

O fi kun pe boya wọn wa nibi iṣẹlẹ ijinigbe naa tabi wn ko si nibẹ ko ṣe pataki bi kii ṣe pe wọn gbimọran pọ lati huwa ijinigbe yi.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ''awọn ọdaran yi mu ẹni to fẹsun kan wọn yi ti wọn si gba owo lọwọ rẹ pe ajinigbe nii ṣe''

''Mi o fi tara tara gba tio ọrọ agbẹjọro awọn ọdaran yi to ni ka wọgile ẹsun onigun meji ti wọn fi kan wọn tori pe o ni wọn o si nibi ti ijinigbe yi ti waye.''

Akinpẹlu tẹsiwaju pe ''o bani lọkan jẹ pe awọn to yẹ ko maa da aabo bo awọn to wa labẹ wọn lo n tori ifẹ owo ṣe idiwọ fun aabo to yẹ ki wọn pese.Tori naa a da wọn lẹbi taa si dajọ yi fun wọn bẹẹ''

Yatọ si idajọ ẹwọn gbere ti adajọ gbe kalẹ, o ni ki wọn san ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira fun ẹni ti wọn jigbe yi gẹgẹ bi owo gba ma binu.