Ìyàwó, ọmọ ọdún 15 fún ọkọ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní májèlé jẹ lálẹ́ ọjọ́ ìgbeyàwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọlọpaa ijọba ibilẹ Jahun, nipinlẹ Jigawa, ti fi ọwọ ofin mu iyawo kan ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹẹdogun(15) lọ.
Ẹsun ti wọn fi kan iyawo tuntun naa ni pe o gbiyanju lati pa ọkọ rẹ pẹlu awọn ọrẹ ọkunrin naa lalẹ ọjọ igbeyawo, nipa fifi majele si ounjẹ fun wọn.
Majele naa ni wọn lo pa ọkan lara awọn ọrẹ ọkọ iyawo, ẹni to n gbaradi lati ṣe isọmọlorukọ awọn ibeji ti iyawo tiẹ ṣẹṣẹ bi fun un.
Ninu ifọrọwerọ kan ti ọkọ iyawo, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ( 34) ti ori ko yọ lọwọ iku ṣe pẹlu BBC, o rawọ ẹbẹ sijọba lati jẹ ki idajọ ododo waye.
Ọkunrin naa ṣalaye pe oun ati iyawo to fẹẹ pa oun yii ti n fẹ ara awọn fun ọdun meji sẹyin, ko too di pe awọn ṣegbeyawo logunjọ, oṣu Kejila ọdun 2024.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?

Ninu aṣa awọn ara abule Albasu ti iṣẹle naa ti waye, tọkọ-tiyawo yoo jọ sun papọ lalẹ ọjọ igbeyawo wọn ni.
Ṣugbọn ọkọ iyawo yii ni oun ko fẹẹ ṣe bẹẹ lọjọ naa ni toun.
" Lẹyin ti wọn gbe iyawo mi de lalẹ ọjọ Aiku, ọrẹ mi to ṣalaisi yii ati awọn yooku sọ pe ki n lọọ sun ti iyawo mi, ṣugbọn mo sọ fun wọn pe mi o fẹẹ lọ lalẹ yẹn.
"Mo duro ti awọn ọrẹ mi ni ṣọọbu ọkan ninu wa to n ṣe telọ, ibẹ ni awọn ọrẹ iyawo ti gbe ounjẹ waa ba wa.
"Nnkan bii aago mẹwaa alẹ ni wọn gbe ounjẹ yẹn wa, macaroni ti wọn se pọ ni, pẹlu ẹran, a si bẹrẹ si i jẹ ẹ lọ.
"A pada fura pe ounjẹ naa ri bakan, a si dawọ duro, a ko jẹ ẹ mọ.
Nigba naa ni ọrẹ mi to ku yii bẹrẹ si i ke irora pe inu n run oun, inu bẹrẹ si i run emi naa. A mu miliiki lati pa oro rẹ ṣugbọn ko lọ. Lẹyin eyi ni wọn sare gbe wa lọ sileewosan Kiyawa, ṣugbọn ọrẹ mi ku ni tiẹ."
Ọkọ iyawo sọ pe o jọ oun loju pe iru nnkan bayii ṣẹlẹ, nitori oun ati ọmọde toun fẹ naa nifẹẹ ara awọn gidi ṣaaju igbeyawo.
" Igbeyawo to ni ifẹ ninu la ṣe, ṣugbọn kadara ati ai ni òye gẹgẹ bii ọmọdebinrin to jẹ lo fa eyi.
" O dun wa pe a padanu ẹmi eeyan lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn iyawo mi naa ṣi ni, nitori mo ti sanwo ori rẹ."
Bẹẹ ni ọkọ iyawo ṣalaye.
'Ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí mo bí ni wọ́n ti pa yìí''

Nigba to n sọrọ, baba ọrẹ ọkọ iyawo to di oloogbe naa sọ pe ọmọkunrin kan ṣoṣo ti oun bi ni wọn ti pa yii.
"Oun nikan ni ọmọkunrin ti mo ni, ẹni to gbọ ẹsin ye to si n pese ounjẹ fun mi ni. Wọn ti pa a bayii, o da ọmọ to ti bi silẹ tẹlẹ ati awọn ibeji le mi laya lati maa tọju.
Ẹ jọwọ, ẹ ran mi lọwọ ki idajọ ododo waye, nitori mi o tiẹ mọ nnkan ti mo le ṣe bayii''
Awọn ara abule ti iṣẹlẹ yii ti waye naa fidi ẹ mulẹ pe, iyawo ti wa lahaamọ ọlọpaa, ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Dutse, ipinlẹ Jigawa.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa, Lawan Shiisu, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn akọroyin.
Atẹjade ọlọpaa sọ pe:
" Ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan, gbimọ pọ pẹlu ọrẹkunrin rẹ tẹlẹ, lati fi majele si ounjẹ ọkọ rẹ l'Abule Albasu, nijọba ibilẹ Jahun.
"Ọkọ ati awọn ọrẹ rẹ meji ni wọn jọ jẹ ounjẹ naa, inu si bẹrẹ si i run wọn.
Wọn sare gbe wọn lọ sileewosan, nibi ti dokita ti sọ pe ọkan ninu wọn ti ku. Iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa."
Bẹẹ ni agbẹnusọ ọlọpaa Jigawa wi.
Kí ni òfin Naijiria sọ nípa ìgbeyàwó ọmọdé?

Ofin Naijiria lori igbeyawo ọmọde ko fi gbogbo ara ye ni yekeyeke.
Idi ni ni pe ilana ofin mẹrin ọtọọtọ leeyan le gba ṣe igbeyawo labẹ ofin Naijiria.
Awọn ilana naa ni: English law, Common Law, Customary Law ati Sharia Law.
Itumọ awọn ilana yii ni:Ilana ofin oyinbo, ofin ajọlo, ofin ibilẹ ati ofin Sharia.
Gbogbo awọn ilana yii ni ofin Naijiria ti lẹyin, wọn si jẹ ofin to so gbogbo eeyan pọ labẹ ofin.
Awọn Musulumi kan n tẹle ilana Anọbi Mohammed to fẹ Aisha nigba to wa lọmọ ọdun mẹfa, to si sọ ọ di iyawo lọọdẹ rẹ lọmọ ọdun mẹsan-an.
Ṣugbọn ninu ofin Naijiria, ko lọ geere rara.
Ofin Federal Child Rights Act (CRA) ti ọdun 2003, sọ pe eewọ ni lati fẹ ẹni ti ọjọ ori rẹ ko ba ti i pe mejidinlogun, (18).
Bo si tilẹ jẹ pe ọkan lara awọn orilẹ-ede to fọwọ si ofin yii lọdọ ajọ Iṣokan Agbaye (UN) ni Naijiria wa, ile igbimọ aṣofin gbọdọ fọwọ si i, awọn ile igbimọ to wa lawọn ipinlẹ mẹrindinlogoji lorilẹ ede yii naa gbọdọ buwọ lu u ko too le di ofin.
Ko si ki i n ṣe gbogbo wọn ni wọn ti fọwọ si ofin naa.














