Àwọn ẹ̀sùn ńláńlá tí wọ́n ti fi kan Tinubu, Atiku àti Peter Obi tó ń díje dupò ààrẹ ní Naijiria

Saaju idibo sipo aarẹ to n bo lorilẹede Naijiria, ọpọlọpọ awuyewuye lo ti ṣuyo lori awọn ẹsun magomago ati iṣe ti wọn fi kan awọn oludije sipo aarẹ naa.

Awọn oludije mẹta gboogi ti wọn n fi ẹsun kan loore-koore ni oludije lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, Oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ati oludije lẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi.

Lara ẹsun ti wọn fi kan wọn ni lilu owo ilu ni ponpo, gbogbe oogun oloro ati ṣiṣe alaisan owo ori.

Amọ titi di asiko yii awọn oludije mẹtẹẹta naa ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Tinubu...

Bola Ahmed Tinubu to jẹ ọkan gboogi lara awọn oludije sipo aarẹ lorilẹede Naijiria ni awọn eniyan sọrọ nipa rẹ julọ, paapaa lori awọn ẹsun ti wọn fi n kan.

Bola Tinubu lo ti di ipo gomina mu ni ipinlẹ Eko fun saa meji, ti awọn eniyan si ri gẹgẹ bi Baba isalẹ fun ọpọ awọn oloṣelu.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ko si ẹni to mọ ọjọ ori rẹ, bi eto ilera rẹ ṣe ri, iru iṣẹ to n ṣe ati otitọ lori iroyin pe boya o lọ si fasiti abi bẹẹkọ.

Ọpọlọpọ awọn alatako rẹ gbagbọ pe ilera rẹ ko pe lati dari orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni wọn ti fi ẹsun kan an pe oun lo wa nidi magomago lasiko idibo ni Naijiria lẹyin ti wọn ri Bullion Van to gbe ọwọ lọ si ile rẹ ni ilu Eko.

Idi owo rẹ naa pẹlu ohun ti awọn eniyan n sọrọ nipa rẹ, ti wọn si fẹsun kan an pe oun gbe oogun oloro.

Ni Oṣu Kejila, ọdun 2023 nigba ti o ba BBC sọrọ, o ni iṣe ile kikọ ati rira ti oun jogun ba, ti oun si dokowo pẹlu rẹ ni idi ọla rẹ.

Bakan naa ni Tinubu ni o kere tan milionu kan o le (1.8 million dollars) ni oun gba gẹgẹ bi owo osu ati ajẹmọnu nigba ti oun ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Deloitte ati Touch gẹgẹ bi auditor ni ilẹ Amerika.

Wọn tun fi ẹsun kan an pe o n gba owo ori awọn eniyan nipinlẹ Eko nipa ileeṣẹ Alpha Beta amọ Tinubu ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

Ọpọlọpọ igba ni Tinubu ti ni ko si otitọ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan oun, ati wi pe ọna to mọ ni oun gba ri ọla oun.

Peter Obi ati ẹsun Pandora

Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi naa lo ti jẹ gomina ipinlẹ Anambra ni eemeji.

Gbogbo igba tii ni awọn eniyan si ma n beere idi owo rẹ to ni o niiṣe pẹlu awọn banki ti wọn darapọ mọ ara wọn ati kiko awọn ohun elo wọ orilẹede Naijiria.

Bio tilẹ jẹpe awọn ololufẹ rẹ ri gẹgẹ ẹni ti ko labawọn, ohun iyalẹnu lo jẹ nipa ti wọn fi ẹsun magomago kan an.

Lasiko ti wọn n ṣe iwadii ti wọn pe ni Pandora ni wọn ṣewadii ọla ikọkọ ti Peter Obi ni ati bi kii ṣe san owo ori.

Iwadii Pandora naa ṣafihan pe ni ọdun 2010 nigba ti Peter Obi wa ni ipo gomina, ko kede awọn ohun ini rẹ to fi mọ ọla to ni si ikọkọ.

Bakan naa ni iwadii fihan pe Obi ni ọpọlọpọ apo iṣuna ni Banki lorisirisi lasiko to si n ṣiṣẹ fun eniyan.

Wọn tun fi ẹsun kan an pe o kọ lati fi iṣẹ silẹ ni ile iṣẹ to da silẹ ni UK lasiko to di ipo gomina mu ni ipinlẹ Anambra.

Amọ Peter Obi ni oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun, ati wipe oun fi iṣẹ naa silẹ fun iyawo oun amọ wọn ko tẹtẹ file rẹ fun oṣu mẹrinla.

Atiku Abubakar ati ẹsun loriṣiriṣi...

Ọpọlọpọ igba ni wọn ti fi ẹ̀sun iwa ajẹbanu kan oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria.

Abubakar ni ọpọ ri gẹgẹ bi onimọ nipa eto oṣelu nitori o ti di ipo igbakeji aarẹ mu ni Naijiria laarin ọdun 1999 si 2007.

Ni gbogbo asiko yii naa ni wọn fi ẹsun magomago kan, ti Oluṣẹgun Ọbasanjo to di ipo aarẹ mu nigba naa si fi ẹsun lilu owo ilu ni ponpo.

Owo naa to to $145 million to tọ si owo iranwo fun ajọ to n ṣeranwọ fun idagbasoke eto epo rọọbi, Peteroleun Technology Development, PTDF.

Bakan naa laipẹ yii ni arakunrin Michael Achimugu jade wa fi ẹsun kan Atiku pe o lu owo ni ponpo nigba to wa ni ipo ni ọdun 2007 si ọdun 2010.

Arakunrin naa ni Atiku fi ipo rẹ lati lu owo ilu ni ponpo lori awọn ọkọ “Special Purpose Vehicles” (SPVs).

Wọn ni Atiku lo eyi lati fi da ileeṣẹ silẹ nibi ti wọn ti ko owo ilu jẹ, ti wọn si fun ẹnikẹni ni ohun kohun ni gba naa lọhun

A n gbe Atiku lọ si ileẹjọ ti EFCC ko ba ṣewadii ẹsun magomago ti wọn fi kan an – Festus Keyamo.

Lẹyin ẹsun tuntun ti wọn fi kan Tinubu yii ni agbẹjọrọ to tun jẹ Minisita ni Naijiria, Festus Keyamo ti ni oun yoo gbe Atiku lọ si ileẹjọ̀ to fi mọ EFCC.

Keyamo ninu lẹta to kọ si EFCC ni ẹni to tu aṣiri Atiku naa ni ẹri to daju, eleyii ti wọn gbọdọ lo lati fi ṣe iwadii oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP naa.

Bakan naa lo fikun un pe oun fun wọn ni wakati mejilelaadọrin lati gbe igbeṣẹ ni kiakia lori ẹsun ti wọn fi kan Atiku ọhun.

Lara awọn ẹsun ti Festus Keyamo fi kan an ni pe o lu owo ilu ni ponpo ati o doju ofin Naijiria ru nipa titapa si ofin to de ihuwasi awọn oṣiṣẹ ijọba paapaa awọn ti wọn ba yan si ipo.