Ìjọba àpapọ̀ gbé Gómìnà 36 re ilé ẹjọ́ lórí òmìnira ijọba ìbílẹ̀, bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ rèé

Ileẹjọ to ga julo lorilẹede Naijiria ti paṣẹ fun awọn gomina mẹrindinlogoji lati wa wi tẹnu wọn lori ẹjọ ti ijọba apapọ pe wọn lori ominira ijọba ibilẹ.

Ijọba apapọ n beere fun ominira fun ijọba ibilẹ 774 lorilẹede Naijiria.

Adajọ Garba Lawal to lewaju igbimọ ẹlẹni meje lo gbe idajọ naa kalẹ lonii Ọjọbọ ọgbọnjọ oṣu Karun-un ọdun 2024 yii.

Adajọ Lawal ni igbẹjọ yii ati gbogbo igbesẹ ni gbigbe ni o gbọdọ pari laarin ọjọ meje, to si sun igbẹjọ si ọjọ kẹtala oṣu kẹfa ọdun 2024.

Adajọ tun palaṣẹ pe ki wọn fẹsun mii kan awọn ipinlẹ mẹjọ ti wọn kọ lati foju han ni ile ẹjọ lỌjọbọ.

Awọn ipinlẹ ti wọn ko foju han ni ilẹ ẹjọ ni ipinlẹ Borno, Kano, Kogi, Niger, Ogun, Osun, Oyo ati Sokoto.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju laarin ijọba apapọ ati awọn Gomina?

Ijọba apapọ labẹ aṣẹ Minisita fun eto idajọ, Lateef Fagbemi n pe fun ominira awọn ijọba ibilẹ kaakiri orilẹede Naijiria.

Ninu iwe ẹjọ naa, ijọba apapọ sọ fun ile ẹjọ pe ki wọn fofin de awọn Gomina lati ma tọju bọ ohun kankan to ni ṣe pẹlu ijọba ibilẹ mọ.

Bakan naa ni ijọba apapọ tun pe fun pe owo ti ijọba ya sọtọ fun ijọba ibilẹ maa lọ si apo wọn taara ni ilana ti ofin gbe kalẹ yatọ si ohun ti awọn gomina n ṣe, ti wọn lọ pese apo owo fun awọn ijọba ibilẹ.

Ti gbogbo erongba ijọba apapọ ba wa si imusẹ, awọn goimina ko ni anfani lati maa tọwọ bọ owo ijọba ibilẹ mọ.

Ijọba apapọ ni gbogbo gomina ipinlẹ pata lo bura lati tẹle ilana ti òfin gbe kalẹ ninu iṣejọba.

O tẹsiwaju pe iwe ofin orilẹede Naijiria ni ẹka ijọba mẹta, ti wọn si jẹ ijọba apapọ, ijọba ibilẹ ati ijọba ibilẹ, ti awọn mẹtẹẹta si n pawo wọle sinu apo ilu ti wọn ti pese silẹ.