Sunday Igboho, yé máa sọ pé ẹ̀yàn kan ló wà nìdi ìwà ọ̀daràn ní Nàìjíríà – Ẹgbẹ́ YWG kìlọ̀

Ẹgbẹ Yoruba Welfare Group (YWG) ti kilọ fun gbajugbaja ajijagbara fun idasilẹ orilẹ ede Yoruba, Oloye Sunday Igboho pe ko ye di ẹbi iwa ọdaran lawujọ ru ẹya kan ni Naijiria.

Lati igba ti Igboho ti pada si Naijiria lati wa ṣe oku iya rẹ ni o tun ti n sọrọ tako awọn darandaran, eléyìí to ni awọn lo n pa eeyan kiri lori oko nilẹ Yoruba.

Igboho tun sọ pe asiko ti to bayii lati le gbogbo awọn darandaran to n huwa ọdaran kuro nilẹ Yoruba.

Amọ, ẹgbẹ YWG sọ ninu atẹjade kan ti o fi sita pe "kii ṣe ẹyà kan ṣoṣo lo wa nidi ijinigbe, iṣekupani, jibiti ori ayelujara at'awọn iwa ọdaran mii lawujọ."

Aarẹ ẹgbẹ YWG, Kọmureedi Abdulhakeem Adegoke Alawuje kepe Igboho lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria mii lati doju ija kọ awọn ajinigbe, janduku agbebọn at'awọn odaran mii nilẹ Yoruba.

"Ọpọ ipenija lo n koju Aarẹ Bola Tinubu lasiko yii, Igboho ko tun gbọdọ dakun awọn ìṣòro yii.

Tinubu ti n gbiyanju agbara rẹ lati yanju iṣoro Naijiria, ko si nilo gbogbo ọrọ ti Igboho n sọ lati ṣe eyi.

Adura lati ṣe aṣeyọri ni Tinubu nilo bayii, kii ṣe awuyewuye ẹlẹyamẹya to le ṣe idiwọ fun un.

Ti a ba da ija ẹlẹyamẹya silẹ bayii, a n dakun iṣoro to wa nilẹ ni.

Ẹ jẹ ki a ranti awọn ọdaran kan ti wọn n wa anfaani lati da ilu ru.

Mo fẹran Igboho, amọ, mi o faramọ ọna ti o fi n jijagbara.

Ti o ba jẹ pe ohun ti Igboho n wa ni alaafia, iṣọkan ati ìfẹ ni Naijiria, ẹgbẹ YWG wa pẹlu rẹ.

O yẹ kí Igboho mọ pe kii ṣe oun nikan lo fẹran iran Yoruba.

Bi a ṣe le wa ojutuu si iṣoro Naijiria ni nipa wiwa alaafia, ifẹ at iṣọkan laarin gbogbo eeyan.

Lati le ṣe eleyii, a gbọdọ yago fun didi ẹbi iwa ọdaran ru ẹya tabi ede kan lawujọ.

Ni ọpọ igba awọn to jẹ kanda ninu ẹyà kan lo maa n huwa ọdaran, eleyii ti ko tumọ si pe bi gbogbo wọn ṣe ri niyẹn.

Gbogbo ẹya ati ede lo nilo ara wọn ni Naijiria.

Ẹ jẹ ki gbogbo wa jọ fọwọ so ọwọ pọ sọ orilẹ ede wa di nla lai da rogbodiyan silẹ.

Ọta gbogbo wa ni awọn ajinigbe, janduku agbebọn at'awọn ti wọn n fi eeyan ṣoogun owo jẹ," Kọmureedi Alawuje ṣalaye.