You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná já iná ilé aṣòfin lẹ́yìn tó jẹ gbèsè ₦2.8bn owó iná
Ileeṣẹ mọnamọna ECG ti ja ina ile igbimọ aṣofin orilẹede Ghana lori gbese N2.8bn owo ina ti wọn jẹ.
Lasiko ti ile n jiroro lọwọ lori ọrọ apilẹkọ ti aarẹ Nana Addo Akufo-Addo bawọn eeyan orilẹede naa sọ lori ibi nkan de duro ni ileeṣẹ ECG ja ina ọhun.
Fidio kan lori ayelujara ṣafihan awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ti n wọn n sọ pe ‘’Dumsor, dumsor’’ ni ede Gbana eyi to tumọ si pe ile tilọ.
Iroyin kan ni Ghana fidi rẹ mulẹ pe ẹrọ amunawa jẹnẹretọ nile aṣofin pada lo lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ wọn.
Amọ, ọpọ ọfiisi ni ko ni ina ti ilẹ ọjọ naa fi su.
Ileeṣẹ tẹlifisan Ghana TV3 sọ pe awọn aṣofin atawọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin to wa ninu lifuti wa loju kan naa fun igba pipẹ nigba ti ileeṣẹ mọnamọna ja ina lojiji.
Ọgagba ileeṣẹ ina mọnamọna ECG, William Boateng sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe awọn gbe igbesẹ lati ja ina ile igbimọ ọhun lẹyin ti wọn kọ eti ikun si ikilọ ileeṣẹ naa wi pe ki wọn san owo ti wọn jẹ.
Ọgbẹni Boateng ṣalaye pe awọn so ina ile igbimọ aṣofin naa pada lọjọ kan lẹyin ti wọn san miliọnu mẹtala owo Cedi ninu gbese ti wọn jẹ nigba ti wọn ṣeleri lati san iyoku laarin ọsẹ.
Amọ, aṣoju ile igbimọ aṣofin, Ebenezer Ahumah Djietror, sọ pe ile aṣofin ko jẹ owo ti ileeṣẹ mọnamọna ECG sọ pe o n jẹ.
Ọgbẹni Djietror ni N1.5bn ni ile n jẹ ileeṣẹ mọnamọna ọhun tori awọn ti san ninu rẹ.
Ileeṣẹ ina mọnamọna ti gunle jija ina awọn onibara wọn to n jẹ owo naa laipẹ yii ni Gbana.
Ẹwẹ, awọn aṣofin lati inu ẹgbẹ alatako ti rọ ijọba lati dokoowo sii ni ẹka ileeṣẹ amunawa ki iṣoro ina ọba to n koju orilẹede Ghana le di ohun igbagbe.