You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aráàlú dáná sun àwọn arìnrìnàjò nípìnlẹ̀ Edo, èèyàn méje kú
Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Monday Okpebholo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fojú àwọn afurasí tó ṣe ìkọlù sáwọn arìnrìnàjò kan ní ìpínlẹ̀ náà, tí wọ́n sì ṣekúpa èèyàn méje lọ́jọ́bọ̀.
Àwọn èèyàn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn náà ló ń ṣe ìrìnàjò gba ìlú Uromi ní ìpínlẹ̀ Edo, káwọn aráàlú náà tó dáwọn, tí wọ́n sì ní àwọn fura sí wọn pé ajínigbé ni wọ́n.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí gómìnà náà fi sórí ìkànnì Facebook rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn aráàlú náà ṣe dáná sun àwọn èèyàn ọ̀hún, tó sì ní àwọn kò ní fi ààyè gba ìwà bẹ́ẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo.
Ó ṣèlérí pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ni yóò fojú winá òfin.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, wọ́n ní àwọn èèyàn tí wọ́n pa ọ̀hún ń rin ìrìnàjò lọ ní òpópónà Uromi sí Obajana nígbà táwọn fijilanté ìlú Uromi dá wọn dúró láti ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀ wọn.
Ìròyìn ní, àwọn èèyàn náà sọ fún àwọn fijilanté náà pé ọlọ́dẹ ni àwọn àti pé àwọn ń ṣọdẹ lọ lásìkò tí wọ́n dá wọn dúró ni.
Àlàyé yìí kò tẹ́ àwọn fijilanté náà lọ́rùn, tí wọ́n si gbàgbọ́ pé afurasí ajínigbé ni àwọn èèyàn náà àti pé àwọn fura sí wọn pé Fulani darandaran ni wọ́n.
Àjọ Amnesty International gbàgbọ́ pé àwọn èèyàn tó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ju èèyàn méje, tí wọ́n sì ń fẹ́ káwọn aláṣẹ ṣe ìwádìí tó gbòòrò lórí ṣíṣe ìkọlù sáwọn arìnrìnàjò mẹ́rìndínlógún.
Adarí Amnesty International ní Nàìjíríà, Isa Sanusi sọ pé níṣe ni àwọn fijilanté àtàwọn ọ̀dọ́ lu àwọn èèyàn náà, tí wọ́n sì tún dáná sún wọn.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, àwọn arìnrìnàjò náà ni a gbọ́ pé wọ́n ń rin ìrìnàjò láti Port Harcourt lọ sí Kano láti lọ ṣọdún ìtunu àwẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn.
Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Uromi ní ìpínlẹ̀ Edo ni wọ́n dáwọn dúró, tí wọ́n sì kọlù wọn fẹ́sùn wí pé, ajínigbé ni wọ́n.
Lára àwọn fídíò tó gba orí ayélujára ṣàfihàn báwọn aráàlú Uromi ṣe ń kígbe ajínigbé lé àwọn èèyàn náà lórí, tí wọ́n sì ń lù wọ́n.
Fídíò mìíràn tún ṣàfihàn àwọn èèyàn mìíràn tí wọ́n wà nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀, tó sì jọ wí pé ẹ̀mí ti bọ́ lọ́rùn wọn bí wọ́n ṣe wà nílẹ̀ níhòhò.
Òmíràn tún ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń na èèyàn kan lára wọn, tí wọ́n sì ń pariwo pé kí ó kú.
Àwọn fídíò tún ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń fi táyà ọkọ̀ sí wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì ń dáná sún wọn láàyè.
Bákan náà ni àwọn fídíò mìíràn ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń tú ọkọ̀ táwọn èèyàn náà ń ṣe ìrìnàjò nínú rẹ̀, tí wọ́n sì sọ pé àwọn bá àwọn ìbọn nínú rẹ̀.
Afurasí mẹ́rìnlá ni a ti nawọ́ gán - ọlọ́pàá
Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà, Kayode Egbetokun náà tib u ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà tó sì ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti fojú àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà winá òfin.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Nàìjíríà, Olumuyiwa Adejobi fi léde lọ́jọ́ Ẹtì ní ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá tin í kí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lọrí ìkọlù náà.
Ó ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò ní fi ààyè gba pípa èèyàn lọ́nà àìtọ́ tí àwọn yóò sì ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn tẹ̀lé ìlànà tí òfin là kalẹ̀.
Ọ̀gá ọlọ́pàá nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí mẹ́rìnlá tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n lọ́wọ́ nínú pípa àwọn èèyàn náà àti pé ìwádìí ṣì ń lọ láti nawọ́ gán àwón yòókù.
Bákan náà ló rọ àwọn aráàlú láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn ọlọ́pàá kí ìwádìí náà le lọ bó ṣe yẹ, tó sì ṣèkìlọ̀ fáwọn èèyàn láti dènà ṣíṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn nígbà tí wọ́n bá kẹ́fín ìwà ọ́daràn ní agbègbè wọn.
Ó fi kun pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá korò ojú sí níní àwọn nǹkan ìjà lọ́wọ́ pé ó lòdì sí òfin láti máa gbé ìbọn àtàwọn nǹkan ìjà mìíràn lọ́nà àìtọ́.
Tinubu, Atiku, Kwankwaso bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà
Ààrẹ Bola Tinubu ti wá bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà, tó sì bá àwọn ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà kẹ́dùn.
Tinubu ní òun yóò ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo àwọn afurasí ọ̀daràn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà ni kò mú jẹ gbé.
Ààrẹ ní òun kò ní ààyè gba pípa èèyàn lọ́wọ́ ara ẹni àti pé gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà ni wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti rìn sí ibi tó bá wù wọ́n ní orílẹ̀ èdè yìí.
Bákan náà ni igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Atiku Abubakar rọ àwọn aláṣẹ láti tètè jí gìrì sí ojúṣe wọn lójúnà àti dènà irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kano, Rabiu Kwankwaso náà ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ èyí tó bani lọ́kàn jẹ́ àti pé ó yẹ káwọn ọmọ Nàìjíríà le máa rìn sín ibi tó bá wù wọ́n láì kojú ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà.
Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Isa Pantami náà pè fún ìjìyà tó tọ́ fáwọn tó hu ìwà ibi náà, tó sì ní kò yẹ kí ikú àwọn èèyàn náà lọ gbé.