'Mo rò pé ohun gbogbo ti tán fún mi ni'

Hanan n kọ nnkan si ojuu patako
Àkọlé àwòrán, Hanan ree, obinrin to sa kuro nile rẹ ni Darfur lọ si Chad nitori ogun to n lọ lọwọ.

Nigba ti obinrin kan, Hanan, ẹni ogoji ọdun, sa kuro nile rẹ lagbegbe Guusu Darfur nitori ogun, ko mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si iṣẹ olukọ to yan laayo.

Ṣugbọn ko si ọgbọn mi-in to le da ju ko sa asala fun ẹmi rẹ nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ alatako 'Rapid Support Forces '(RSF) gba ilu mọ wọn lọwọ ninu ija ti ẹlẹyamẹya da silẹ.

“Awọn ẹya Arab ati awọn RSF kan da oju ogun kọ wa laduugbo wa, wọn si dana sun ọpọlọpọ nnkan laarin igboro. Wọn tun bu majele sinu awọn orisun omi wa, ko si sohun ti a le ṣe. Ko si ọna fun wa lati lọọ wa omi tabi ounjẹ. A lo to oṣu meji ninu ijiya naa'' Bẹẹ ni Hanan ṣalaye fun BBC.

Pẹlu eyi, awọn ọmọ ogun RSF ko yee sọ pe irọ ni wọn n pa mọ awọn ni Darfur.

Ki i ṣe Hanan nikan lo sa lọ si Chad, bo ti debẹ lo ba awọn ọmọ Sudan ti iye wọn ju idaji miliọnu lọ. Awọn wọnyi naa sa kuro nitori ogun Sudan ti ọgagun Abdel Fattah al-Burhan n dari, ati tawọn RSF ti ọgagun Mohamed Hamdan Dagalo n lewaju rẹ.

O ti le ni ẹgbẹrun mẹwaa eeyan ti wọn ti pa ninu ogun, o si to miliọnu mẹwaa eeyan ti wọn ti di alarinkiri, ti wọn ko rile gbe mọ.

Idaamu to sọ ọpọ eeyan di alairilegbe mọ yii ni wọn lo pọju ti ibikibi lọ lagbaaye bayii, koda, o pọ ju ti Ukraine ati Syria lọ.

Ni ti Hanan, ibi kan ti wọn n pe Adré, ni wọn kọkọ de si, eyi si jẹ ọkan ninu awọn ile alaini to ti pẹ gan-an. Ṣugbọn ero tun ti pọju nibẹ, bẹẹ ni wọn n pọ si i, eyi lo mu Hanan ati awọn ẹbi rẹ kọri si ibo mi-in ti wọn n pe Metche.

Aworan awọn akẹkọọ ti wọn jokoo sori ẹni ninu yara ikawe
Àkọlé àwòrán, Aworan awọn akẹkọọ nileewe alakọọbẹrẹ tuntun ti wọn da silẹ nibudo alairilegbe to wa ni Metche.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi eeyan yoo ba lọ si Metche pẹlu mọto lasiko ẹẹrun, irin ajo wakati meji ni. Loju ọna eleruku to kun fun yẹpẹ, bẹẹ ni awọn apata pọ niluu aṣálẹ̀ ọhun. To ba waa di asiko ojo, irin naa yoo pẹ ju bẹẹ lọ, nitori gbogbo ilẹ yoo maa yọ bọrọ ni.

Awọn ahere ti wọn kọ leeyan yoo maa ri, ibẹ ni ibugbe idile to to ẹgbẹrun lọna ogoji. Bo ti ri yii naa, wọn ṣe ileewosan sibẹ, wọn kọ ọja ati ile iwe alakọọbẹrẹ tuntun.

Oṣu keji ọdun 2024 yii ni ajọ kan da ileewe naa silẹ fun wọn, yara ikawe ogun lo wa nibẹ, awọn akẹkọọ to din diẹ lẹgbẹrun meji si n gba ẹkọ nibẹ. Bẹẹ ni awọn olukọ bii Hanan naa si ti n riṣẹ ṣe.

Ọrọ ọmọde ko ṣoro ni tiwọn, wọn ti n kọrin pẹlu ariwo nileewe naa, ohun ti wọn fi ki ikọ BBC to ṣabẹwo sibẹ kaabọ niyẹn, bo tilẹ jẹ pe orule ileewe wọn ko to nnkan, to si jẹ paali tapoli ni wọn fi bo ara ogiri.

Awọn ọmọde tọjọ ori wọn ko jọra wọn jokoo silẹẹ lọ, ẹni ni wọn tẹ dipo aga ati tabili tawọn akẹkọọ maa n lo. Ṣugbọn eyi ko din ayọ wọn ku, wọn turaka daadaa.

Nibi ni ikọ iroyin yii ti pade Hanan, to n kọ iṣẹ si ojuu patako. Oun naa ṣalaye pe oun gbagbọ pe awọn ọmọde naa yoo gbagbe nipa ogun, wọn yoo si le lafojusun ọjọ iwaju rere ti ifẹ yoo wa.

“ Mo nigbagbọ pe wọn le pari ipele ẹkọ yooku, ki wọn gba iwe-ẹri ni yunifasiti, ki wọn le dari orilẹ-ede wa nigba ti wọn ba pada dele.'' Hanan lo sọ bẹẹ.

Aworan Ahmed lati Sudan
Àkọlé àwòrán, Ahmed ree, ọkan lara awọn akẹkọọ lati Sudan ti ogun ti ṣakoba fun ẹkọ rẹ.

Ahmed, ọmọ ọdun mejila, jokoo niwaju laarin awọn akẹkọọ yooku, o n ba wọn kawe.

Ogun lo le awọn obi re naa kuro nigba ti awọn RSF ati Araabu kọlu wọn nile wọn to wa ni El Geneina, bi wọn ṣe di ẹni to n wa aabo lọ sẹyin odi niyẹn.

“ Mo lo to oṣu meje si mẹjọ lai lọ sileewe nitori ogun, nigba ti mo si de Chad nibi, mi o tun ri ileewe lọ fun ọpọlọpọ oṣu.

“ Ni bayii ṣaa, mo ti ri ileewe, inu mi si dun nitori mo ti ni awọn ọrẹ tuntun. Mo ti ro pe gbogbo nnkan ti tan fun mi tẹlẹ ni. Pe mi o ni ọjọ iwaju mọ.” Bẹẹ ni Ahmed wi fun BBC.

Àwọn kan kò tí ì rí iléèwé lọ rárá

Aworan Gamareldin
Àkọlé àwòrán, Gamareldin ree, ọkan ninu awọn ọmọ ti ko ti i ri ileewe lọ

Ajọ Iṣọkan Agbaye (UN), sọ pe Sudan wa lara awọn orilẹede ti eto ẹkọ wọn buru ju lọ lagbaaye bayii. Wọn ni miliọnu mọkandinlogun (19 million) ni awọn ọmọ ti ko lọ sileewe mọ nibẹ. Ogun to bẹ silẹ lo si fa a ti miliọnu mẹfa ati aabọ ninu wọn ko fi lọ sileewe mọ.

Koda, pẹlu idasilẹ ileewe ti wọn ṣẹṣe kọ, o ṣi ju ẹgbẹrun lọna ogun akẹkọọ ti wọn ko ri ileewe lọ nibudo alainibugbe ti wọn n fori pamọ si.

Ọkan ninu awọn akẹkọọ ti ko ribi lọ naa ni Gamareldin, to jẹ aburo Ahmed.

“ O n ba mi lọkan jẹ gan-an ni, ẹgbọn mi ti bẹrẹ ileewe, emi ko ti i ribi kankan lọ''

Bayii ni Gamareldin wi pẹlu omije to fẹẹ jabọ loju rẹ, o sunkun ọjọ ọja ọla rẹ ti ko mọ bi yoo ti ri.

Hanan naa ṣalaye nipa awọn ọmọde ti ko ti i ri ileewe kankan lọ, o ni ojoojumọ ni wọn n wa sileewe awọn yii lati beere boya aaye wa. Ṣugbọn niṣe lawọn maa n sọ fun wọn pe awọn ko le gba wọn.

Aworan Abobakar to filu silẹ pẹlu awọn ẹbi rẹ nitori ogun
Àkọlé àwòrán, Abobakar, oun naa loun nireti pe ọmọ oun yoo le pari ẹkọ rẹ lorilẹede awọn lọjọ kan

Baba kan, Abobakar, lo bi Ahmed ati aburo rẹ, Gamareldin. O ni ile to wa niluu awọn lọkan oun wa roro, oun ko fẹẹ duro lẹyin odi.

“ Mi o fẹ kawọn ọmọ mi duro sibi, ireti mi ni lati pada sorilẹde mi kawọn ọmọ mi le pari ẹkọ wọn nibẹ.” Bẹẹ ni Abobakar wi.

Bi ogun ṣe n le si i kaakiri Sudan lai si ireti pe yoo dawọ duro laipẹ, o ṣoro lati sọ fun wọn pe igba bayii ni wọn yoo le pada silee wọn.

Ni ti Hanan, o ni oun ti gba f'Oluwa nigba tawọn akẹkọọ ti pada sileewe.

“ A gbagbọ pe ko si ewu fun wa lasiko yii rara.”

Bayii ni Hanan sọ.