Ronaldo ní ‘’ẹ ò tíì rí nǹkan kan’’ lẹ́yìn táwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lórí ìtàkùn ayélujára di bílíọ̀nù kan

Aworan Cristiano Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Yoruba bọ wọn ni ti ọmọ ẹni ba dara ẹ jẹ ka wi tori a o ni fi ṣaya, bayii gan an lọrọ gbajugbaja ẹlẹsẹ ayo ninu ere bọọlu, Cristiano Ronaldo, ṣe ri lẹyin to kede pe awọn olololufẹ rẹ lori itakun ayelujara ti di biliọnu kan bayii.

Pẹlu aṣeyọri tuntun yii, Ronaldo ni elere idaraya akọkọ lagbaaye tawọn ololufẹ rẹ to n tẹle e lori itakun ayelujara yoo wọ biliọnu kan.

Ninu ọrọ idupẹ ti Ronaldo to jẹ ẹlẹsẹ ayo fun ikọ agbabọọlu Al Nassr ni Saudia Arabia fi lede loju gbogbo opo ayelujara rẹ, o sọ pe biliọnu kan eeyan to n tẹle oun bayii jẹ nkan iyanu.

''Aṣeyọri mi yii ju nọmba lasan lọ, eleyii n ṣafihan ipinnu wa, afojusun ti a jọ ni ati ifẹ ti a jọ ni fun ere bọọlu ati ju ere bọọlu gan an lọ.

Lati ilu Madeira lorilẹede Portugal ti mo ti bẹrẹ irinajo mi to fi de ibi giga lagbaaye bayii, ni gbogbo igba ti mo ba n gba bọọlu lori papa ni mo maa n ni ẹyin ololufẹ mi atawọn ẹbi mi lọkan.

Ni bayii ti a si ti di biliọnu kan papọ, a si tun jọ wa bakan naa ni.

Ẹ o fi mi silẹ nigba kankan, lasiko to le ati lasiko to rọrun.

A jọ n rin irinajo yii ni, a si ti fi han gbogbo agbaye wi pe ko si nnkan ti a ko le jọ ṣe papọ.

Ẹ ṣe pupọ fun bi ẹ ṣe gbagbọ ninu mi, ẹ ṣe bi ẹ ti n ko ipa pataki ninu igbe aye mi.

Ẹ ma gbagbe pe ẹ o tii ri nnkan nipa aṣeyọri ti a le jọ ṣe papọ.

A o tẹsiwaju ninu igbiyanju wa, a o tẹsiwaju lati maa bori, a o si tẹsiwaju lati maa wọ inu iwe itan papọ,'' Ronaldo dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Atupalẹ awọn ololufẹ Ronaldo lori itakun ayelujara fihan pe miliọnu 638 eeyan lo n tẹle e loju opo Instagram, miliọnu 170 eeyan lori Facebook, nigba ti miliọnu 113 eeyan n tẹle e loju opo X rẹ.

Aṣeyọri yii fihan pe kii ṣe ninu ere bọọlu afẹsẹgba nikan ni Ronaldo ti ni ipa to lagbara, ipa rẹ tun ti milẹ titi bayii lori ayelujara nibi ti ọpọ eeyan ti n wo o gẹgẹ bi awokọṣe.