Wo àwọn ọkùnrin tó ń múra bí obìnrin àti ohun tí àwùjọ ń fi ojú wọn rí

Aṣa ki ọkunrin ma mura bi obinrin lo ti wọpọ ni awujọ wa, to si n sokunfa bi ibalopọ ṣe waye laarin ọkunrin si ọkunrin ni Naijiria.

Ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun yii ni yoo fi owo toto ẹgbẹrun dọla gbara tabi ko lọ si ẹwọn oṣu mẹfa sugbọn o da bi pe ọrọ ẹnu lasan ni.

Awọn to n mura bayi ni wọn ti ṣalapade ọrọ ti ko da lẹnu ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria ni tori iha ti aṣa ati ise ni awujọ wa kọ si. 

Lọdun 2014, Aarẹ Goodluck Jonathan buwọlu aba dofin to fi ofin de ibagbe ọkunrin ati ọkunrin tabi obinrin ati obinrin gẹgẹ bi ọkọ ati aya, ti wọn ko si gbọdọ ri wọn paapọ lawujọ.

Nigbati awọn aṣofin n sọrọ lọri ofin naa, wọn ni erongba awọn ni lati dabobo asa ati iwuri ilẹ adulawọ, paapaa julọ, ti orilẹede Naijiria.

Sugbọn, ọrọ ba ibo miiran yọ nigba ti pupọ lara awón to n se bi obinrin bẹrẹ si koju ibawi lọwọ awọn araalu.

Ọkan lara wọn, Fola Francis, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ni ọpọlọpọ igba ni oun igba ipe iku lati ọdọ awọn ti ko nifẹ si imura oun..

“Ofin yii ni ko dara, mi o ni anfani lati duro si ile mi, nitori wọn korira mi.”

“Mo ni lati saa kuro ni ile lẹyin ti fidio kan bọ si ori ayelujara, ti awọn amulelẹgbẹ mi si ri fọnran naa.”

Lọdun 2022, awọn aṣofin tun gbe ofin naa dide pe ko si aye fun ọmọ orilẹede Naijria to jẹ ọkunrin lati ma mura bi obinrin tabi ki obinrin ma mura bi ọkunrin.

Wò díẹ̀ lára àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó jẹ́ ọkùnrin ṣùgbọ́n wọn ń múra bí obìnrin

Adenrele Oluwafemi Edun:

Adenrele Oluwafemi Edun, ti ọpọ mọ si Denrele jẹ gbajugbaja amuludun, ti o si maa n fi ọpọ igba mura bi obinrin.

Denrele ni ọpọ igba ni awọn eeyan ti bu ẹnu atẹlu bi oun ṣe ma mura.

O ni lọdun 1990, awọn ero inu ọkọ kan le oun bọ silẹ kuro ninu mọto nitori pe oun mura bii obinrin.

Olanrewaju Idris Okuneye ‘Bobrisky’:

Ọpọ igba ni Bobrisky ti jade pe erongba awọn aṣofin lati fi ofin de awọn to mura bi obinrin ni ko ni wa imusẹ.

Olanrewaju lo wa lati idile musulumi ni ipinlẹ Ogun, to si dagba si agbegbe Ebutte Meta ni ipinlẹ Eko.

Lolu Vangei Jordyn

Lolu Vangei ni erongba awọn aṣofin lati mu ofin naa wa imusẹ ni ko jẹ ajoji si oun nitori pe ọpọ igba ni wọn ti ba oun wi ni awujọ.

Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Lolu Vangei , o si jẹ obinrin to ma mura bi ọkunrin.

“Ki abadofin naa to waye ni mo ti gba ibawi ninu ilu, ti ẹru si n ma ba mi.”

Jordyn ni aba dofin naa ni ko tọna rara nitori ohun to ba wu onikaluku ni o le ṣe.

James Brown “Princess of Africa”:

James Chukueze Obialor ni o jẹ osere sinima, alawada ati alajota ni orilẹede Naijiria.

 Lọdun 2018 ni ọwọ ọlọpaa tẹ awọn mẹtadinlọgọta kan ti wọn jẹ ‘Gay’, ti James Brown si wa lara wọn ni ile itura kan.

Brown ni o ti fi ọpọ igba gbe jade lori ayelujare pe oun jẹ ọkunrin to n mura bi obinrin.

Ki ni àwọn agbẹjọ́rò sọ nípa àbádòfin náà?

Agbejọro kan, Manfred Ekpe ni bi awọn aṣofin ṣe fẹ fi ofin de awọn ọkunrin to n mura bi obinrin lo tọna.

Awijare rẹ ni pe irufẹ iwa yẹn lodi si asa awujọ wa,

Ekpe tẹsiwaju pe iwe ẹsin mẹjeeji ni agbaye lo lodi si iwa naa, ti o si rọ awọn ọkunrin to mura bi obinrin lati fi awokọṣe rere silẹ fun awọn iran to n bọ lẹyin wọn.

Amofin Ekpe ni “Ofin naa ni yoo mu adikun ba awọn iwa to lodi si awujọ wa.”