Á san ọ̀pọ̀ mílíọ́nù náírà fáwọn olùpẹ̀jọ́ EndSARS - Ìjọba àpapọ̀

Ìjọba àpapọ̀ yóò fáwọn olùpẹ̀jọ́ EndSARS 75 ní N289m

Ijọba orilẹede Naijiria ti kede pe ninu osu kẹjo ọdun 2022, awọn yoo san owo gba ma binu toto miliọnu lọna ọrinlerugba ati mẹsan naira (N289m).

Awọn eeyan marundinlọgọrin ti wọn pe ẹjọ lori iṣẹlẹ iwọde EndSARS to waye lọdun 2020 si ni yoo gba owo naa.

Ikede yii ni ijọba apapọ fi si ori ayelujara lẹyin ti awọn igbimọ to ṣe iwadi iṣẹlẹ naa ti pari isẹ wọn.

Ijọba ni iwe ẹhonu nipa iwọde ENDSARS to to ọrinlerugba o din ẹyọ kan (279) ni oun tẹwọgba lati ipinlẹ mọkandinlọgbọn.

Ijọba ni oun ti kọkọ san owo gba ma binu toto milọnu lọna mẹrindinlaadọjọ fun awọn ọlupẹjọ mẹrindinlọgbọn ninu osu kejila ọdun 2021.

Ki lo fa iwọde ENDSARS?

Ifẹhonuhan EndSars lo jẹ ọkan gboogi ti a ba sọrọ ifẹhonuhan lorilẹede Naijiria.

Ogunlopọ eniyan lo tu sita nigba naa lati bu ẹnu atẹ lu ifiyajẹni awọn ọlọpaa to n gbogun tiwa ọdaran, ti wọn n pe ni Anti Robbery Squad, SARS.

Saaju iwọde yii, ifiyajẹni ọlọpaa SARS lo wọpọ lorilẹede yii.

Ẹka ọlọpaa Sars ni ọpọlọpọ ọdọ fi ẹsun ifiyajẹni lọna aitọ kan.

Iwọde naa si lo waye ipinlẹ mẹẹdọgbọn ni orilẹede Naijiria.

“Mo ti tan obìnrin tó lé ní ọgbọ̀n lọ ilé ìtura, fún wọn ní òògùn mu láti jà wọn lólé dúkìá”

Asamọ ọrọ kan lo ni inu mi ni mo mọ, n ko mọ inu ẹnikeji mi nitori oju la ri, ọrẹ ko denu.

Nibayi ti eto aabo ti n buru jai si lorilẹede Naijiria, o yẹ ki gbogbo wa maa fi oju sọri, ka ma baa ko sọwọ awọn ikooko ẹda, to da asọ aguntan bora.

Ọrọ yii si gbe awọn obinrin lori pupọ, paapaa nitori awn ọkunrin to le tan wọn lọ sibi kọlfin lati siẹ ibi.

O si yẹ ki awọn obinrin ka iroyin yii lai fi ti ọkunrin yii kọgbọn, ẹni to ti tan ọpọ obinrin jẹ lati ja wọn ni ole ara ati dukia.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lo tu asiri ọrọ naa ninu ikede kan to gbe soju opo ayelujara rẹ lọjọ Satide.

“Mo ti tan obìnrin tó lé ní ọgbọ̀n lọ ilé ìtura, fún wọn ní òògùn olóró mu láti jà wọn lólé dúkìá”

Ọkunrin kan ree, Ifeanyi Ezenagu ni orukọ rẹ, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn nii se, to si rẹwa lọkunrin.

Lọwọ lọwọ bayii, kunrin naa ti wa ni akata awọn ọlọpaa nibi to ti n ka boro-boro nipa isẹ ibi to ti se fun awn obinrin.

Agọ ọlọpaa Surulere nipinlẹ Eko si ni o ti n ka bẹẹ, to si salaye bo se maa n tan awn obinrin lọ sile itura.

Bakan naa lo ni nibẹ ni oun ti maa n fun wn ni oogun oloro mu, ki oun le ja wọn ni ole ara ati ti dukia.

Bawo ni ọwọ sinkun ọlọpaa se tẹ afurasi naa?

Yoruba ni bi irọ ba lọ logun ọdun, ọjọ kansoso ni otitọ yoo ba, bẹẹ ni ọrọ ri fun Ifeanyi yii.

Se ni ọwọ palaba to fi n sisẹ ibi naa segi lẹyin to ja awọn obinrin mẹfa ni ole dukia eyi ti apapọ owo rẹ to miliọnu meji, ọtalelọọdunrin ati mẹjọ naira (N2,368,000).

Ọna ẹtan ati alumọkọrọyi to maa n lo lati tan awọn obinrin, fi ja wọn lole dukia naa si lo tun lo pẹlu wọn.

Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko se wi “ Se ni ọkunrin yii tun tan awọn obinrin naa lọ sile itura, to si fi oogun oorun sinu ohun mimu to gbe fun wọn.

Awọn obinrin naa sun fọn-fọn lati aago meje alẹ di aago kan ọsan, to si raye ko awọn dukia wọn lọ.

Wo dukia to to N2, 368,000 ti afurasi naa gba lọwọ awọn boinrin to n tan:

Lara awọn ohun to gba lọwọ awọn obinrin naa ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ iPhone-12 mẹta, iPhone 11 Pro-max meji, iPhone XR kan.

Awọn dukia yoku ni foonu Nokia kan, aago ọwọ kan, goolu ọrun kan eyi ti apapọ gbogbo owo wọn to miliọnu meji, ọtalelọọdunrin ati mẹjọ naira (N2,368,000).

Ọpọ awọn obinrin to ti ja lole dukia yii si lo n mu ẹjọ rẹ tọ awọn ọlọpaa lọ, tawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ si n dọdẹ rẹ.

Awọn agbofinro to wa ni agọ ọlọpaa Surulere si lo nawọ gan, ti akara rẹ fi tu sepo.

Hundeyin ni iwadii ti n lọ lọwọ nipa ọkunrin naa, ẹni ti ko ni adirẹsi kankan pato, ti eeyan le wa si.

O fikun pe awọn ti gba awọn dukia to fi ọna eru gba yii lọwọ rẹ ko to di pe o lu wọn ta ni gbanjo.

O wa salaye pe awọn ti n tọpasẹ awọn to n sisẹ pẹlu afurasi naa ti awọn to n ba ta ọja ole to n fi ọna ero ko jọ.