You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kòkòrò àìsàn tó ń jẹ ẹran ara láti pa èèyàn láàrin ọjọ́ méjì tún gbalẹ̀
Ipinlẹ Florida to fojuwina ikọlu Hurricane Ian ni oṣu to kọja, ti tun n koju ajakalẹ aisan kan bayii, eyi tó n jẹ ẹran ara, to si n ṣekú pa eeyan.
Àwọn alaṣẹ sọ pe agbegbe Lee, nibi ti iji lile naa balẹ si lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹ̀sán-an, ti ni akọsilẹ eeyan mọkandilọgbọn ti kokoro aifojuri 'bacteria' ọhun ti ran.
O si ti ṣekú pa eeyan mẹrin, meji pere ninu awọn oloogbe yii si lo ni aisan yii sáájú ki iji lile naa tó waye.
Aisan naa, Vibrio vulnificus, ti wọn tun n pe ni kokoro a jẹran ara, ma n mu eeyan lẹyin ti kokoro aifoju ri naa ba wọ ara lati oju egbo.
Inu omi àgbàrá si lo ma n gbé.
Ẹ sọra fun kiki ara to ni ọgbẹ, egbò tabi ti nkan ha, bọ adagun omi tabi omi iyọ - Alaṣẹ
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ eto ilera lẹkun naa sọ pe, awọn ti ń wadii bi aisan Vibrio vulnificus ṣe n pọ si nitori bi awọn eeyan ṣe n rin ninu omi àgbàrá ati awọn adagun omi miran lẹyin iji lile Hurricane Ian.
Ninu atẹjade naa ni wọn tun ti kesi awọn olùgbé agbegbe naa, "lati sọra fun kiki ara to ni ọgbẹ, egbò tabi ti nkan ha, bọ adagun omi tabi omi iyọ."
Atẹjade naa tun sọ pe awọn ile igbọnsẹ ti Hurricane Ian wu jade tun le nu ki aisan naa gbilẹ si i.
Eeyan marunlelọgọta to ti ni aisan Vibrio vulnificus ni Florida, eeyan mọkanla ku.
Ni agbegbe Collier bakan naa, eeyan mẹta ni akọsilẹ ti wa pe o ni aisan to nii ṣe pẹlu iji lile.
Ko din ni eeyan marunlelọgọta to ti ni aisan naa jakejado ipinlẹ Florida, eeyan mọkanla si ti ku.
Bakan naa ni ọdun 2021, eeyan mẹwaa lo kú, mẹrinlelọgbọn si ni i aisan na.
Wọn n pe Vibrio vulnificus ni aisan a jẹ ẹran ara, nitori pe o le yọri ṣi 'necrotising fasciitis', aisan kan to ma n mu ki gbogbo iṣan ara da isẹ silẹ
Vibrio vulnificus maa n pa eeyan to ba mu laarin ọjọ meji
Àjọ to n mojuto itankalẹ aarun ni America, sọ pe eeyan kan ninu marun-un to ba ni Vibrio vulnificus lo ma n ku.
Paapaa laarin ọjọ kan si meji ti wọn ba dubulẹ aisan.
O tun le fa gìrì, to ba wọ inu ẹ̀jẹ̀, o si tun le mu ki wọn o ge apá tabi ẹsẹ alaisan ko ma ba ran awọn ẹ̀yà ara to kù.