Olubadan àná ló ní kí Makinde fi àtúnṣe ìlànà oyè jíjẹ tó yọ ọwọ́ Ladoja láwo ipò Olubadan sínú ìwé òfin ìjọba – Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti bọ sita lati ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ gan lori iwe ofin ijọba kan to lu sita laipẹ yii ninu eyi ti o ti sọ pe ọba ti ko ba dade ko le bọ si ipo Olubadanti Ilu Ibadan.

Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọyọ, Ọmọọba Dọtun Oyelade, fi sita, ijọba ipinlẹ Ọyọ ni o ti ya ju bayii lati maa sọrọ nipa ẹni ti yoo jẹ Olubadan lọla nigba to jẹ wi pe wọn ṣẹṣẹ fi Olubadan kan jẹ ni.

Atẹjade naa tẹsiwaju lati yannana rẹ pe, “Ohun to tini loju gidi ni lati maa gbọ pe lẹyin ọjọ diẹ ti wọn gbe ọpa oye le Olubadan tuntun Ọba Owolabi Ọlakulẹhin, Ige Ọlakulẹhin I lọwọ, lawọn eeyan kan ti yara bẹrẹ si nii nọga wo ejika ọba tuntun yii, ti wọn si n na ika si iwe ofin ijọba to buwọlu aba igbimọ oluyẹwo eto oye jijẹ nilu Ibadan pe o n gbero lati fagile awọn eeyan kan.”

Ijọba ipinlẹ Ọyọ niOlubadan to gbesẹ, Ọba Moshood Ọlalekan Balogun, Alli Okumade II lo gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe agbeyẹwo ilana oye jijẹ ni ilu Ibadan ki wọn si jiroro lori awọn atunṣe to yẹ fun eto oye jijẹ nilu Ibadan, ati bi ato ilana oye jijẹ ṣe ri lawọn ijọba ibilẹ gbogbo to wa ni ilẹ Ibadan ki wọn si gbe aba to ba yẹ kalẹ.

O ni igbimọ yii lo gbe aba wa pe ki gbogbo awọn oloye mọkanla to wa ninu igbimọ Olubadan o bẹrẹ si nii de ade.

Atẹjade naa tun yọju rẹ sita pe ninu lẹta kan to kọ si gomina ipinlẹ Ọyọ ni ọjọ karun un oṣu keji ọdun 2023, Ọba Balogun Alli mu u wa gẹgẹ bi aba pe ki wọn gbe awọn abajade ijọko ati ijiroro igbimọ naa wọ inu iwe ofin oye jijẹ ilu Ibadan ti ọdun 1957.

Lẹyin oṣu diẹ, iyẹn ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2023 kan naa ni ijọba ipinlẹ Ọṣun ba fi ountẹ lu u.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ wa rọ awọn eeyan lati maṣe dana wahala silẹ nitori pe ijọba yoo tubọ maa tẹle ohun to ba wo o pe o tọna ti o si wo pe o ba aṣa ati iṣe awọn eeyan rẹ mu.

Bawo lọrọ naa ṣe bẹrẹ gan?

Gbogbo eeyan lo ti mọ pe gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloye Rasidi Adewolu Ladoja ni ipo ọhun kan lẹyin Ọba to ṣẹṣẹ jẹ yii.

Bo tilẹ jẹ pe ṣaaju asiko yii ni wahala ẹni ti ipo Olubadan kan ti kọkọ suyọ ni kete ti ọba ana, Oba Mahood Olalekan Balogun waja.

Amọṣa, Ọrọ taani yoo jẹ Olubadan lẹyin Ọba Mahood Olalekan Balogun ti n fẹ da wahala miran silẹ bayii, pẹlu bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe gbe ilana tuntun kalẹ lori bi wọn yoo ṣe maa jẹ oye ọhun.

Ilana yii fi oju kọọrọ yọ ọwọ Ladọja kuro lawo itẹ ilu Ibadan nigba ti akoko rẹ ba to pẹlu abala kan ninu iwe ofin ti ijọba ipinlẹ Ọyọ kọ naa to sọ pe ẹni yoowu ti yoo ba gun ori itẹ Olubadan gbọdọ jẹ “ọba ti ade rẹ ba ga julọ ni ilana ọhun.”

Ko sẹni meji ti ipo rẹ tun ga ju ti Ladoja lọ ninu awọn to n jẹ oye Olubadan, ṣugbọn ti baba naa ti kọ jalẹ wi pe oun ko le ba wọn de ade kankan.

Eyi si ṣee ṣe ki ilana tuntun naa ma fun Ladoja ni anfaani lati de ipo Olubadan.