Nítorí ìwọ̀sí tó ń kan àwọn olóyè àgbà ni mo fi gbà pé kí wọn máa dádé- Olubadan

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ti tan imọlẹ si idi to fi pinnu lati fun awọn agbaoye mọkanla niluu Ibadan ni Ade Oba.

Kabiyesi sọ eleyi ni bi ayẹyẹ ifinijoye naa to waye ni gbọngan Mapo niluu Ibadan.

Ọba Balogun, ẹni ti olori osisẹ ijọba tẹlẹri nipinlẹ Oyo, Tajudeen Aremu gba ẹnu rẹ sọrọ ni igbesẹ lati fun awọn oloye ni Ade Ọba yii ko ni nnkan se pẹlu ipo ati ilana Olubadan to ti wa tẹlẹ.

Oba Balogun tẹsiwaju pe bi iwọsi se n ba awọn Oloye agba ni ilẹ Ibadan ni ko tẹ oun lọrun, ti oun si pinnu lati fun wọn Ade lati le fun wọn ni anfani lati ni iyi ati aponle to yẹ ki wọn ni lawujọ.

"A wa ni ibi bayi lati tun itan kọ nitori nnkan ti a n se loni ni o jẹ ọrọ itan.

"O ti tọ ni pe jijẹ Ọba ni ilẹ Ibadan da yatọ si ti awọn ilẹ Yoruba miiran."

"Awọn Agbaoye ni wọn ri iwọsi, ti wọn ko si ri aponle to yẹ lawujọ.

"Ti awọn Ọba ilu kekere, ti wọn ko tọ bi to agboole mi ni Aliwo ba le gba Ade ati iponle nitori pe wọn ni Ade lori, ko si nnkan to yọ awọn Agbaoye mi kuro lati ma gba Ade.

" Awọn Oloye yii nani wọn yoo di Olubadan lọla. Ko si nnkan to jọ mọ pe igbesẹ yii yoo da eto ati ilana to wa fun ilẹ Ibadan.

Ninu awọn agbaoye ti wọn gba Ade lọjọ Eti yii ni ati ri Otun Olubadan, Rasheed Ladoja, ẹni to kọ lati darapọ mọ ayẹyẹ naa.

Adé Olubadan nìkan ni mọ fẹ́- Ladoja

Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Rashidi Ladoja ti ni lati ọgbọn ọdun ṣẹyin ti oun ti di ipo Otun Olubadan mu ni oun ti fẹ jẹ oye Olubadan ti ilu Ibadan.

Ladoja lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni lootọ ni oun gbọ awuyewuye nipa awọn oloye ti wọn fẹ maa de ade amọ oun ko ni nkan se nipa rẹ.

O ni ade ẹyọkan ṣoṣo to wu oun de lati igba pipẹ wa ni ade olubadan, ati pe oun ko nifẹ si ade miran.

Bakan naa lo fikun un pe ki ijọba gba awọn to nifẹ lati de ade gẹgẹ bi oloye ni aaye lati de ade wọn, kii ṣe ade ti ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo fun wọn.