Gómìnà Sanwo-Olu ṣàbẹ̀wò sí'bi tí bàlúù kékeré kan ti já lulẹ̀, l'Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, Sanwo-Olu

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu t ṣabẹwo si ibi ti ọkọ ofurufu ẹlikọpta ti ja lulẹ ni Ikeja, nipinlẹ Eko.

Sanwo-Olu gboriyin fun awọn oṣiṣẹ pajawiri ati gbogbo awọn to tuyaya jade lati doola ẹmi awọn eniyan.

Ninu atẹjade ti akọwe fun gomina naa, Gboyega Akọsile fi lede to ti sapejuwe ọkọ ofurufu naa gẹgẹ bi eleyii to ni engine kekere, pẹlu nọnba idanimọ 5NCCQ.

Ọkọ ofurufu kekere naa lo ja lulẹ pẹlu awọn to wa ninu rẹ si agbegbe Oba Akran Avenue, Ikeja, Eko.

Awọn meji to wa ninu ọkọ ofurufu naa ni wọn doola ẹmi wọn ti wọn si w ani ileewosan nibi ti wọn ti n gba itọju.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Sanwo-Olu/Twitter

Lẹyin ti gomina naa wo ibi iṣeḷ naa tan lo sọ fun awọn oniroyin pe oun lọ si papakọ ofurufu lati darakọ mọ aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu to n lọ si Benin Republic.

Bakan naa lo fi da awọn eniyan loju pe ko si ẹmi to sọnu ninu iṣẹlẹ naa.

Gomina naa ni oun dupẹ lọwọ Ọlorun wi pe iṣẹlẹ naa ko la ẹmi awọn eniyan lọ.

To si ni fikun pe ajọ to n sewadii isẹlẹ pajawiri, Nigerian Safety Investigation Bureau (NSIB) ti bẹrẹ iwadii kikun lori iṣẹlẹ naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, SanwoÒlu

Wọ́n ní awakọ̀, òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ náà àtàwọn èrò méjì ló wà nínú ọkọ̀ náà tí àwọn sì ti dóòlà wọn.

Àtẹ̀jáde kan tí àjọ panápaná Eko fi síta ní ọkọ̀ òfurufú náà jẹ́ èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́.

Adarí àjọ náà Adeseye Margaret ní àwọn ènìyàn mẹ́rẹ́ẹ̀rin tó wà nínú ọkọ̀ náà ni wọ́n móríbọ́ láàyè àmọ́ tí wọ́n farapa.

Margaret ní ohun gbogbo ti padà bọ̀ sípò ní agbègbè náà tí àwọn sì ti ṣe ohun gbogbo láti fi dènà ìjàmbá tó tún le ṣẹ́yọ látara ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn àwòrán tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí àwọn ènìyàn ṣe péjọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti pa iná ọkọ̀ òfurufú ọ̀hún lásìkò tó ń jó.