‘’Ohun ìjagun ní àwọn orílẹ̀èdè ní àgbáyé ń ná owó lé lórí báyìí’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadii ti fihan pe ohun ija ogun ni awọn orilẹede ni agbaye n na owo to pọju lọ si bayii.

Iwadii ti ileeṣẹ imọ ijinlẹ nipa ọrọ aigbọraẹniye ni Sweden fihan pe ni itan agbaye igba akọkọ ni yii ti iye owo ti awọn orilẹede naa lati ra ohun ija yoo pọju lọ.

Wọn ni eyi ko ṣẹyin ijogun to n waye laarin orillẹede Russia ati Ukraine to fi mọ aigbọra ẹniye ni ija Ila oorun Asia, paapaa Taiwan.

Aṣoju ileeṣẹ BBC ni iye owo ti wọn n na lati ra ohun ijagun laarin ọdun mẹjọ fun igbaradi fun ogun ko mọ ni iwọn paapaa ni ilẹ Yuroopu.

Bakan naa ni ileeṣẹ to n risi ọrọ alaafia lagbaye, International Institute for Peace Research ni Stockholm ni iye ti wọn naa laarin ọdun kan le ni triliọnu meji dọla.

Iwadii ọhun fikun un pe orilẹede Amẹrika lo ra ohun ijagun julọ ni agbaye.

Àwọn orílẹ̀èdè tó tí kó àwọn ènìyàn wọn kúrò ní Sudan rèé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọlọpọ orilẹede lo ti n ko awọn eniyan wọn kuro ni Sudan bayii lẹyin ti ija laarin awọn ọgagun naa wọ ọṣẹ keji.

Nkan bii ọṣẹ meji ṣẹyin 1 ni ija bẹ silẹ ni Khartoun laarin awọn ọgagun meji ti wọn n tako ara wọn gẹgẹ bi adari lorilẹede naa.

Igun ikọ ọmọogun to gbajọba lo n koju ikọ RSF to n lọgun lati gba ijọba.

Iye orilẹede to ti ko awọn eniyan wọn kuro niyii

  • Ọjọ Aiku ni orilẹede Amẹrika, Canada ati Ilẹ Gẹẹsi kede pe awọn n ko awọn eniyan wọn kuro ni Sudan.
  • Aarẹ ilẹ Faranse, Emmanuel Macron kede pe Ọjọ Aiku ati Ọjọ Ajẹ ni awọn yoo gbe awọn eniyan wọ̀n to le ni 388 kuro nibẹ.
  • Bakan naa ni orilẹede Belgium ni awọn ti ko awọn eniyan wọn ni ilu Kahrtoum pẹlu ọkọ ofurufu ilẹ Farance.
  • Ijọba Ilẹ Gẹrman ni ọkọ ofurufu mẹta ti kuro ni Sudan lọ si Jordan fun aabo awọn ẹniyan mọkanlelọgọrun to wa ninu baalu naa.
  • Italy, Spain naa ni awọn ti kọ awọn eniyan wọn kuro to fi mọ awọn ọmọ ilẹ Argentina, Colombia, Portugal, Poland, Mexico, Venezuela ati Sudan.
  • Turkey fi ọkọ ko awọn eniyan to le ni ẹgbẹta lati gba oju ọna kuro ni Sudan pẹlu awọn eniyan lati orilẹede Azerbaijan, Japan, China , Mexico ati Yemen.

Igba akọkọ kọ ni yii ti ija ti n waye ni Sudan.

Ogun abẹle laarin iha ariwa ati gusu orilẹede naa pa idaji miliọnu awọn eniyan ti ogun to n waye ni Darfur si ti sọ awọn eniyan to le ni miliọnu meji di alairile gbe.