You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Ọkàn mi ti wà lára Ẹja 1,500 tí mo ń sìn láti tà a, omiyalé kó gbogbo ẹ̀ lọ'
- Author, Emmanuel James
- Role, Video Journalist
Omíyalé tí Kwara fẹ́ yàtọ̀ sí bó ṣe ń wáyé láwọn ìpínlẹ̀ míì.
Àbí ká ní o tún kó gbogbo ẹ̀ pọ̀ ni. Gbogbo ẹja, ẹ̀fọ́, ewédú tí àwọn àgbẹ̀ ń tà ni wọn ni o ti lọ patapata.
Awọn agbẹ ọlọsin ẹja ati ti ko lee de oko mọ ti figbe bọ ẹnu ni ipinlẹ Kwara to fi mọ awọn ọmọ ile ẹkọ ti ASUU da pada sile lati ọjọ yii.
Wọn dawo jọ lati maa sin ẹja ki wọn le ri mu lọ si ile ẹkọ.
Hamza Abdulwasiu to jẹ agbẹ ẹlẹja ni ipinlẹ Kwara ba BBC Yoruba sọrọ to si ni oun gbagbọ pe ayipada oju ọjọ ti oloyinbo n pe ni "Climate Change" lo ṣẹlẹ lootọ amọ ti ọtẹ yii ti pọ ju.
"Tẹlẹ ti yoo ba fi di asiko yii, a ti maa n wọ ẹrọ alupupu wa lọ si ibi ti odo ba wa lati wa omi fun ẹja wa lati ye amọ ko ri bẹẹ lọdun yii".
Bakan naa ni ọmọ ile ẹkọ kan, Nasirudeen Buhari sọ ipo ti iṣẹlẹ omiyale sọ ọ si lẹyin gbogbo igbiyanju rẹ lati ko owo jọ ta ẹja ko lee ri owo mu lọ ile ẹkọ.