You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn òsèré tí wọ́n ní ìdádúró kí wọ́n tó di ọlọ̣́mọ rèé…
Ayọ ti ọkọ ati iyawo ni ni lati jẹ ọlọmọ ni aye, bẹẹ si ni ayọ igbeyawo ni ki a ri ọmọ gbe jo.
Amọ ni ọpọ igba, ọkọ ati iyawo ma n ni idaduro ati bimọ ti wọn a si koju ọpọ iṣoro amọ ni ikẹyin, wọn a fi inu se oyun, wọn a si fi ẹyin gbe ọmọ pọn.
Ni ẹka amuludun ni Naijiria, akojọpọ awọn ti wọn ni idaduro ati bimọ ree
Niyi Johnson ati Seyi Edun
Ọdun 2013 ni Adeniyi Johnson ati Toyin Abraham ti wọn mọ si Toyin Aimakhu tẹlẹri se igbeyawo amọ lẹyin ọdun meji, igbeyawo wọn fi ori ṣanpọn ni ọdun 2015.
Lẹyin igba naa ni Niyi fẹ osere miran ti orukọ rẹ n jẹ Oluwaseyi Ẹdun ni ọdun 2018, amọ wọn ko di ọlọmọ titi Osu keji, ọdun 2023, eleyii to waye ni ọjọ ibi rẹ pẹlu.
Johnson kọ si oju opo Instagram rẹ pe ọdun meje ni oun ati iyawo oun fi wa ọmọ amọ ni ọni, oun ti di baba ibeji.
Gbogbo araye, ẹbi ara ati ọrẹ lo ba wọn pe jọ lati se ayẹyẹ ọmọ bibi naa, to fi mọ awọn ololufẹ wọn loju opo Instagram.
Biola Adebayo
Ti ọmọde ti agba lo fẹran Biola Adebayo ninu ọmọ jẹjẹ ti o ma n se ninu ere.
Igbeyawo rẹ akọkọ pẹlu arakunrin kan ni Ile Gẹẹsi waye ni ọdun 2013, to si lọ bao ̣kọ rẹ lẹyin igbeyawo rẹ.
Amọ lẹyin ọdun kan ni igbeyawo wọn fi ori sanpọn ti wọn si ni idi ti awọn fi pinya ni pe ẹjẹ wọn ko bara mu ni awọn se pinya,
Biola Adebayo gbiyanju lati fẹ ẹlomiran ni ọdun 2021, ti orukọ ọkọ rẹ si jẹ Oluwaseyi Akinrinde, ti wọn si ni wọn simọ ara wọn fun ọdun mẹta ki wọn to se igbeyawo.
Lẹyin naa ni wọn ni idaduro ọmọ amọ osu kẹrin, ọdun 2023 ni wọn di ọlọmọ
Ohun ti Biola sọ lori ẹrọ ayelujara ni pe ohun ti wa ọmọ ti ko si tete wa, koda o ti se IVF, amọ ẹlomiran lo bag be oyun naa to si dupẹ lọwọ Ọlọrun, to sọ oun ti iya ọlọmọ.
Ini Edo
Gbajugbaja osere ni Ini Edo to si kede ni ọdun 2021 pe oun ti di iya ọlọmọ lẹyin ti oun ri ẹni gbe oyun fun oun, ti wọn pe ni ‘’Surrogate Mother’’.
Lasiko to ba oniroyin ori ayelujara kan sọrọ, Stella Dimoko-Korkus sọrọ lo ni pe lootọ ni oun ni ọmọbinrin kan lẹyin ti wọn bag be oyun naa.
O ni idi ti oun fi gbe igbesẹ bẹẹ lati di ọlọmọ ni pe oun ko faramọ bi awọn obi miran se n ja lori ọmọ, ti awọn kan ma n ja lori ọmọ.’’
Bakan naa lo fikun un pe oun ko fi aworan ọmọ oun si ori ẹrọ ayelujara nitori pe oun ko fẹ ki awọn eniyan mọ bi o se n lọ pẹlu ọmọ ohun.
Ini Edo ni oun fẹ da abo bo ọmọ oun ni ọna ti yoo fi rọrun fun gbogbo wọn.
Funke Akindele
Osere to gbajugbaja ni Funke Akindele, to si duro fun ọpọlọpọ ọdun ki o to di ọlọmọ.
Igbeyawo akọkọ rẹ fi ori sanpọn lẹyin to se igbeyawo ni ọdun 2012, ti ko si lo ọdun nibẹ ti o fi tuka, amọ ko si ọmọ laarin wọn.
Ọdun 2016 lo fẹ gbajugbaja osere bii tirẹ, Abdulrasheed Bello, aka JJC Skills ni ọdun 2016, ti ọpọ si gbadura fun wọn.
Igbeyawo naa ni ọmọ lanti lanti meji, ti gbogbo agbaye si ba wọn yọ ayọ ọmọ.
Amọ ni ọ̀un 2022 ni JJC kede pe igbeyawo awọn ti tuka.
Toyin Abraham
Gbajugbaja osere, Toyin Abraham ni ọpọ eniyan mọ bi o se n lọ ninu aye rẹ.
Adeniyi Johnson ni wọn kọkọ jọ se igbeyawo ni ọ̀un 2013, ti ọpọ si ro pe wọn maa pẹ titi amọ igbeyawo naa fi ori sanpọn ni ọ̀un 2015.
Ọdun 2019 ni Toyin Abraham fẹ osere miran, Kolawole Ajeyemi ti wọn si bi ọmọkunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Ire.
Ni ọdun to kọja ni oserebinrin naa kede pe oun padanu oyun inu oun nitori oun fẹ bimọ si amọ iṣẹlẹ naa waye.
O ni o dun oun lọpọ amọ oun pinu lati tẹsiwaju.