You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Makinde fi ‘Ticket’ tí wọ́n padà gbé fún Tegbe lọ̀ mí ṣùgbọ́n mo ní mi ò fẹ́ – Kola Balogun
Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Guusu Ọyọ nile igbimọ aṣofin agba, Kọla Balogun ti ṣalaye pe Gomina Ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde gbiyanju lati fa oju oun mọra pada sinu ẹgbẹ oṣelu PDP ṣugbọn oun kọ jalẹ.
Eyii lo n waye lẹyin ti o fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).
Balogun lo sọ ọrọ naa lopin ọsẹ lori eto oṣelu kan nileeṣẹ redio Fresh FM, ilu Ibadan.
O ni ṣaaju eto idibo abẹle, ninu eleyii ti oludije sipo Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Joseph Tegbe ti gba anfani lati dije gẹgẹ bii Sẹnetọ ninu eto idibo si ile igbimọ aṣofin lọdun 2023, ni Makinde ti ran awọn eeyan si oun lati pada sinu ẹgbẹ oṣelu PDP lati dije du ipo Sẹnetọ, ṣugbọn o ti bọ sori nitori oun ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu alatako, APC.
Anfani ti Balogun ko ni lati dije fun saa ikeji lo mu ko darapọ mọ APC ki o le de ibi ilẹpa rẹ.
Amọ oludije sipo Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Sharafadeen Alli ni ẹgbẹ naa fun ni anfani lati dije, oun lo si jawe olubori ninu eto idibo naa.
Balogun ni iba jẹ wi pe oun tẹwọgba anfani ti Makinde fi ṣọwọ si oun ṣaaju asiko ti wọn gbe fun Tegbe ni, ko ba ti ja si nnkan iwọsi nitori gbogbo aye ni yoo maa pariwo pe oun ti di alagbere oṣelu to n ti ibi kan bọ si ibi ikeji.
Balogun fi kun ọrọ rẹ pe oun ko kabamọ pe oun darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, oun ko si ni yi ipinnu oun pada bi anfani ba tun yọju lati dije du ipo.