You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Olórí ẹ̀sìn kankan tó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọdún tuntun yóò rugi oyin - Ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Ghana ti ṣe ikilọ fun awọn olori ẹka ẹsin gbogbo ni orilẹede naa, lati dẹkun sisọ awọn asọtẹlẹ ọdun, eleyi to le fa ipaya ati ibẹru fun araalu.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, ileeṣẹ ọ̀lọpaa ni ẹtọ ati ṣe ẹsin kankan to ba wu ni ko gbọdọ tẹ ẹtọ ẹlomiran naa mọlẹ.
Awọn onwoye kan n sọ pe aṣẹ yii ko bofinmu nitori pe o tako ẹtọ ọmọniyan to de ominira lati ṣe ẹsin to ba wu ni.
Ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi lo maa n pejọ pọ lawọn ṣọọṣi lati gbọ awọn asọtẹlẹ fun ọdun tuntun lẹnu awọn pasitọ wọn.
Ọdun to kọja ni aṣẹ ọlọpaa yii kọkọ waye lẹyin ti awọn asọtẹlẹ iku, hilahilo ati rogbodiyan gbode
Awọn asọtẹlẹ wọnyi si le jẹ ti afojusun ohun rere fun ọdun tuntun tabi ko jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ tabi ba ni lẹru gidigidi.
Gẹgẹbi ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede Ghana ṣe sọ, ni ọdun to kọja ni aṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa yii kọkọ waye lẹyin ti awọn asọtẹlẹ iku, hilahilo ati rogbodiyan gbode kan lorilẹede naa.
Ninu atẹjade kan, ileeṣẹ ọlọpaa kan sara si awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ẹlẹsin gbogbo fun ajọṣepọ wọn lori rẹ ati bi wọn ṣe n tẹle ilana to ba ofin mu fun fifọnrere asọtẹlẹ wọn.
Awọn amofin n fọnmu lori aṣẹ yii
Amọṣa o, amofin kan lorilẹede Ghana, Sammy Darko faake kọri pe aṣẹ ti ko ba ofin mu rara ni aṣẹ ti ọlọpaa gbe kalẹ naa.
“Kii tilẹ ṣe ohun ti o yẹ ki a maa gba bi ẹni n gba igba igba ọti tabi to nilo itumọ lati ọdọ ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Ghana.
Ko si ofin kankan lorilẹede Ghana to fun ọlọpaa ni agbara lati maa ṣe amojuto lori asọtẹlẹ ni orilẹede yii”
Amofin Darko fi kun un pe, “ Ominira ẹsin ju ọrọ ‘ominira lati jọsin’ ni sinagọgu, ṣọọṣi tabi mọṣalaṣi kan.
O tumọ si pe awọn eeyan ko nilo lati ṣe lodi si ohun ti wọn gbagbọ nitori pe wọn fẹ ṣe ohun ti aṣa tabi ijọba wọn fẹ ayafi ti nnkan bẹẹ ba tako ofin kan ni pato.”
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko sohun ti yoo yi aṣẹ rẹ pada
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Ghana ni oun ti ya ọjọ kẹtadinlọgbọn sọtọ gẹgẹ bi ọjọ titẹle ilana lamẹtọ lori kikede asọtẹlẹ.
Atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa Ghana tun fi sita naa tun sọ pe, “A ya ọjọ yii sọtọ lati ran gbogbo wa leti lati maa ṣe ẹsin wa ni ibamu pẹlu ofin.
Eyi wa lati lee ri pe abo to peye wa ni awujọ lai si ipaya nipasẹ awọn asọtẹlẹ nipa irọdẹdẹ wahala, ewu tabi iku.”