"Lẹ́yìn ọmọ àkọ́bí, ọdún mẹ́jọ ni Bolanle Raheem fi wá oyún oṣù mẹ́fà tó wà nínú rẹ̀ tí ọlọ́pàá tó pa á"

Bolanle Raheen ni èèyàn kejì táwọn ọlọ́pàá Ajah yóò pa láàrin ọ̀sẹ̀ méjì - Macaroni

Lẹyin ti ọlọpaa kan yinbọn pa amofin, Bolanle Raheem niluu Eko, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iṣẹlẹ naa.

Ni kete ti iroyin iku ọhun jade ni awọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ ọlọpaa fun bi wọn ṣe n pa araalu ni ipakupa.

Lara awọn to ti da si ọrọ naa bayii ni adẹrinpoṣonu kan to tun jẹ ajafẹtọ, Adebowale Adedayo, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Macccaroni.

Bakan naa ni gbajumọ kan lawujọ asaraloge, Toyin Lawani, ti oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oselu APC, Bola Ahmed Tinubu naa ko si gbẹyin.

Koda, oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu PDP naa, Atiku Abubakar ati ogunlọgọ awọn ọmọ Naijiria mii lo ti gbarata lori isẹlẹ ipaniyan naa.

Bolanle fun meji lara ọmọ mi ni ilẹ lọfẹ, ololufẹ alaafia ni - Toyin Lawani

Ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ, Toyin Lawani sọ pe ṣe ni oun n wa ẹkun mu lẹyin ti oun gbọ iroyin iku oloogbe naa.

O ni “Mo kọkọ ro pe ere ni iroyin naa amọ kii ṣe ere o, Bolanle ti lọ... o ṣi ba mi sọrọ lọsẹ to kọja nipa ajọṣẹpọ wa lori ileeṣẹ Croston Homes gẹgẹ bii aṣoju ileeṣẹ naa.”

“Ileeṣẹ Croston Homes yii fun meji lara awọn ọmọ mi ni ilẹ, eeyan to fẹran alaafia ni, wọn ko fẹ wahala ninu idile wọn.”

“Iwaju ọkọ rẹ, ọmọ ati awọn ọmọ aburo rẹ ni ọlọpaa ti yinbọn lu.”

“Eyii to buru ju nibẹ ni pe oyun wa ninu rẹ, o si ti n wa oyun yii lati ọdun mẹjọ sẹyin.”

“Awọn ọlọpaa to yẹ ko maa daabo bo wa lo tun n pa wa o.”

“Ẹyin ọlọpaa Naijiria nigba wo ni ẹ o dẹkun ati maa fun awọn ọmuti ni ibọn...

Gbogbo wa gbọdọ fọwọsọwọpọ lati ri daju pe ẹni to ṣiṣẹ yii jiya to tọ labẹ ofin.”

Bolanle ni ẹnì kejì tí àwọn ọlọ́pàá Ajah yóò pa lárìn ọ̀sẹ̀ meji – Mr Macaroni

Nigba ti yoo da si ọrọ naa, aderinpoṣonu, Mr Maccaronmi sọ pe agbegbe ti ọlọpaa to pa agbẹjọro yii ti wa, naa ni awọn ọlọpaa kan ti ṣeku pa ọkunrin kan, Gafaru Buraimoh ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin.

Mr Macaroni sọ pe o ṣe ni laanu pe ọlọpaa kọ lati fi oju afurasi naa lede amọ to ba jẹ araalu lo daran, wọn yoo fi orukọ ati aworan rẹ lede.

Beẹ naa lo tun sọko ọrọ si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu pe ṣe ni awọn agbofinro n paayan bii ẹni pa ẹran labẹ iṣẹjọba rẹ, amọ ko ri nnkankan sẹ nipa rẹ.

Ẹgbẹ awọn agbẹjọro (NBA) yari

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA, ti sọ pe ọlọpaa to pa Bolanle ko ni lọ lai foju wina ofin.

Ninu atẹjade kan loju opo Twiiter rẹ, NBA sọ pe awọn ti gbe igbimọ kan dide ti yoo ṣe iwadii ọrọ naa ni kikun, ki ẹbi oloogbe le ri idajọ ododo gba.

NBA sọ pe gbogbo ohun ti yoo gba lawọn yoo ṣe ki idajọ ododo le waye.

Tinubu, Atiku atawọn mii ba ẹbi oloogbe kẹdun

Wayi o, awọn oludje sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP, Bola Tinubu ati Atiku Abubakar ti bu ẹnu atẹ lu ipaniyan naa.

Tinubu ni irufẹ iwa idukoko mọni bẹẹ lati ọdọ ọlọpaa si araalu ko ṣe itẹwọgba.

Nigba ti Atiku sọ pe asiko ti to lati fọ ileeṣẹ ọlọpaa mọ.

Ìyàwó mi ló ní ká gbé àwọn àlejò wa jáde lọ ra ìpanu lẹ́yìn ìsìn ọdún, tó fi pàdé ikú òjijì - Ọkọ Amòfin tó kú

Ọlọ́pàá tó pa ẹ̀gbọ́n mi sálọ pẹ̀lú ọkọ̀ ọlọ́pàá àmọ́ mo fi ọ̀kadà le ní àṣírí rẹ̀ fi tú - Àbúrò Amòfin

Gbenga Raheem, to jẹ ọkọ agbẹjọro ti ọlọpaa yinbọn pa niluu Eko, Bolanle Raheem, ti ṣalaye bi ọlọpaa naa ṣe yinbọn pa iyawo rẹ.

Gbenga Raheem salaye nipa isẹlẹ naa lasiko ti ọpọ awọn abanikẹdun ṣabẹwo sile rẹ to wa ni Ajah.

Ọjọ ọdun Keresimesi ni ọlọpaa naa, Drambi Vandi, yinbọn pa Omobolanle lasiko to n yi oju ọna olobiripo to wa labẹ afara Ajah.

Isẹlẹ naa lo ti n fa awuyewuye lori ayelujara, ti ọpọ ọmọ Naijiria ati ẹgbẹ awọn agbẹjọro nilẹ wa si ti koro oju si isẹlẹ naa.

Bẹẹ ba gbagbe, igbakeji ree ti afurasi ọlọpaa yoo yinbọn pa eeyan lagbegbe Ajah nilu Eko laarin ọsẹ meji.

“Bi ọlọpaa ṣe yinbọn pa iyawo mi lọjọ ọdun ree”

Kayode ninu alaye rẹ ni “Emi ati gbogbo ẹbi mi atawọn to wa ba ṣe ọdun lọ sile ijọsin lọjọ ọdun Keresimesi.

Nigba ti a n pada bọ, ni iyawo mi sọ pe ki a gbe gbogbo wọn jade lati ṣe faaji ọdun.”

“Idi ree ti a fi lọ sile itaja kan ni Abraham Adesanya, lẹyin naa ni a lọ si Domino’s Pizza.”

“Bi a ṣe n bọ, a gba ọna Ajah lati yi ọna obiripo to wa labẹ afara naa.”

“A ri awọn ọlọpaa kan to n da awọn ọkọ duro, wọn ni ki a duro, bi a ṣe n gbiyanju lati duro bayii ni a gbọ iro ibọn to dun lẹgbẹ ibi ti iyawo mi joko si.”

"Oyun osu meje wa ninu Bolanle Raheem ti ọlọpaa yinbọn pa"

“Lojiji, mo ri ti ẹjẹ n ṣan jade lati aya rẹ...

Lẹsẹ kan naa ni mo sare jade temi ti ibatan rẹ to wa pẹlu wa, a si gba ọlọpaa naa mu, o tun gbiyanju lati yin ibọn lu aburo iyawo mi naa.”

“Nigba ti a ri pe ko si nnkankan ti a le ṣe, ti iyawo mi si n pọkaka iku, a gbe lọ sile iwosan kan amọ wọn sọ pe apa wọn ko ka.”

Ọkọ oloogbe naa ṣalaye pe asiko ti awọn yoo fi gbe de ile iwosan Grandville ni wọn kede pe o ti dakẹ.

Iroyin kan ni oyun oṣu meje wa ninu oloogbe ọhun ṣaaju iṣẹlẹ laabi yii.

Ọlọpaa to yinbọn pa ẹgbọn mi gbiyanju lati salọ amọ mo lọ lasọ mu – Aburo oloogbe

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin TVC, aburo oloogbe naa to wa ninu ọkọ pẹlu rẹ lasiko ti ọlọpaa yinbọn lu ẹgbọn rẹ ṣalaye ohun ti oju rẹ ri.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ni kete ti ọlọpaa naa yinbọn lu Bolanle tan, ni oun jade kuro ninu ọkọ naa lati lọ gba ọlọpaa to yinbọn mu, ko ma baa salọ.

O ni bi oun ṣe sọ fun ọlọpaa ọhun pe o ti yinbọn pa ẹgbọn oun, ni ọlọpaa naa tun gbe ibọn ọhun soke, to si dunkoko pe oun pẹlu yoo fara gba ọta.

Aburo oloogbe naa ni ọlọpaa ọhun gbiyanju lati salọ amọ oun gba mu.

Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa naa salọ nigbẹyin-gbẹyin, obinrin naa ṣare tẹle lori alupupu ki ọwọ to tẹ.

Gẹgẹ bii bii ohun ti a gbọ, ọdun mẹtalelọgbọn ni afurasi ọlọpaa to yinbọn pa Bolanle ti lo nidi iṣẹ ọlọpaa.

Ta ni oloogbe Bolanle Raheem?

Ẹni ọdun mọkanlelogoji ni Omobolanle Raheem.

Fasiti Olabisi Onabanjo to wa ni ni Ago iwoye, ni ipinlẹ Ogun, lo ti kẹkọọ gboye ko to bẹrẹ iṣẹ agbẹjọro to ni ṣe pẹlu ọrọ dukia ati ile.

Oun ni ọga agba ati adari ileeṣẹ Croston Homes, o tun wa lara awọn to da ileeṣẹ City Building silẹ, eyii to jẹ ileeṣẹ to maa n ri si ọrọ ilẹ ati ile.

Ko to jade laye, ọmọ ijọ Redeemed Christian Church of God ni.

O si jẹ ọkan lara awọn to n jọsin ni ẹka ijọ naa, Olive Tree Parish, to wa ni Banana Island, Ikoyi, nilu Eko.