Iléejọ́ dájọ́ ikú fún obìnrin méjì lórí ẹ̀sùn pípolongo ìbálòpọ̀ abo sí abo

Zahra Seddiqi Hamedani

Oríṣun àwòrán, Guiti RA/FACEBOOK

Ile-ẹjọ kan ni Iran ti da Zahra Seddiqi Hamedani ati Elham Choubdar lẹbi iku fun iwa ibajẹ.

Awọn mejeeji jẹ ajafẹtọ ẹni nidii igbeyawo laarin akọ si akọ ati abo si abo.

Ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, Hengaw ni, wọn fi ẹsun sise agbega ibasepọ laarin akọ si akọ ati abo si abo kan kan awọn obinrin mejeeji naa.

Bakan naa lo ni wọn fi ẹsun pipolongo ẹsun Kristiẹni ati lílo ẹrọ ayelujara to lodi si ofin islam ni Iran, kan awọn ajafẹtọẹni naa.

Àjọ ti o risi eto idajọ ni Iran jẹri si idajọ ile ẹjọ́ naa, o ni awọn ajafẹtọẹni naa tun jẹbi ẹsun fifi eniyan ṣowo.

Ajọ Hengaw to fidi isẹlẹ yii mulẹ ni Norway sọ pe Seddiqi Hamedani, ti a tun mọ ni Sareh, wa lati ilu Kurdish.

O ni Naqadeh jẹ ilu nla ni agbegbe Iwọ-oorun Azerbaijan, eyiti o pin aala pelu Turkey ati Iraq.

Ajo Amnesty International ṣapejuwe Zahra Seddiqi Hamedani gẹgẹ bi “olugbeja ẹtọ eniyan.

Ajo Amnesty International royin pe Oṣu Kẹwa Ọdun 2021 ni ẹka ikọ ologun ilu Iran (IRGC) mu Zahra Seddiqi Hamedani lakoko ti o n gbiyanju lati rekọja si Turkey.

Labẹ ofin Iran, iwa-ibalopọ laarin akọ si akọ ati abo si abo jẹ ẹṣẹ ọdaran, ti ijiya ti o tẹle si jẹ ijiya iku.

Eyi ni igba akọkọ ti obinrin yoo ri idajọ iku ni Iran fun ẹsun ibalopọ pẹlu ìṣẹ̀dá re.