Òpin dé bá ilé ìjo, ̀̀Ọkadà alẹ́! Wo ìdí tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo fi fòfin dè wọ́n

Gómìnà Rotimi Akeredolu àti ọ̀kadà

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo ti kéde pé àwọn ti fi òfin de àwọn ọlọ́kadà ní àwọn wákàtí kan ní ìpínlẹ̀ náà.

Olùbádámọ́ràn gómìnà Rotimi Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ ààbò, Akogun Adetunji Adeleye ní ìjọba ti ṣetán láti fi òfin dè é wí pé àwọn ọlọ́kadà ko gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ mọ́ tí aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ bá ti lù sí aago mẹ́fà ìdájí.

Adeleye tó tún jẹ́ Ọ̀gá àgbà ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun ní ìpínlẹ̀ Ondo nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́ja Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹsàn-án tún ní àwọn kò ní fi ààyè gba àwọn ilé ijó láti máa ṣiṣẹ́ kọjá aago méjìlá òru.

Ó ní ìgbésẹ̀ yìí wáyé látọwọ́ ìjọba láti rii dájú pé gbogbo àwọn oníṣẹ́ ibi ni wọ́n lé jìnà ní ìpínlẹ̀ náà.

Bákan náà ló fi kun un pé gbogbo àwọn ọkọ̀ tí wọ́n bá kun gíláàsì rẹ̀ lọ́dà ni àwọn kò ní fi àyè gbà mọ́ àyàfi tí ọkọ̀ náà bá ní ìwé àṣẹ láti lo ọkọ̀ náà.

Ó fi kun pé àwọn ọkọ́ tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ náà ni òfin yìí kàn.

Adeleye ní ìjọba ti darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ ààbò láti láti fi òfin de gbogbo àwọn ọ̀kadà tàbí ọkọ̀ tó bá rú òfin yìí.

Ó rọ gbogbo àwọn ọlọ́kadà àti àwọn ọlọ́kọ̀ láti lọ ṣe àkọ́lè pẹ̀lú ìjọba ní kíákíá nítorí ẹnikẹ́ni tó bá rú òfin náà yóò fojú winá òfin.

Ó ní ìṣèjọba tó wà lóde lábẹ́ ìdarí gómìnà Oluwarotimi Akeredolu ní ìfarajì sí ààbò ẹ̀mí àti dúkìá ní ìpínlẹ̀ náà.