You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí rèé tí mo fi jẹ́ kí ọmọ mi padà sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti fún un ní májèlé - Ronke Oshodi-Oke
Gbajumọ oṣerebinrin, Ronke Ojo, ti ọpọ mọ si Ronke Oshodi-Oke ti pada sọrọ lori bi awọn kan ṣe fun ọmọ rẹ ni majele mu ni ile ẹkọ̀ fasiti to wa.
Ọsẹ to kọja ni Ronke Ojo kegbajare lori ayelujara Instagram rẹ pe awọn kan da kẹmika ti wọn fi n fọ aṣọ, bleach si inu omi ti ọmọ naa mu.
Ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ̀, ni Arabinrin Ronke ti ṣàlàyé pe ni bii ọ̀sẹ̀ mẹrin ṣeyin, ni awọn Aláṣẹ ile ẹ̀kọ́ giga Fasiti, ti ọmọ oun wa deede pe oun.
O ni o ku díẹ̀ ki aago mẹ́rin ìdájí lù ni wọn pe oun pe ọmọ oun mu kẹ́míkà 'bleach' ti wọn fi n fọ aṣọ.
O ni nigba ti oun de bẹ, asiri gbe ike omi 'bottle' lati mu omi laarin oru ni nnkan bi aago mẹta. Lai mọ pe awọn ti wọn jọ n gbe yaara ti da bleach sinu omi.
Ko pẹ̀ẹ́ to mu omi naa ni inira de ba agọ ara rẹ.
Ileewosan gbogboogbo to jẹ ti ìjọba ni wọ́n ti pada doola ẹ̀mí ọmọ naa.
Ọpọlọpọ awọn ololufẹ ati akẹgbẹ rẹ si lo ba a kẹdun, ti awọn kan si gba a ni imọran pe ko paarọ ile ẹkọ ọmọ naa, ko si pe awọn ọmọ naa to hu iwa naa l’ẹjọ.
Ṣugbọn ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Punch ni ọjọ Aiku, Ronke Oshodi-Oke ni ọmọ naa ti pada sile ẹkọ rẹ.
Arabinrin Ojo sọ pe lati igba ti ọmọ naa ti pada sile ẹkọ lẹyin to kuro nileewosan, ni ọkan oun ko ti balẹ rara lati igba naa.
O ni o kere tan, oun n pe ni igba marun-un lojumọ lati fi mọ alaafia rẹ.
“Ti mo ba pe e, ti ko ba gbe ipe rẹ, ipaya ma n ba mi.
Ronke Ojo sọ pe o da oun loju pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ri fidio ti oun fi kegbare, ti oun si ṣetan lati pariwo orukọ fasiti naa sita, ti wọn ba fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iṣẹlẹ naa.
“Botilẹ jẹ pe a ko mọ awọn to hu iwa naa, awọn alaṣẹ sọ pe awọn ti n ṣe iwadii.”
Ọpọ eeyan lo gba a nimọran pe ko paarọ ile ẹkọ fasiti ọmọ naa, Ronke Ojo sọ pe oun jẹ ki o pada sile ẹkọ pẹlu awọn ikilọ to l’agbara.
“Mo kilọ fun pe o gbọdọ ma a kiyesara ni gbogbo igba to ba fẹ jẹun.
“Bakan naa ni mo sọ fun un pe ko gbọdọ fi ounjẹ tabi nnkan mimu rẹ silẹ lai ni amojuto, fun idi kankan.”
Amọ o, ko ṣai dupẹ lọwọ gbogbo awọn to ṣe aajo rẹ lori iṣẹlẹ naa, “botilẹ jẹ pe awọn kan bu u”.
Iléèwòsàn kẹta ni wọ́n ti pa oró májèlé tí wọ́n fún ọmọ mi mu ní Fáṣítì
Gbajugbaja òṣèrébìnrin, Ronke Ojo, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ronke Oshodi Oke, ti ké gbajare pe, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan fun ọmọ oun ni majele jẹ.
Ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ̀, ni Arabinrin Ronke ti ṣàlàyé pe ni bii ọ̀sẹ̀ mẹta ṣeyin, ni awọn Aláṣẹ ile ẹ̀kọ́ giga Fasiti, ti ọmọ oun wa deede pe oun.
O ni o ku díẹ̀ ki aago mẹ́rin ìdájí lù ni wọn pe oun pe ọmọ oun mu kẹ́míkà 'bleach' ti wọn fi n fọ aṣọ.
"Aya mi ja pe, Kia ni mo gbera lọ si ile ẹ̀kọ́ naa.
O ni nigba ti oun de bẹ, asiri gbe ike omi 'bottle' lati mu omi laarin oru ni nnkan bi aago mẹta. Lai mọ pe awọn ti wọn jọ n gbe yaara ti da bleach sinu omi.
Ko pẹ̀ẹ́ to mu omi naa ni inira de ba agọ ara rẹ.
"Ileewosan gbogboogbo to jẹ ti ìjọba ni wọ́n ti pada doola ẹ̀mí ọmọ mi."
Bo tilẹ̀ jẹ́ pé fasiti aladani ni ọmọ oserebinrin naa n lọ, nibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ti waye, Arabinrin Ronke Ojo sọ pe oun ko nii dárúkọ ile ẹ̀kọ́ naa.
O ni oun pinnu lati ṣe bẹẹ, ki abuku ma bàa ba orúkọ wọn.
O ni sugbọn, oun fi asiko yii kilọ fun wọn pe iru nnkan bẹẹ ko gbọdọ ṣẹlẹ̀ si ọmọ oun mọ.
Lẹ́yìn to fi fidio naa síta, ni ọpọlọpọ awọn olólùfẹ́ rẹ, ati awọn akẹẹgbẹ́ òṣèrébìnrin naa ti n ba a daro.
Ọ̀pọ̀ lo n gba a nimọran pe ko mu ọmọ rẹ kuro ni fasiti naa, nitori pe 'ina eeṣi ko gbọdọ jóni lẹẹmeji'.
Bákan náà ni àwọn kan tun sọ fun pe ko fi ọwọ́ òfin mu ọrọ naa, nitori pe igbiyanju lati pani ni wọn n pe iru nnkan ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ naa ṣe.
Eyi tó yẹ ki awọn akẹ́kọ̀ọ́ naa jiya ẹ̀ṣẹ̀ wọn.