Ọkọ- ìyàwó fi ojú ba iléẹjọ́ nítórí ó fẹ́ ìyàwò míì

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ọjọru ni awọn ti gbe arakunrin, Edmund Uzoma lọ si ileẹjọ nipinlẹ Eko lori ẹsun pe o fẹ iyawo meji

Uzoma ni wọn gbe lọ sile ẹjọ magisreti ni agbegbe Yaba ni ilu Eko, ti Magisreti Adeola Olatunbọsun jẹ adajọ fun.

Ẹsun ti wọn fi kan Uzoma ni pe o parọ igbeyawo ati fifẹ iyawo oloruka ju ẹyọkan lọ labẹ ofin.

Agbẹjọrọ , Idowu Osungbure sọ fun ileẹjọ pe Uzoma ni iyawo si ile to si tun lọ ṣe igbeyawo miran pẹlu arabinrin kan, Sophia Yongxian ni ileẹjọ.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan ọkunrin ọkọ iyawo ọhun pe oun dibọn, to si n gbe igbeaye ẹni ti ko ni iyawo rii, bẹẹ o si ti bimo si ile.

Osungbure ni ọdun 2019 ni ọkunrin naa ṣe aṣemaṣe ọhun to si ni ẹṣẹ naa ni ẹtọ si ijiya labẹ ofin.

Ninu ọrọ rẹ, ẹsun naa tako iwe ofin ipinlẹ Eko ẹka ṣection 411 ati 115 ti ipinlẹ Eko to fi mo ti ijọba apapọ Naijiria.

‘’Iwọ arakunrin Edmund Uzoma to n gbe ni agbegbe Lekki, Golden Gate ti gbe igbeṣẹ aburu lati ṣe si ofin ijọba nipa piparọ lẹyin to ti bura pe iyawo kan ni oun ni.

Amọ ọkọ iyawo naa ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Magisreti Olatunbosun wa gba miliọnu kan Naira gẹgẹ bi owo beeli rẹ pẹlu oniduro meji.

Magisreti naa ni awọn oniduroti rẹ gbọdọ ni ilẹ ni ilu Eko, igbẹjọ tẹsiwaju ni Ọjọ marundinlogun, Oṣu Kẹta, ọdun 2023.