Princess gbé ìkìlọ̀ síta lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ Baba Ijesha lọ́gba ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Instagram
Adẹrinpoṣonu obinrin, Damilola Adekoya, ẹni ti ọpọ mọ si Princess ti sọrọ sita lẹyin ti gbajugbaja oṣere tiata, Olarenwaju James, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha gba ominira kuro lọgba ẹwọn lẹyin to ti to ọdun mẹta to dero ọgba ẹwọn naa.
Ana ode yii ni Yomi Fabiyi, tii ṣe akẹẹgbẹ Baba Ijesha lagbo tiata lo kede ọrọ yii loju opo Instagram rẹ ni alẹ ọjọ Ẹti ana.
Princess, ninu fọnran to n gbe sita loju opo ayelujara ni iroyin ituseilẹ Baba Ijesha ko ki n ṣe iroyin ayo rara pe Baba Ijesha jade kuro lọgba ẹwọn.
O fẹsun kan Baba Ijesha pe ọpọ ọmọde lo ti kọlu pẹlu ifipabanilopọ ṣaaju ki ọwọ to tẹ.
"O yẹ ki Olarenwaju James, Baba Ijesha wa ni atimọlẹ fun aye araye ni. Ni bayii, gbogbo wa ti mọ iru eeyan ti Baba Ijesha jẹ, ti a si ni lati dabobo awọn ọmọde lọwọ nini iru iriri yii.
"Ọrọ ti mo n sọ yii wa fun awọn ọlọgbọn, ti o ba ni ile ẹkọ, ile itura, ti ẹ ba ri Baba Ijesha ni ayika yii, ẹ mọ ohun to yẹ lati ṣe.
"Ko ki n se awọn ọmọde nikan, koda awọn onile, ti wọn gbe ile fun awọn eeyan ni lati mọ iru eeyan ti Baba Ijesha jẹ."
Princess ni ti nnkan mii ba wayii lẹyin ti oun gbe fọnran yii jade, ki awọn eeyan mọ pe oun ti sọ ṣaaju.
O fikun pe Baba Ijesha ti lo gbogbo ọdun ti ile ẹjọ dajọ ni pe ko lọ lo ni ọgba ẹwọn lori ẹsun ifipabanilopọ to fi kan.
Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹlu bi Yomi Fabiyi fun bi o ṣe n ṣe atilẹyin fun Baba Ijesha.
"Fun ẹyin ti ẹ n sọ n pe o ti jade, Ọlọrun yoo da fun mi, n jẹ ẹ ro pe Ọlọrun wa lẹyin eeyan to n fipa ba ọmọde lopọ.
"Baba Ijesha lo gbogbo agbara lati lọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, to si lulẹ ni gbogbo igba to lọ."
Princess tun darukọ awọn agbegbe ti Baba Ijesha ti gbe nipinlẹ Eko lati kilọ fun awọn eeyan ibẹ.
"Mo ti kilọ fun yin bayii, n ko fi nnkan pamọ fun yii, Baba Ijesha jẹ ọdaran ti lọ ọgba ẹwọn.
"Mo ti ṣe nnkan to yẹ ki n ṣe gẹgẹ bii abiyamọ, to n fẹ ilọsiwaju agbegbe wa, o lo si ofin pe ki o fipa ba eeyan lopọ, paapa ọmọ.
"Mo n rọ ijọba ipinlẹ Eko pe ki wọn gbe orukọ Baba Ijesha si ta gẹgẹ bii ọdaran to fipa lopọ.
"Ti wọn ba bi yin da, ẹ jẹ ki n ri pe ẹ wa ba mi pe ki a ja fun idajọ fun ẹnikẹni."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Bàbá Ijesha jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ilé ẹjọ́ kotẹ́milọrun ní kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ṣíṣe àṣemáṣe pẹ̀lú ọmọdé

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi/Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà àti aláwàdà nnì, James Olanrewaju Omiyimika, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Baba Ìjẹ̀ṣà tí gba idande kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Yomi Fabiyi, tíí ṣe akẹẹgbẹ́ Bàbá Ijesha lágbo tíátà lo kéde ọ̀rọ̀ yìí lójú òpó Instagram rẹ ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì àná.
Fabiyi ni inú òun dùn pé ilé ẹjọ́ kotẹ́milọrun lo tún bàbà Ijesha silẹ pé kò máa lọ ní àlàáfíà.

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi/Instagram
"Koko ni ara Baba Ijesha le lẹ́yìn to tí ọgbà ẹ̀wọ̀n de, ó sì wá ní àláàfíà ní ara ati ọpọlọ"
Bákan náà, ó soju rẹ síta pé ilé ẹjọ́ náà wẹ baba Ijesha mọ kúrò nínú ẹ̀sùn ṣíṣe àṣemáṣe pẹlu ọmọdé tó gbé de ọgbà ẹ̀wọ̀n tẹlẹ.
Nínú àlàyé rẹ̀, Fabiyi ni koko ni ara Baba Ijesha le lẹ́yìn to tí ọgbà ẹ̀wọ̀n de, tí ó sì wá ní àláàfíà ní ara ati ọpọlọ.
"Irọ patapata ni ẹ̀sùn biba ọmọ ọdún méje lòpọ̀ tí wọn fi kan Baba Ijesha, kò sí ohun tó jọ bẹẹ.
Ile ayé búburú ni a ń gbé, níbi tí ìwà ìkà tí ń borí idajọ ododo àti òtítọ́
Kókó ohun tí Fabiyi ní o mú kí bàbà Ijesha bọ́ lórí ẹ̀sùn tó gbé e dé ọgbà ẹ̀wọ̀n
Wọn fi ẹ̀sùn ṣíṣe àṣemáṣe pẹlu ọmọdé dẹ pakute mú bàbà Ijesha lọ ṣẹwọn ni.
Nínú àlàyé rẹ̀ lórí ìdí tí ilé ẹjọ́ ṣe kéde pé Bàbá Ijesha kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ṣiṣe àṣemáṣe pẹ̀lú ọmọdé tó gbé dé ọgbà ẹ̀wọ̀n, Yomi Fabiyi ṣàlàyé ìdí márùn-ún tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀.
Ìdí akọkọ ni pé àwọn èèyàn tó dẹ pakute náà silẹ fún bàbá Ijesha pàrọ̀ nípa ọjọ́ orí ọmọdé tí ọrọ̀ náà kan.
"Kò sí ẹ̀rí tó dájú ní ibikíbi tàbí nílé ẹjọ́, títí di àkókò yìí, tó fihan pe ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni ọmọ tí wọn ní Baba Ijesha bá ṣe àṣemáṣe.
Sì èmi, wọn kan lo ẹ̀sùn pé Baba Ijesha bá ọmọdé lòpọ̀ láti fi ìwà búburú ṣe àtakò si ni.

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi /Instagram
"Wọn kò bá Okele, ọdẹ ilé Princess, tó ń ní ibalopọ pẹlu ọmọdébìnrin tí ọrọ̀ kan ṣe ẹjọ́ rara"
Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí kejì tí ilé ẹjọ́ kotẹ́milọrun se kéde pé Baba Ijesha kò jẹbi ẹsun àṣemáṣe pẹlu ọmọdé tí wọ́n fi kan, Yomi Fabiyi ni àwọn èèyàn tó ń lo ọmọdébìnrin tí ọrọ̀ kan nilokulo kò de ile ẹjọ rara.
"Damola Adekola tí wọn tún ń pè ní Princess, òṣèré tíátà àti aláwàdà to jẹ alagbatọ ọmọdébìnrin náà, ní ọdẹ kan nínú ilé, tí wọn ń pè ní Okele, to tí ń ní ibalopọ pẹlu ọmọdébìnrin náà láti ọdún 2020 sì ń rìn kiri pẹlu ominira.
Okele yìí ní ibalopọ gangan pẹlu ọmọbìnrin náà, kódà, ó fìdí rẹ mulẹ pé ọ̀rẹ́bìnrin òun ni ọmọ náà, tí wọn sì tú silẹ lai bá ṣe ẹjọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́pàá mú òun àti Baba Ijesha papọ ni.
Ṣé eléyìí mú ọpọlọ dání pé nínú ẹjọ́ kan náà, lórí ọmọdébìnrin kan náà áti lórí iwadii kan náà.

"Wọn rí àtọ̀ ọkùnrin ní ojú ara ọmọbìnrin náà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tí ọlọ́pàá tí gbé bàbá Ijesha, wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ja ibale ọmọdébìnrin náà ni"
Ìdí kẹta tí Yomi Fabiyi ṣàlàyé pé ó mú kí ilé ẹjọ́ kotẹ́milọrun tú bàbà Ijesha silẹ ni pé Princess, tíì ṣe aláwàdà lo jẹ alagbatọ ọmọ náà,
"Wọn rí àtọ̀ ọkùnrin ní ojú ara ọmọ náà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tí ọlọ́pàá tí gbé bàbá Ijesha.
Kii se àtọ̀ baba Ijesha lo wa lara ọmọ náà, ìwádìí sì fihan pe wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ja ibale ọmọdébìnrin náà ni."
"Princess mọọmọ rí ẹ̀rọ̀ ayaworan sinu ilé rẹ ni ọjọ́ tó ránṣẹ́ pé Baba Ijesha láti wa ṣeré"
Yomi Fabiyi tẹsiwaju pé idí kẹrin ni pé Princess mọọmọ rí ẹ̀rọ̀ ayaworan sinu ilé rẹ ni ọjọ́ tó ránṣẹ́ pé Baba Ijesha láti wa ṣeré.
"O ka ohun àti àwòrán silẹ nípa bí wọn tí ń ṣe àṣemáṣe pẹlu ọmọdé to gba sílè."
Yomi Fabiyi wá ṣèlérí pé gege bíi ajàfẹ́tọ̀ọ́ẹni, àwọn ko ni gba kí ìwà ìkà máa gbèrú si.

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi /Instagram
Bawo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbé Bàbá Ijesha dé ẹ̀wọ̀n ṣe wáyé?
Gbajúmọ̀ aderinposonu àti òṣèré tíátà, Princess, lo kede pe akẹẹgbẹ́ òun lágbo tíátà, James Olanrewaju Omiyimika, tí a tún mọ si Baba Ijesha ń ní àṣemáṣe pẹlu ọmọbìnrin tí òun gba tọ, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, tó sì fi ọlọ́pàá mú.
O gbé bàbá Ijesha lọ sílé ẹjọ́, tí ìgbẹ́jọ́ sì wáyé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, tí ilé ẹjọ́ sì kéde pé Baba Ijesha jẹbí esun ìfipábánilòpọ̀ pẹlu ọmọ ọdun mẹ́rìnlá naa.
Agbẹjọ́rò Baba Ijesha, Dada Awosika níbi ìgbẹ́jọ́ náà sọ fún ilé ẹjọ́ wí pé ilé ẹjọ́ nílò láti se atungbeyẹwo ọ̀rọ̀ ọjọ́ orí ọmọ tí wọ́n fi ẹ̀sùn rẹ̀ kan òun, wí pé òun bá lòpọ̀ kìí ṣe òótọ́.
Adajo Oluwatoyin Taiwo, ninu idajọ wakati meji rẹ, da Baba Ijesha lẹbi fun iwa aisedede si ọmọ na, àṣemáṣe to fara pẹ ibalopo, ati igbidanwo ìfipábánilòpọ̀.















