Ọkọ̀ Cybertruck tó kún fún epo àti báńgà gbiná níwájú ilé ìtura Trump ní Las Vegas

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ọlọpaa ti n ṣe iwadii lẹyin ti ọkọ Tesla Cybertruck kan, to kun fun agolo epo bẹtiro ati nnkan abugbamu ti awọn eeyan n tan fun ọdun, gbina ni iwaju ita Trump Hotel niluu Las Vegas, Nevada, ni America.

Oju ẹsẹ ni awakọ naa ku, ti eeyan meje si tun fara. Awọn ọlọpaa sọ pe ifarapa wọn ko pọ pupọ.

Ilu Colorado ni wọn ti yá ọkọ naa fun lilo, to si de si Las Vegas ni owurọ Ọjọru. Ko ju wakati meji lọ to wọ inu ilu ni awọn nnkan naa bu gbamu, gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa sẹ sọ. Iwaju ile itura naa nitosi ẹnu ọna kan ti wọn fi gilaasi ṣe lo gbe ọkọ naa si, nibi to ti eefin ti bẹrẹ si ni jade ninu rẹ, ko to o bu gbamu.

Ninu ọrọ to sọ, Aarẹ Joe Biden sọ pe ileeṣẹ ijọba ni White House ti n tọpinpin iṣẹlẹ naa lati mọ boya o ni nnkan ṣe pẹlu ikọlu kan to waye ni New Orleans, nibi ti eeyan mẹẹdogun ti ku lọjọ ọdun tuntun.

Ibugbamu naa waye lẹyin wakati diẹ ti ọkunrin kan wa ọkọ akẹru kan to ni asia ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State (IS), wọ aarin eero ni New Orleans. Eeyan mẹẹdogun lo ku, ọpọ si farapa.

Kevin McMahill, olori ileeṣẹ ọlọpaa ni Las Vegas, sọ pe awọn tun n ṣe iwaddi lati mọ boya iṣẹlẹ ibugbamu naa ni ohunkohun lati ṣe pẹlu Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Donald Trump, to ni ile itura naa, tabi Elon Musk, ti ileeṣẹ rẹ ṣe ọkọ Tesla.

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ FBI sọ pe awọn ṣi n wo o boya igbesunmọmi ni iṣẹlẹ naa, ṣugbọn wọn ni awọn ko tii le sọrọ lori idanimọ ẹni to wa ọkọ ọhun.

Awọn alaṣẹ sọ pe ọkọ mejeeji ti wọn lo fun awọn iṣẹlẹ mejeeji ọhun ni wọn yá fun lilo lori aapu kan ti wọn ti ma n ya ọkọ, Turo.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ Turo sọ pe awọn n ṣiṣẹ pẹlu awọn alaṣẹ ni Las Vegas ati New Orleans lati ran wọn lọwọ ninu iṣẹ iwadii. Agbẹnusọ ileeṣẹ naa sọ pe awọn eeyan mejeeji ko jọ ẹni to ni akọsilẹ iwa ọdaran, eyi to le mu ki awọn fura si wọn pe, wọn le ṣe ijamba laarin ilu.

Awọn alaṣẹ sọ pe awọn ni akọsilẹ orukọ ẹni ẹni to yá ọkọ naa, amọ awọn ko tii le sọ boya oun naa lo wa a .

Àjà mẹrinlelọgọta lo wa ni Trump Hotel, to si ni awọn yaara alaṣepọ 1,300, gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni ori itakun agbaye rẹ.

Laipẹ yii ni Trump darukọ Elon Musk gẹgẹ bi olori igbimọ ti yoo maa gba aarẹ ni imọran, lẹyin ti awọn mejeeji di ojugba ara wọn lasiko ipolongo ibo Trump.