Wo ìlú kan l'Ondo, níbi tí ìró àpáta ń mú kí ilé mì tìtì, fọ́ ògiri ọ̀pọ̀ ilé, tí ìdààmú sì ń báwọn olùgbé ibẹ̀

Oríṣun àwòrán, Adesola Ikulajolu/BBC
- Author, Adesola Ikulajolu
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
"Ohun to sẹlẹ ni pe, lọjọ kan, a kan ri pe wọn de ni, wọn dẹ sọ fun wa pe ki a kuro ni agbegba naa, pe wọn fẹ ma fọ apata."
Femi Odimayo ra ilẹ ni ilu Imafon nijọba ibilẹ Ariwa Akure nipinlẹ Ondo ni o le ni ọdun mẹwaa bayii, ṣugbọn lọdun 2025, ohun iya lẹnu lo jẹ fun nigba ti awọn ileeṣẹ kan ṣadede de si ilu naa pe awọn fẹ fọ apata kan to wa ni ẹgbẹ ile rẹ.
Femi darapọ awọn olugbe agbagbe Ulyagbi, Imafon ti wọn ni awọn koju fifọ apata nla to n mi ile, to si tun ba ọpọ nnkan jẹ ni agbegbe naa.
Femi sọ fun BBC pe lasiko ti wọn ba bẹrẹ si ni ma fọ apata, wọn yoo le awọn olugbe kuro ni agbegbe, to si jẹ pe nigba ti wọn yoo ba pada, ijamba yoo ti ṣe ile wọn,
"Gbogbo wa salọ, a lo si odi keji. Ki a to pada, wọn ti ba ile wa jẹ, orule mi ti ja, ti ara ogiri si ti fọ."
BBC gbera lọ si agbegbe Uluyagbi ni Imofon nipinlẹ Ondo lati wo bi nnkan ṣe n lọ.
Lasiko abẹwo wa, lara awọn nnkan ti a ri ni awọn agbegbe to jẹ pe wọn gbẹ ilẹ, ti a si tun ri apẹrẹ pe wọn ṣẹṣẹ fọ apata nibẹ.
Fifọ apata nilo awọn kẹmika ati awọn ado oloro ko to si pe o waye.

Oríṣun àwòrán, Google Map screenshot
Ọpọ awọn olugbe sọ pe awọn kẹmika ti wọn n lo lati fi fifọ apata yii lo n ṣe akoba fun ilera wọn, ti ọpọ wọn si ti ni ifupa giga ati pe iṣoro eti nitori bi wọn se n gbọ ariwo ẹrọ ti wọn fi n fọ apata.
Odimayo sọ fun BBC News Pidgin ado oloro ti ileeṣẹ naa n lo ma n mi ilẹ titi lasiko ti wọn ba fọ apata naa, ti yoo da bi ilẹ riri.
Awọn olugbe agbegbe da orukọ ileeṣẹ gẹgẹ bii Dortmund and Company.
Olugbe miiran, Olufemi Oluwatuyi, to wa ni ẹni ọdun aadọta sọ pe ileeṣẹ yii ti ṣe akoba nla fun awọn ọmọ-ọmọ rẹ.
O ni ariwo ado oloro naa ma n jẹ ki ẹru ba oun pupọ, ti oun si ni lati gbe awọn ọmọ naa kuro ni ile naa nitori wọn ko gbọ iru ariwo bẹẹ ri.
"Ariwo gbaooh lẹẹkan naa, ọkan mi yoo ka soke. A ti mọ pe wọn fẹ fọ apata ni, ti a si ni lati ṣalọ, lai wọ bata, mogbe awọn ọmọ-ọmọ mi salọ."
Ofin Najiria nipa fifọ apata ni o ṣe koko ki wọn mọ ohun ti igbesẹ wọn n fa lasiko ti wọn ba sọ ado oloro si apata.
A ni iwe aṣẹ'- Ileeṣẹ Dortmund fesi

Oríṣun àwòrán, Mobolaji Olatunde/BBC
Ninu iwadii wa, orukọ ileeṣẹ Dortmund and Company Ltd ko jade loju opo ayelujara Corporate Affairs Commission(CAC), to n mojuto iforukọsilẹ awọn ileeṣẹ lorilẹede Naijiria.
Iwadii tun fihan pe ileeṣẹ yii ti wa fun ọjọ pipẹ, ti ọfisi wọn si wa niluu Akure, to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo.
A kan si ileeṣẹ naa lati beere pe njẹ nnkan ti wọn n se eyi ba ofin mu ati pe n jẹ wọn tọwọ bọ iwe adehun pẹlu awọn olugbe agbegbe naa.
"A ni iwe aṣẹ fun fifọ apata, A ki n ṣe eyi lai gba aṣẹ lọwọ wọn. "
"A ko ru ofin pẹlu a se n fọ apata, quarry ni agbegbe naa, gbogbo nnkan wa lo wa ni iforukọsilẹ," Adu Ojo arakunrin kan to jẹ asoju ileeṣẹ Dortmund and Company Ltd sọrọ.
Ẹwẹ, o fikun pe ọrọ yii wa ni ile ẹjọ lati igba ti ijọba ti da si ọrọ naa, to si tun jẹ ko di mimọ pe awọn ko ni ayede kankan pẹlu agbegbe Imafon.

Oríṣun àwòrán, Mobolaji Olatunde/BBC
Ileeṣe yii tapa si ọpọ ofin to nise pẹlu fifọ apata- Ijọba
Ni oṣu kẹjọ, ọdun 2025, ijọba ipinlẹ Ondo ati kọmisana fun ọrọ agbara ati ohun alumọni, Onimọẹrọ Johnson Jaiyeola Alabi ṣe abẹwo si agbegbe Imafon lati bi nnkan ṣe n lọ ati ileeṣẹ to n fọ apata.
Ẹka ijọba to n risi ọrọ agbara ati ohun alumọni ni ileeṣẹ naa tapa si ọpọ ofin orilẹede Naijiria to nise pẹlu fifọ apata.
O ni o kọ oun lominu pe ibi ti wọn ti n fọ apata ko jina si agbegbe ti awọn n gbe, ti eyi si lewu.
O ni ijọba yoo bẹrẹ igbesẹ lati da bobo awọn agbegbe ati ofin ti yoo dena de awọn ileeṣẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Mobolaji Olatunde











